Ipinya de laarin ore meji *Wọn ni Ajimọbi fẹ fi ọmọ Akala ṣe igbakeji gomina, niyen ba ni ko si ohun to jọ ọ

Spread the love

Okun ibaṣepọ to wa laarin gomina ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi ati Ọtunba Adebayọ Alao-Akala to wa nipo ọhun ṣaaju ti rẹ ja patapata pẹlu bi gomina atijọ naa ṣe pinnu lati fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan ko mọ inu ẹgbẹ ti Akala n lọ, awọn to sun mọ ọkunrin naa, ṣugbọn ti wọn ko fẹ ka darukọ awọn fidi ẹ mulẹ f’ALAROYE pe inu ẹgbẹ oṣelu ADC lo n lọ.

Bi eto ti wọn ti ṣe labẹnu ko ba yẹ, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, oni yii gan-an lọkunrin ọmọ Ogbomọṣọ naa yoo kede ni gbangba pe oun ti di ọmọ ẹgbẹ oṣelu ADC, ti wọn yoo si tẹwọ gba a tọwọ tẹsẹ nibẹ.

Gbogbo eeyan nigbesẹ ọhun ya lẹnu nigba ti Akala darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC lẹyin to ti figa gbaga pẹlu Gomina Ajimọbi lorukọ ẹgbẹ oṣelu Labour (LP), ninu idibo gomina ọdun 2015 to gbe Ajimọbi wọle lati ṣe saa keji nipo naa. Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu atawọn adari ẹgbẹ mi-in ni wọn tẹwọ gba a wọle ni gbọngan Mapo, n’Ibadan, lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kejila, ọdun to kọja (2017). Awọn amoye si gba pe ibaṣepọ wọn ko le pẹẹ fori ṣanpọn, wọn ni ọrọ ipo fun idibo ọdun 2019 ni yoo fa ipinya laarin wọn. Akala n fẹ lati tun ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ lẹẹkan si i, wọn si mọ pe bi ẹgbẹ Onigbaalẹ ko ba fa a kalẹ gẹgẹ bii oludije wọn ninu idibo ọdun to n bọ, lọgan ni yoo fi ẹgbẹ naa silẹ gba ibomi-in lọ.

Ṣugbọn Gomina Ajimọbi ṣe kinni kan to jọ pe o fi de Akala mọle ti awọn eeyan si ro pe ko ni i fun gomina atijọ yii lanfaani lati kuro ninu ẹgbẹ APC mọ. Bo ba si papa kuro, ẹgbẹ APC yoo ti gba pupọ ninu awọn oludibo to gbojule lagbegbe Ogbomoṣọ mọ ọn lọwọ. Iyẹn naa ni bi Ajimọbi ṣe fi ọmọkunrin Akala, Ọlamiju Akala, ṣe alaga ijọba ibilẹ Guusu Ogbomọṣọ.

Akala fifẹ han lati dupo ọhun ninu ẹgbẹ APC, ṣugbọn ko ba wọn kopa ninu idibo abẹlẹ ẹgbẹ naa ti Oloye Adebayọ Adelabu fi wọle idibo ọhun. Lati igba naa lawọn amoye oṣelu ti mọ pe ko le pẹ ko le jina ti Akala yoo fi binu kuro ninu ẹgbẹ oṣelu naa. Nitori naa, bo ṣe fi ẹgbẹ APC silẹ ko ba ọpọ eeyan lojiji rara.

Iroyin to tun n lọ bayii ni pe Ọlamiju yii paapaa ni wọn fẹẹ fi ṣe igbakeji gomina, eyi ti yoo mu ki ọpọ ara Ogbomọṣọ fẹ lati dibo fun egbẹ APC, koda, ki Akala fi ẹgbẹ naa silẹ ju bẹẹ lọ. Ṣugbọn ọkunrin naa ti sọ pe ọmọ oun ko jẹ gba lati ṣe igbakeji gomina, nigba ti ki i ṣe ọmọ ale.

Akala ko ti i kede pe oun ko ṣẹgbẹ APC mọ ti awọn eeyan ti mọ pe baba naa ti fẹẹ pin gaari pẹlu wọn. Eyi to ya awọn eeyan lẹnu ni ti ẹgbẹ oṣelu ADC ti ọkunrin naa pinnu lati darapọ mọ nitori inu ẹgbẹ ọhun ni Sẹnetọ Rashidi Ladọja wa, wọn gba pe awọn mejeeji ko le jọ ṣe ẹgbẹ oṣelu kan naa mọ laelae. Ṣe Akala ni igbakeji Ladọja nigba ti iyẹn wa nipo gomina ipinlẹ Ọyọ ko too pada di gomina nigba ti awọn alagbara oloṣelu yọ ọga ẹ (Ladọja), nipo. Rabaraba iṣẹlẹ yii ni Ladọja ba kuro ninu ẹgbẹ PDP lẹyin idibo ọdun 2007 to gbe Akala wọle sipo gomina laarin ọdun naa si ọdun 2011, ko too di pe oun paapaa binu fi ẹgbẹ naa silẹ nigba to dupo gomina lẹẹkeji, ṣugbọn ti awọn alakooso ẹgbẹ fipa yan oludije mi-in (Sẹnetọ Teslim Fọlarin) gẹgẹ bii oludije fun ipo gomina lorukọ ẹgbẹ yii.

Ọpọ igba ni Ladọja ati Akala ti gbe igbesẹ lati jọ wa ninu ẹgbẹ oṣelu kan naa, ṣugbọn ti ero awọn mejeeji ki i dọgba nitori ọga meji ti ko le wa ọkọ kan naa, lasiko kan naa, lawọn mejeeji. Ṣugbọn inu ẹgbẹ ADC ti Ladọja ti n ṣe adari wọn ni Akala papa pinnu lati lọ lẹyin to fi ẹgbẹ APC silẹ.

Gẹgẹ bii iwadii akọroyin wa, ko si ohun meji to mu awọn mejeeji gba lati jọ ṣiṣẹ pọ bayii bi ko ṣe nitori erongba lati lo oore-ọfẹ idibo ọdun 2019 lati le ẹgbẹ oṣelu APC kuro nipo ijọba.

Eto ta a gbọ pe wọn ṣe ni lati fun Akala lanfaani lati dupo sẹnetọ ẹkun idibo Ariwa ipinlẹ Ọyọ lorukọ ẹgbẹ ADC. Bẹẹ ni wọn yoo tun yọnda awọn ipo oṣelu meloo kan fun un.

ALAROYE gbọ pe ọpọ ninu awọn ti inu wọn ko dun si ọna ti idibo abẹle APC gba waye lo ti pinnu lati ba Akala lọ sinu ẹgbẹ ọhun.

Ṣugbọn pẹlu bo ṣe jẹ pe ẹnikan ki i ba Akala fori gbari ko rọwọ mu ninu idibo niluu Ogbomọṣọ ati awọn apa ibi kan lagbegbe ilu nla naa tẹlẹ, ko jọ pe eyi yoo ri bẹẹ ninu idibo ọdun 2019 to n bọ yii pẹlu ipo alaga kansu ti Ajimọbi ti fi Ọlamiju si, agaga ti iroyin ipo igbakeji gomina ta a gbo pe wọn fẹẹ fi da ọmọkunrin naa lọla ba tun lọọ dootọ. Amọ ṣa, Akala naa ko dakẹ, o ti ni ọmọ oun ko ṣe igbakeji gomina kankan, ki Ajimọbi atawọn APC fọwọ mu ipo wọn.

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.