Ipinlẹ Ogun n koju ijamba ọkọ pupọ nitori ibi to wa—Akọwe ijọba

Spread the love

Akọwe ijọba ipinlẹ Ogun, Amofin Taiwo Adeoluwa, ti sọ pe lasan kọ ni ipinlẹ naa n koju ijamba ọkọ lọpọ igba, o ni ohun to n fa a ko ju pe ibi ti ilu naa wa ni i ṣe pẹlu ilẹ Ibo ati ilẹ Hausa, o si tun ja si ilẹ Olominira Benin pẹlu.

Adeoluwa sọrọ yii nibi ipade ọlọdọọdun ajọ TRACE, ẹlẹẹkẹta iru ẹ to waye l’Abẹokuta lọjọ kin-in-ni, oṣu kejila yii. O ṣalaye pe beeyan n bọ lati Ila-Oorun Naijiria ti i ṣe ilẹ Ibo, yoo gba ipinlẹ Ogun kọja, bo si jẹ apa Ariwa naa lọkọ ti n bọ, dandan ni ko gba apa kan ipinlẹ Ogun kọja.

Bo ṣe tun waa jẹ pe aala da ipinlẹ Ogun pọ mọ Benin naa pẹlu idi ti ero fi n gbabẹ wọle lọpọ igba, beeyan ba si ṣe pọ to n lo oju ọna kan to naa lo ṣe jẹ pe ijamba le ṣẹlẹ nibẹ to.

Yatọ si apa ibi ti ipinlẹ yii wa, nnkan mi-in ti akọwe ijọba lọfisi Gomina Amosun tun tọka si pe o le fa ijamba ni ti awọn oniṣọọṣi ati ijọ ẹlẹsin Islam ti wọn kọ ṣọọṣi ati agọ nla sẹgbẹẹ oju ọna marosẹ ipinlẹ yii. O tọka si awọn ṣọọṣi bii Ridiimu, Deeper Life, Mountain of Fire, Winners atawọn Nasfat ti wọn ni ileejọsin lopopo yii, eyi to n mu ọpọ mọto wọ ipinlẹ Ogun, to si le ṣokunfa ijamba ojiji nigba ti ẹni kan ko ba gba fun ikeji.

Lati kapa awọn ijamba yii lo ni ijọba ṣe bẹrẹ iṣe lori awọn afara gigun (Flyover) mẹtalelogun, ti mẹẹẹdogun ti yọri ninu ẹ, ti mẹjọ to ku naa yoo si pari laipẹ.

Adeoluwa gboriyin fun ajọ TRACE, o ni iṣẹ wọn ti din ijamba ku nipinlẹ Ogun gan-an.

O fi kun un pe idanilẹkọọ yẹ ko wa fawọn awakọ atawọn araalu, bẹẹ si ni ẹgbẹta oṣiṣẹ(600) to n ṣiṣẹ TRACE lasiko yii ko to. Akọwe ijọba ni ki saa iṣakoso yii too pari loṣu karun-un, ọdun to bọ, o kere tan, awọn yoo gba igba (200), oṣiṣẹ si i ti wọn yoo kun TRACE.

Ṣaaju ni apaṣẹ TRACE, Ṣeni Ogunyẹmi, ti sọ pe ilẹ eeka mẹta lo ti wa bayii fajọ naa lati kọ olu ileesẹ TRACE ati ileewe nipa igbokegbodo ọkọ (Transport Academy), eyi to jẹ ẹka kan lara ileewosan Jẹnẹra Ọlabisi Ọnabanjọ to wa ni Ṣagamu si.

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.