Ipinlẹ Kwara ti jiya to lọwọ awọn adari amunisin -APC

Spread the love

Ẹgbẹ oṣelu APC ti ni oṣelu ipinlẹ Kwara ti n yatọ si ti atijọ, to si ti n gba ọna ọtun bayii pẹlu bawọn araalu ṣe dibo wọn ninu atundi ibo to waye lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kọkanla.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro apapọ ẹgbẹ ọhun, Malam Lanre Onilu gbe sita lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, lo ti ni awọn araalu ti jiya to lọwọ adari jẹgudujẹra to kan ara rẹ nipa le wọn lori.

Nigba to n fesi si igbesẹ ile igbimọ aṣofin agba lati ṣewadii ohun to fa a ti ẹgbẹ PDP ṣe fidi-rẹmi nipinlẹ Olori ile igbimọ naa, Bukọla Saraki, o ni awọn tako igbesẹ ti wọn fẹẹ gbe, nitori pe awọn araalu ti sọ ohun to wu wọn nipa ibo wọn.

Onilu sọ pe, “O jẹ ohun iyalẹnu pe ọrọ atundi ibo Kwara nikan nile igbimọ aṣofin n pariwo. Ki lo de ti wọn ko pariwo lori awọn atundi ibo to waye nipinlẹ Katsina ati Bauchi, nibi ti ẹgbẹ PDP ti fidi-rẹmi sọwọ APC.

“Ohun to daju ni pe bi oludije APC, Raheem Ọlawuyi Ajulọ-Opin, se jawe olubori ninu atundi ibo naa ba awọn aṣofin Kwara tile igbimọ aṣofin agba naa ti gbega kọja bo ṣe yẹ nibi ti ko dara. Idi niyi ti wọn ṣe n pariwo kiri”.

Onilu ni o yẹ ko ti ye ile igbimọ naa bayii pe oju awọn ara ipinlẹ Kwara ti la, wọn si ti ri i bawọn ti wọn n pe ara wọn ni adari wọn lẹgbẹ PDP ṣe n ṣe wọn baṣubaṣu.

O gba awọn adari ẹgbẹ PDP nipinlẹ Kwara ati kaakiri nimọran lati tete maa fi ifidi-rẹmi ninu idibo kọra. O ni ero awọn araalu lo maa ṣẹ lọdun 2019, ati lawọn ọdun to n bọ.

 

 

 

 

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.