Ipaniyan: Afẹnifẹre, APC kegbajare l’Ekiti

Spread the love

Ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba ta a mọ si Ẹgbẹ Afẹnifẹre atawọn aṣofin ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ti kegbajare pe iṣẹlẹ ipaniyan to n waye lemọlemọ nipinlẹ Ekiti ti to gẹẹ bayii, kawọn agbofinro wa awọn to n ṣiṣẹ ibi naa sita kiakia.

Eyi waye lẹyin tawọn agbebọn kan pa Bunmi Ojo to jẹ oloye APC l’Ekiti, ati ọkunrin kan ti a ko ti i mọ orukọ rẹ laarin ọjọ mẹrin sira wọn, iyẹn lọsẹ to lọ lọhun-un ati ọsẹ to kọja.

Ẹgbẹ Afẹnifẹre kede ọrọ naa nipasẹ alaga wọn, Alagba Yẹmi Alade ati akọwe ipolongo, Oloye Bisi Alade, wọn si woye pe apa awọn ọlọpaa gan-an ko fẹẹ ka kinni ọhun mọ.

Bakan naa ni wọn sọ pe iṣẹlẹ ipaniyan lemọlemọ naa fi han pe awọn ẹgbẹ to jẹ tibilẹ ko ri nnkan ṣe sọrọ yii, eyi to ba ni lọkan jẹ jọjọ. Wọn ni o daju pe eeyan lawọn to n ṣiṣẹ ibi ọhun, idi niyi to fi yẹ ki wọn wa wọn ri ni gbogbo ọna.

Wọn waa ba APC ati idile Oloogbe Bunmi Ojo kẹdun, wọn ni akanda ẹda ti iranti rẹ ko ni i parẹ laelae ni ẹni wọn to lọ ọhun.

Ninu ọrọ tiwọn latẹnu Ọnarebu Gboyega Aribiṣọgan to jẹ olori ọmọ ẹgbẹ to kere ju nile igbimọ asọfin Ekiti, awọn aṣofin APC ni awọn aṣebajẹ ti da awọn ti Bunmi Ojo ṣeranlọwọ fun si wahala bayii.

Asọfin naa to sọrọ lorukọ Ọnarebu Sunday Akinniyi ati Ọnarebu Adeniran Alagbada waa ṣapejuwe oloogbe bii ẹni to gbe igbesi aye rere, eyi ti Ekiti ko ni i gbagbe laelae, bẹẹ lo rọ awọn agbofinro lati wa awọn apanijaye naa jade kiakia.

(36)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.