Inu n bi ewurẹ, o fẹsẹ halẹ …

Spread the love

Bi inu ba n bi ewurẹ to n fi ẹsẹ halẹ, ṣe yoo pa olowo rẹ jẹ ni! Ṣugbọn o jọ pe ewurẹ eleyii n mura lati pa olowo rẹ jẹ o. Ọrọ Buruji Kaṣamu leeyan yoo ro debẹ, Buruji to fẹẹ ṣe gomina Ogun lorukọ PDP. Ṣugbọn ẹgbẹ PDP lawọn ko fẹ ẹ, wọn ni awọn ti le e ninu ẹgbẹ awọn, ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ naa, ko si le du ipo lorukọ ẹgbẹ awọn. Bo si tilẹ jẹ pe wọn ti da ẹgbẹ oṣelu yii silẹ tipẹ ki Kashamu too de lojiji, to si dọmọ ẹgbẹ, sibẹ, ọkunrin naa ni ko si ẹni to le le oun ninu ẹgbẹ yii, afẹni to ba maa tẹ. Wọn ti ṣeto idibo abẹle, wọn ti fi orukọ ranṣe, ẹgbẹ si ti gbe asia wọn fun Ladi Adebutu, wọn ni oun ni yoo du ipo gomina lorukọ wọn. Ṣugbọn Kaṣamu ko sinmi, o nija ṣẹṣẹ bẹrẹ ni, nitori oun loun yoo du ipo naa, ki i ṣe Ladi. Ko si bi ẹni kan ti le lowo to, tabi ko lagbara to, bo ba wa ninu ẹgbẹ kan, afi ko tẹle ofin ẹgbẹ naa, ko si gba ohun ti ẹgbẹ ba ṣe. Nibi ti ẹ ba ti n ri ẹni ti ko gba ohun ti ẹgbẹ ṣe, tabi to ni ofin oun ga ju ti ẹgbẹ lọ, ẹ mọ pe iru ẹgbẹ bẹẹ yoo tuka gbẹyin ni, iyẹn bi wọn ko ba le tọhun danu, ti wọn yoo ti i ṣubu yakata. Bi Kaṣamu ba mọ pe oun fẹẹ du ipo gomina ninu ibo to n bọ yii, o yẹ ko lọ sinu ẹgbẹ mi-in ni, nitori PDP ti forukọ ẹni ti wọn mu ranṣẹ, yoo si ṣoro fun wọn lati fa orukọ Ladi yọ ki wọn fi tirẹ si i. Bi wọn ba fi orukọ Kaṣamu si i paapaa, ibo meloo loun naa ro pe oun le mu ni ipinlẹ Ogun, bawo lawọn araalu ṣe mọ ohun alara si ti yoo fi di gomina wọn. Awọn ohun to yẹ ki ọkunrin yii ro ree: ko wo bi yoo ti pari ija pẹlu ẹgbẹ rẹ; ati bi yoo ti tun orukọ ara rẹ ṣe laarin ilu. Bi ko ba ṣe eleyii, koda ko jẹ ẹgbẹ rẹ fiya jẹ ẹ lasan naa ni, yoo kan maa halẹ kiri ilu lai ni i ri nnkan kan ṣe si i ni. Ko ni i yatọ si ewurẹ to n binu olowo ẹ, afaimọ ko ma jẹ alapata ni yoo laja wọn.

 

 

(14)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.