Ilu Ọffa fi ọgọrun-un meje miliọnu ko teṣan fawọn olopaa

Spread the love

Minisita feto iroyin ati aṣa lorilẹ-ede Naijiria, Alhaji Lai Mohammed, ti ke si awọn ọlọpaa lati fi kun igbiyanju wọn lori igbogun ti iwa ọdaran nipinlẹ Kwara.

Mohammed sọrọ naa lasiko ti wọn n ṣi agọ ọlọpaa tuntun tawọn araalu naa kọ lati ran ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, niluu Ọffa.

Minisita naa ni gbogbo ohun to n ṣẹlẹ nipinlẹ naa ti fi han pe awọn ọdaran atawọn janduku ṣi gbode.

Lai Mohammed ni: “pẹlu ohun tawọn araalu Ọffa ṣe loni-in, wọn ti fun ẹyin ọlọpaa ni atilẹyin lati le gbogun ti awọn janduku, ẹgbẹ okunkun, adigunjale atawọn ọdaran mi-in kaakiri ipinlẹ Kwara.”

O ni alaafia ṣe Pataki, nitori ohun nikan lo le mu idagbasoke ba ilu, nitori naa,ki wọn kopa wọn bo ṣe yẹ lati le kawọ awọn abalujẹ ko.

O ni pẹlu idibo 2019 to n bọ atawọn eto to maa n waye ṣaaju idibo, ileeṣẹ ọlọpaa ni iṣẹ pupọ lati ṣe lati ri i daju pe aabo to peye wa fun awọn araalu lagbegbe wọn.

O gboriyin fawọn araalu fun ipese agọ ọlọpaa adigboluja (MOPOL), tuntun naa, paapaa julọ niru asiko yii.

Ọga ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria, Ibrahim Idris, ẹni ti kọmiṣana ọlọpaa, Lawal Jimeta, ṣoju fun sọ pe ibi ti wọn kọ agọ ọlọpaa naa si dara pupọ, nitori pe yoo fun wọn lanfaani lati dẹkun awọn iwa ọdaran to maa n ṣẹlẹ niluu Ọffa atawọn ipinlẹ bii Ekiti, Ọṣun ati Kogi to sun mọ ọn.

Ninu ọrọ tiẹ, Ọlọfa ti ilu Ọffa, Ọba Mufutau Gbadamọsi, ni ẹẹdẹgbẹrinmiliọnu Naira( #700m), lawọn lo lati fi kọ agọ naa laarin oṣu mẹfa.

 

 

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.