Ileepo, aadọta ile ati ọpọlọpọ dukia ṣofo sinu ijamba ina l’Ogbomọṣọ

Spread the love

Nnkan bii aadọta (50), ile, ileepo kan toun ti ọkọ epo to kun fun gaasi pẹlu ọkada mẹfa, atawọn dukia towo ẹ ko din ni aadọta miliọnu Naira (N50m), lo poora ninu ijamba ina kan to ṣẹlẹ laduugbo Gaa Lagbedu, nitosi ileejọsin Ijọ Onitẹbọmi, niluu Ogbomọṣọ.

 

Iwadii ALAROYE fidi ẹ mulẹ pe ina akara ti wọn n da nitosi ileepo lasiko ti wọn n ja gaasi sileepo kan to n jẹ Musalat Filling Station, laduugbo naa, lo fa ijamba ọhun ni nnkan bii aago mẹfa aabọ irọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.

 

Gbogbo ile to wa nitosi ileepo yii lo jona pata, titi dori ileewosan alabọọde kan to wa legbegbe naa. Apapọ dukia ti ko din ni miliọnu lọna aadọta lo si ba iṣẹlẹ ọhun rin.

 

Ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ileepo Musalat so pe nnkan bii wakati mẹta lo gba awọn panapana ki wọn too ri ina ọhun pa. Mẹta ninu wọn lo si fara pa lori akitiyan naa. bẹẹ nijamba ṣe olori awọn oṣiṣẹ ileepo ọhun.

 

Ọga awọn panapada to fopin si ijamba naa, Ọgbẹni Ṣeyi Awoyẹmi fidi ẹ mulẹ pe nnkan ti fẹẹ bọwọ sori ko too di pe wọn pe ileeṣẹ awọn, ati pe asiko kan wa ti awọn paapaa ni lati bila sẹyin nigba ti ina naa burẹkẹ tan pata ko too di pe Ọlọrun fun awọn ni aṣeyọri ṣe lati ri i pa lẹyin ifarapa rampẹ.

 

Obinrin to n ta omi atawọn ohun mimu ẹlẹridodo ni Gaa Lagbedu nibẹ, Abilekọ Bọla Arẹmu, sọ pe firiiji ati ọja ti oun padanu sinu iṣẹlẹ naa ko din ni miliọnu meji abọ Naira.

 

Ní ti Ọgbẹni Adeṣina Ifajinmi, ọkan ninu awọn olugbe adugbo ọhun ti ijamba naa ṣoju ẹ, o gba pe ileepo tọrọ yii kan lo jẹ ki ijamba ọhun pọ to bẹẹ.

 

O wa rọ ijọba lati wa nnkan ṣe si bi awọn eeyan ṣe maa n kọ ileepo si adugbo ti ọpọ eeyan n gbe, lati le maa dena ofo ẹmi ati dukia awọn araalu.

 

 

 

 

 

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.