Ileeṣẹ ọlọpaa yọ awọn SARS mẹrin ti wọn ji biṣọọbu gbe gbowo l’Ekoo

Spread the love

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ti ẹkun keji, CSP Dọlapọ Badmọs ti fi mulẹ pe igbakeji ọga agba ọlọpaa ti fọwọ si i pe ki wọn yọ awọn ọlọpaa SARS mẹrin kan; Adeoye Adekunle,  Adeniran Adebọwale, Lucky Agbi, ati Odighe Hehosa , ti gbogbo wọn n ṣiṣẹ ni ẹka F-SARS, iyẹn awọn ọlọpaa to n gbogun ti iwa idigunjale ti ijọba apapọ ṣagbekalẹ rẹ , eyi too wa ni Ikẹja niṣẹ.

Ẹsun ti wọn fi kan wọn, ti iwadii si fi mulẹ pe awọn ọlọpaa yii jẹbi rẹ ni pe wọn gbimọ-pọ lati ji ọkunrin kan, Chukwudi Odionye, ti inagijẹ rẹ n jẹ ‘Bishop’ gbe pamọ, ti wọn si gba miliọnu meje naira gẹgẹ bii owo idoola lọwọ rẹ. Ọjọ kẹrin ati ọjọ karun-un, oṣu kẹfa, ọdun too kọja ni wọn ni awọn afurasi yii huwa naa. Iṣẹlẹ yii ni  Chukwudi fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, lẹyin ti wọn tu u silẹ tan. Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye ninu iwe-ẹhonu to fi ṣọwọ si ileeṣẹ ọlọpaa, o ni ile oun too wa ni adugbo Alagbado niluu Eko loun wa lọjọ kẹrin, oṣu naa. Lojiji ni awọn ọlọpaa SARS yii wọle, ti wọn si ni awọn waa mu oun ni, ẹsun ti wọn si fi kan oun ni pe oun n ṣe ayederu iṣẹ iyanu, eyi toun fi n lu jibiti. Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye fun wọn, o ni ‘Lẹyin ti wọn mu mi tan, ni wọn gbe mi lọ si otẹẹli kan too wa ni Agege, nibẹ ni wọn si ti mi mọ, koda, wọn halẹ mọ mi pe awọn aa pa mi, ti mi o ba fọwọsowọpọ pẹlu awọn. Nigba to di ọjọ keji, ti i ṣe ọjọ karun-un, oṣu kẹfa, niṣe ni wọn tẹle mi de banki, ti wọn si fi tipa-tipa mu mi san miliọnu meje naira si asunwọn banki ọkan ninu wọn latori kọmputa, ko too di pe wọn tu mi silẹ.’

Ẹsun yii ni igbakeji oga agba ọlọpaa naa ṣewadii le lori, eyi to si fi mulẹ pe awọn olọpaa naa ko ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ, wọn ko si ṣe iwadii daadaa ki wọn o too mu bisọọbu, eyi to tako ofin to de iṣẹ naa. Awọn igbimọ oluwadii ti igbakeji ọga agba awọn ọlọpaa gbekalẹ lati ṣewadii ẹsun  naa fi mulẹ pe, nitori imo-taara-ẹni-nikan ni awọn oṣiṣẹ SARS naa fi ṣe ohun ti wọn ṣe yii, eyi lo si mu ki igbimọ naa da wọn lẹbi, wọn ni iwa ti wọn hu naa tako ilana ofin too de iṣẹ ọlọpaa SARS, bẹẹ ni wọn si jẹbi iwa ajẹbanu ati eyi to le ta epo si aṣọ aala ajọ naa. Badmos ni igbakeji ọga agba ọlọpaa naa ni eyi yoo jẹ ikilọ fun awọn too ba tun fẹẹ hu iru iwa yii, pẹlu alaye pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni i faaye gba iwa ibajẹ kankan bi ti i wu ko mọ laarin awọn oṣiṣẹ rẹ.

(36)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.