Ileeṣẹ ọlọpaa n wa Ọmọọba Ewenla, wọn ni oun lo ṣaaju awọn to bẹ ọpa epo l’Ekoo

Spread the love

Nitori pe wọn fura si i pe o lọwọ ninu bi wọn ṣe bẹ ọpa epo kan laduugbo Abule Ẹgba ati Agege, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti ni awọn n wa Ọnarebu (Amb)Prince Adeipọ Dauda Ewenla, wọn ni oun ni aṣaaju awọn ọdaran to huwa laabi naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Chike Oti, lo sọ eleyii di mimọ ninu atẹjade to fi ṣọwọ si awọn oniroyin. Ṣe lọjọ kọkandinlogun, oṣu to kọja yii, ni ina ṣẹ yọ nibi ọpa epo kan to wa laduugbo Abule Ẹgba ati ni Agege, nibi ti ọgọrun-un ile ati ọgọrun-un ṣọọbu pẹlu awọn ọkọ ayọkẹle to to aadọta niye ti jona guruguru. Lẹyin iwadii awọn ọlọpaa ni ọwọ tẹ awọn afurasi mẹrin ti wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ naa. Lasiko ti awọn ọlọpaa n fọrọ wa wọn lẹnu wo ni wọn ṣalaye bi ina ṣe ṣẹ yọ nibi ọpa epo bẹntiroolu  kan to wa laduugbo Abule-Ẹgba, to si tan kalẹ de agbegbe Agege, nibi ti ọpọlọpọ dukia ti jona guruguru.

Ninu ọrọ ti wọn sọ fun awọn ọlọpaa ni wọn ti darukọ Ọmọọba Adedipọ Dauda Ewenla bii aṣaaju ikọ awọn. Nigba ti awọn ọlọpaa wa Ewenla de ile rẹ, wọn ri i pe ọkunrin naa ti sa lọ si ipinlẹ Ogun, ki ọwọ awọn ọlọpaa ma baa to o.

Oti ni nnkan to le ṣe ọkunrin naa lanfaani ju ni ki o waa jọwọ ara rẹ fun awọn ọlọpaa, ko fi le sọ tẹnu rẹ lori ẹsun ti awọn ọdaran ti awọn mu fi kan an.

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.