Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti bẹrẹ iwadii lori awọn ti wọn pa ọmọleewe OAU

Spread the love

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, SP Fọlaṣade Odoro, ti sọ pe iwadii to nipọn ti bẹrẹ lori awọn ti wọn ṣe ọmọleewe Ọbafẹmi Awolọwọ tiluu Ileefẹ kan, Abiọdun Babalọla, ẹni to wa nipele kẹta ni ẹka iṣiro-owo leṣe, eleyii to yọri si iku fun un lọsẹ to kọja.

 

Odoro fi da gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun, paapaa, awọn araalu Ileefẹ loju pe laipẹ lọwọ yoo ba awọn ti wọn da ẹmi ọmọ ọhun legbodo.

 

Lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ to kọja lọhun-un, iyẹn Keresi ku ọtunla la gbọ pe awọn janduku kan ya wọ inu ilegbee awọn akẹkọọ ti wọn n pe ni Adam and Eve Hostel, eleyii to wa lagbegbe Parakin, niluu Ileefẹ.

 

Oniruuru nnkan ija oloro bii ada, igi, afoku igo, irin, ọbẹ ati oogun abẹnugọngọ la gbọ pe awọn janduku naa ko lo sibẹ lati lọọ fi dẹruba awọn akẹkọọ ni nnkan bii aago meji oru lọjọ naa.

 

Bi wọn ṣe debẹ, wọn pin ara wọn si gbogbo yara to wa nibẹ, foonu, owo, nnkan ẹsọ ara, aago-ọwọ atawọn nnkan eelo ile loriṣiiriṣii la gbọ pe wọn n gba lọwọ awọn akẹkọọ ọhun.

 

Wọn ko ba Biọdun ni yara tiẹ, yara ọrẹ rẹ kan lo sun ninu ile naa. Nigba ti wọn debẹ, awọn janduku yii ni ko fi Iphone ọwọ rẹ silẹ, ṣugbọn o kọ jalẹ, o loun ko ni i fi foonu yii silẹ, pẹlu ibinu ni wọn fi ṣa a lada yannayanna lati le fi kọ ọ lọgbọn.

 

Lẹyin tawọn janduku yii lọ tan, awọn ẹgbẹ Biọdun gbe e lọ sileewosan Obafẹmi Awolọwọ University Teaching Hospital (OAUTHC), ṣugbọn aitete ri itọju ti jẹ ko padanu ẹjẹ pupọ, aago mẹfa idaji ọjọ naa la gbọ pe akukọ kọ lẹyin ọmọkunrin.

 

Gẹgẹ bi ọkan lara awọn akẹkọọ-binrin to wa nilegbee tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, ṣugbọn ti ko fẹ ka darukọ oun ṣe sọ, o ni ọpọlọpọ nnkan ni wọn gba lọwọ awọn akẹkọọ lọjọ naa, wọn ko si fọwọ kan ẹnikẹni ti ko ba ti ba wọn ṣagidi.

 

O fi kun ọrọ rẹ pe oun ko le sọ pato iye awọn janduku naa, ṣugbọn oun mọ pe wọn pọ, wọn si pin ara wọn kaakiri awọn yara to wa nibẹ ni kete ti wọn de lọjọ yii. Akẹkọọ yii ni loootọ lawọn janduku ọhun ṣe awọn akẹkọọ mi-in ti wọn ko tete fọwọsowọpọ pẹlu wọn lese, ṣugbọn ti Abiọdun lo pọ ju, ati pe ai tete ri itọju to peye wa lara nnkan to ṣeku pa a.

 

Amọ sa, Odoro ti sọ pe ni kete ti ọwọ ba ti tẹ awọn eeyan ọhun, tileeṣẹ ọlọpaa si pari iwadii lori wọn, ni wọn yoo foju ba ile-ẹjọ.

 

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.