Ileeṣẹ ọlọpaa Eko ṣekilọ fun awọn awakọ

Spread the love

CSP Chike Oti, ti i ṣe Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti sọ pe oṣu kan pere ni anfaani ti awọn fun awọn awakọ lati fi gba awọn iwe-ọkọ to ba yẹ ki wọn ni, idi niyẹn ti awọn si fi sinmi fun ‘operation velvet’ ti awọn ti gun le tẹlẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni Gomina ipinlẹ Eko, Akinwumi Ambọde, ati awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ naa lo pẹtu si awọn ninu, ti wọn si ni ki awọn fun awọn eeyan yii lanfaani lati fi ṣe nnkan to yẹ.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ awọn ọlọpaa naa fi sita lo ti waa ṣekilọ pe awọn ko ni i fojuree wo ẹnikẹni to ba wakọ gba ọna BRT laarin oṣu kan ti awọn fẹẹ fi sinmi naa, nitori iwa to lodi si ofin irinna nipinlẹ Eko ni.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.