Ileeṣẹ ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori awakọ tanka ti wọn ni SARS pa l’Ekoo

Spread the love

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja ni agbẹnusọ awọn ọlọpaa nipinlẹ Eko, Chike Oti, fi atẹjade kan sita lori wahala to ṣẹlẹ laarin awọn awakọ tanka ati awọn ọlọpaa SARS laduugbo Ajegunlẹ, niluu Eko.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ni ọlọpaa SARS kan yinbọn pa awakọ tanka yii, o ni o kọ lati fun oun ni ẹgbẹrun kan Naira. Oṣiṣẹ SARS naa ni wọn gbe lọ si Ajegunlẹ lati lọọ koju awọn adigunjale to n yọ agbegbe Mile 2 si Apapa lẹnu. Niṣe ni wọn ni awakọ naa sọ fun ọlọpaa to n beere ẹgunjẹ yii pe ẹẹdẹgbẹta Naira (500.00), loun le fun un, eyi ni wọn lo bi oṣiṣẹ SARS naa ninu to fi yinbọn lu awakọ yii.

Ibinu iṣẹlẹ yii ni awọn awakọ tanka yooku fi ya bo ọlọpaa yii, ti wọn si lu u bii bara ko too di pe awọn ẹgbẹ rẹ gba a silẹ. Niṣe ni awọn awakọ tanka naa wa ọkọ wọn di ọna Apapa lati fẹhonu han.

Oti ni oun ko ti i gbọ hulẹ-hulẹ ohun to ṣẹlẹ gan-an, ṣugbọn Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Imohimi Edgal, ti ni ki awọn ṣewadii iṣẹlẹ naa, ẹni to ba i jẹbi yoo fimu danrin. O fi da awọn oniroyin loju pe awọn yoo sọ abọ iwadii awọn di mimọ fun gbogbo eeyan.

 

 

 

 

 

 

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.