Ile wo pa eeyan meji l’Agege

Spread the love

Lanaa ode yii ni ijamba buruku naa ṣẹlẹ, eyi to ṣeku pa Sherifat Ọlalere to jẹ ọmọ ọdun mẹsan-an ati Toyin Ogundimu to jẹ ọmọ ọdun marundinlogoji l’Agege ipinlẹ Eko.

A gbọ pe ile naa wo lasiko ti Sherifat n mumi lọwọ ninu ile idana wọn, ogiri ile idana yii naa lo wo pa Toyin.

A ri i gbọ pe baba Sherifat ti kilọ fun gbogbo awọn ọmọ ẹ pe wọn ko gbọdọ kuro ninu mọṣalaṣi to wa niwaju ile wọn titi ti oun yoo fi de, awọn ọmọ wọnyi si gbọrọ si i lẹnu, koda inu mọṣalaṣi yii ni wọn ti jẹun wọn, amọ nibi ti wọn ti n jẹun lọwọ ti Sherifat ti fẹẹ lọọ mu omi ninu ile ni aburu naa ṣẹlẹ, ti ile si wo pa a mọbẹ.

Ọkan ninu awọn olugbe ile naa, Tayọ Adekunle, ni koun too kuro ninu ile laarọ ọjọ Abamẹta loun ti ri birikila kan to fẹẹ ṣe awọn nnkan kan ninu ile yii, amọ lasiko to n ṣakojọ awọn nnkan ti yoo nilo lati fi tun ile naa ṣe lo wo.

Ijọba ipinlẹ Eko ti ti ile naa pa gẹgẹ bi ofin ṣe sọ

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.