Ile-ẹjọ tu igbeyawo ọdun mẹwaa ka l’Ado-Ekiti

Spread the love

Lẹyin ọdun mẹwaa ti wọn bẹrẹ ajọṣepọ, ile-ẹjọ kọkọ-kọkọ to fikalẹ siluu Ado-Ekiti ti tu tọkọ-tiyawo kan, Rabiu Tosin ati Rabiu Ayọdeji, ka.

Igbeyawo naa to so eso ọmọ meji, iyẹn Fathia to jẹ ọmọ ọdun mẹsan-an ati Faidat to jẹ ọmọ ọdun mẹta, lo han gbangba pe o ti tuka pẹlu ẹjọ ti olupẹjọ ati olujẹjọ ro.

Lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keji, ọdun yii, tigbẹjọ bẹrẹ ni Tosin rojọ pe gbogbo igba ni Ayọdeji maa n na oun, ti wahala kekere ba si ti ṣẹlẹ bayii, yoo da ẹru oun sita ni.

Ẹni ọdun mẹtalelọgbọn naa sọ pe lati ibẹrẹ ajọṣepọ ọhun ni olujẹjọ ti maa n huwa bẹẹ, ṣugbọn oun ro pe yoo yiwa pada. O ni ọjọ kan wa toun lọ si ọja, ṣe lọkọ oun si ti kẹru oun sita koun too de.

Obinrin to n gbe lagbegbe Bank Road, l’Ado-Ekiti, naa ni nigba toun bẹ Ayọdeji ko jẹ koun ko ẹru to ku, ṣe lo bẹrẹ si i lu oun, to si gba foonu toun n lo.

Eyi lo ni o mu koun pe iya-agba oun, ẹni to fẹẹ gba foonu naa pada, ṣugbọn ti ọkọ oun ko da lohun, bẹẹ lo tilẹkun pa.

O waa sọ pe owo lo maa n saaba da wahala silẹ nitori Ayọdeji ki i fẹẹ fowo silẹ nile, lọjọ toun ko ba si jẹ ko ba oun laṣepọ, ko sowo ounjẹ niyẹn.

O ni ki ile-ẹjọ naa tu awọn ka, ki wọn si ko awọn ọmọ foun nitori wọn ko le nitọju nile Iya Ayọdeji ti wọn wa.

 

Ṣugbọn olujẹjọ sọ pe ki i ṣe gbogbo igba loun n na Tosin, ẹẹkan pere ni. O ni oninu-fufu niyawo oun, gbogbo araale ati lanlọọdu gan-an lo maa n ba ja, eyi to jẹ kawọn ni wahala nibi tawọn n gbe.

Okunrin to n gbe lagbegbe Omiṣanjana, l’Ado-Ekiti, ọhun ni alagbere lobinrin naa, ẹnikan si ti wọ ọ lọ si aafin ri pe o n fẹ ọkọ oun.

O sọ siwaju pe ija kekere kan lawọn ja to fi ko kuro nile, ṣugbọn oun ti fọwọ si ipinya to n beere fun bayii. O waa bẹ kootu naa pe oun ni ki wọn ko awọn ọmọ fun.

Tosin ni Abilekọ Ọlayinka Akọmọlede to jẹ aarẹ kootu ọhun ni ko maa ko awọn ọmọ lọ lẹyin to woye pe awọn mejeeji ko nifẹẹ ara wọn mọ, bẹẹ lo ni ki Ayọdeji maa ṣan

ẹgbẹrun mẹta Naira gẹgẹ bii owo ileewe wọn fun ọmọ kọọkan loṣooṣu. O ni o lanfaani lati ri wọn nigba to ba wu u.

 

(21)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.