Ile-ẹjọ tu igbeyawo ọdun mẹsan-an ka, ọrọ ẹsin lo da wahala silẹ Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Spread the love

Ile-ẹjọ kọkọ-kọkọ to fikalẹ siluu Ado-Ekiti ti tu igbeyawo ọdun mẹsan-an to wa laarin Ayọdele Ọlaoye atiyawo rẹ, Oluwatoyin, ka.

Ayọdele lo wọ iyawo rẹ lọ si kootu lori ẹsun ija ojoojumọ, epe ati bo ṣe  kọ lati darapọ mọ ẹsin baale ile naa.

Ninu alaye to ṣe niwaju igbimọ igbẹjọ, ọkunrin ẹni ọdun mejidinlaaaọta naa sọ pe ọdun 2010 lawọn pade, odidi ọdun marun-un lawọn si fi gbe papọ. O ni laarin asiko naa lawọn bi Faith, ọmọ ọdun mẹfa, ati Otitọdele, ọmọ ọdun mẹrin, tawọn mejeeji jẹ obinrin.

O sọ ọ di mimọ pe lati ibẹrẹ lawọn ti mọ pe awọn ko bara awọn mu rara nitori pe iwa ati iṣe awọn yatọ.

Ayọdele to n gbe lagbegbe Odo-Ado, niluu Ado-Ekiti, ṣalaye siwaju pe, ‘’Iyawo mi fẹran ko maa bu mi, ko si maa ṣepe fun mi nitori ero ti mo ni nipa ọrọ ile aye. Ẹsin Grail Message ni mo n tẹle, ṣugbọn ko ba mi ṣe e lẹyin arọwa temi ati tawọn olori ẹsin ti mo n sin.

‘’Iyawo mi tun pe mi ni oloogun to fẹẹ fi awọn ọmọ wa ṣoogun owo. Ibi to waa pada gba yọ ni bo ṣe lọọ ba ọga mi nibi iṣẹ pe mo n ṣe ẹgbẹ okunkun, eyi to jẹ ki wọn gbe mi kuro nipo ti mo wa lọ sipo to kere. Nigba ti wahala naa pọ ju ni mo ko kuro nile fun un.’’

Baale ile naa waa rọ kootu ọhun lati tu ajọṣepọ naa ka kia, ki wọn si foun laṣẹ lati maa ri awọn ọmọ oun nigbakigba toun ba fẹ.

Nigba to n fesi sawọn ẹsun ọhun, Oluwatoyin ni ọdun 2015 lawọn tuka, ṣugbọn Ayọdele ṣi n wa sọdọ oun lẹẹkọọkan.

Ẹni ogoji ọdun to n gbe lagbegbe Mofẹrere, l’Ado-Ekiti, naa sọ pe ko si ootọ ninu pe oun lọọ fẹjọ sun ọga ọkọ oun, oun kan lọọ gba imọran lọdọ rẹ ni nitori bii baba lo jẹ sawọn.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, ‘’Ko si ootọ ninu pe nitori mo lọọ fẹjọ sun ni wọn ṣe da sẹria fun un, oun lo fiwe silẹ pe oun ko ṣiṣẹ mọ. Ko sigba ti mo ṣẹ awọn epe to ni mo n ṣẹ foun, ọrọ ẹsin lo si da awọn ija ta a ja silẹ.

‘’Ṣọọṣi Mountain of Fire la n lọ tẹlẹ, afi bi ọkọ mi ṣe deede ni ọdọ awọn Grail Message loun tun fẹẹ maa lọ, ṣugbọn mi o fọwọ si i.

‘’Latigba to ti n ṣe ẹsin yẹn niwa ẹ ti yipada, bo ṣe n mura naa ti yipada, bẹẹ lo tun maa n da sọrọ nigba mi-in.

‘’Lọjọ ti mo ko awọn ọmọ mi lọ sibi ile isin wọn, ayika ibẹ ko bojumu, o si da mi loju pe nnkan okunkun ni wọn n ṣe nibẹ.’’

Lẹyin alaye tọkọ-taya, Abilekọ Ọlayinka Akọmọlede to jẹ aarẹ igbimọ kootu naa sọ pe nnkan ti daru laarin awọn eeyan naa, ko si laatunṣe, eyi lo ṣe tu wọn ka.

O paṣẹ pe kawọn ọmọ wa lọdọ iya wọn, ki ọkọ si maa san ẹgbẹrun marun-un lori ọmọ kọọkan gẹgẹ bii owo ounjẹ loṣooṣu.

O ni Ayọdele naa ni yoo maa sanwo ileewe wọn, o si lẹtọọ lati ri wọn nigba to ba fẹ.

Bakan naa lo kilọ fun Oluwatoyin lori eebu, epe ati wahala to n ba olupẹjọ fa, o ni ko jawọ nibẹ ko ma baa ṣẹ sofin.

(43)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.