Ikunlẹ abiamọ o! Ọga onimọto, iyawo ẹ meji atawọn ọmọ wọn ku sinu ijamba mọto lOgbomọṣọ

Spread the love

Bi iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun ko tiẹ ṣoju eeyan, eti to ba gbọ ọ yoo si maa bẹru ati ko gbogbo ẹbi ẹ sọkọ rinrinajo lasiko kan naa pẹlu bi ọga awọn onimọto kan niluu Ogbomoṣọ pẹlu awọn meje mi-in ninu idile ẹ ṣe jẹ Ọlọrun nipe ninu ijamba mọto to waye lọna Ọyọ si Ogbomọṣọ lọsẹ to kọja.
Meji ninu awọn meje to ṣalaisi pẹlu ọkunrin naa to n jẹ Mufutau Gbadamọsi lo jẹ iyawo ẹ, nigba ti awọn marun-un yooku jẹ ọmọ ẹ.
Ni nnkan bii aago mẹfa aabọ aarọ Ọjọbọ, Tọsidee, niṣẹlẹ ọhun waye nigba ti ọkọ ayọkẹlẹ ti Gbadamọsi ati idile ẹ n gbe rinrinajo ọhun, eyi ti nọmba rẹ jẹ OYO XB 397 KKY nijamba, olori ẹbi funra ẹ lo si wakọ naa.
Ọkọ nla to n wọ́ mọto kan to taku sọna lọ ti nọmba rẹ jẹ LAGOS KTU 220 XC lo n bọ lati ọna Ogbomọṣọ lọ sọna Ọyọ, nigba ti ọkọ ayọkẹlẹ awọn Gbadamọsi n bọ lati ọna Agric, ti oun paapaa si n gbiyanju lati jade si ọna ti ọkọ nla ọhun n ba lọ.
Oṣiṣẹ ẹṣọ alaabo oju popo to fidi ẹ mulẹ sọ pe ere asapajude ti Oloogbe Gbadamọsi n sa lo ṣokunfa ijamba alagbara naa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, nibi ti ọga awọn onimọto naa ti n gbiyanju lati gba iwaju ọkọ to n wọ mọto rin ọhun kọja lasiko ti ko yẹ nijamba ti ṣẹlẹ.
Iroyin fi ye ni pe lasiko ti ọkọ awọn Gbadamọsi fẹẹ jade si oju ọna nla yii ni wọn ko sẹnu ọkọ nla naa. Nigba to si di pe wọn fẹẹ kọlura wọn, Ọgbẹni Gbadamọsi gbiyanju lati sare pẹwọ fun ọkọ nla naa lati le dena ijamba oju popo, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ
Womuwomu ni iwaju ọkọ ayọkẹlẹ Mazda alawọ pupa naa run bo awakọ atawọn ọmọ ẹ to gbe siwaju wọn mọlẹ. Aake lawọn ẹṣọ alaabo oju popo pẹlu awọn ẹlẹyinju aanu ni lati fi ṣa ọkọ naa ki wọn too le ri wọn yọ jade.
Bo tilẹ jẹ pe ọmọ ti wọn n pọn lẹyin ati awọn ọmọde pọ ninu ẹbi to n rinrinajo yii, to si jẹ niṣe ni wọn gbe ara wọn lẹsẹ, ninu mọto, bi Gbadamọsi pẹlu iyawo atawọn awọn ọmọ ẹ ṣe fun ara wọn mọ inu ọkọ ayọkẹlẹ kan ṣoṣo ọhun ti gbogbo wọn si jẹ mẹsan-an ninu ẹ ko ye ẹnikan
ALAROYE gbọ pe loju ẹsẹ ti ijamba ọhun waye ni mẹrin ninu awọn ọmọ naa ti ku. Bi wọn ṣe gbe awọn mẹrin to ṣi wa laye de ileewosan aladaani BOWEN, to wa niluu Ogbomọṣọ, fun itọju lọkan ninu wọn tun dagbere faye.
Ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun la gbọ pe awọn mẹta yooku to n gba itọju nileewosan ọhun wa titi ta a fi pari akojọ iroyin yii pẹlu bi ori gbogbo wọn ṣe bẹ́, ti gbogbo ara wọn si kun fun oriṣiiriṣii ọgbẹ́.
Orukọ diẹ ninu awọn to ba iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun rin ni Mufutau Gbadamọsi (baba), Hadija Gbadamọsi (iyaale), ati Idowu Gbadamọsi to jẹ iyawo keji, nigba ti orukọ awọn ọmọ wọn to ṣe kongẹ iku oro naa n jẹ Kudus, Muideen, Asisi ati abigbẹyin wọn to n jẹ Yinusa.
Abigbẹyin ti wọn pe ni Yinusa la gbọ pe ko ti i ju ọmọ oṣu kan pere lọ pẹlu bo ṣe jẹ pe ninu oṣu kẹsan-an to kọja yii ni wọn ṣe ayẹyẹ isọmọlorukọ ẹ nile wọn nigboro ilu Ogbomọṣọ.
Ko too di pe iku yọwọ kilanko ẹ lawo, Gbadamọsi ni wọn pe ni alaga ẹgbẹ awọn awakọ (NURTW) nibudokọ Ahóyaya, niluu Ogbomọṣọ.
Ẹka ti wọn n ṣe awọn oku lọjọ si nileewosan ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa niluu Ogbomoṣọ la gbọ pe wọn gbe awọn to padanu ẹmi wọn sinu iṣẹlẹ yii lọ.
Ọkan ninu awọn dokita ileewosan ọhun, Dokita Victor Backo, fidi ẹ mulẹ pe ileewosan awọn nibẹ ni wọn gbe awọn mẹjẹẹjọ to ku sinu ijamba mọto naa wa ni nnkan bii aago meje kọja ogun iṣeju aarọ ọjọ naa.

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.