Ikọ operation Burst pa adigunjale mẹta ni Ibadan

Spread the love

Ikọ ajumọṣe eto aabo ipinlẹ Ọyọ, ‘Operation Burst’ ni wọn ti pa mẹta ninu awọn adigunjale ẹlẹni mẹfa kan ti wọn maa n yọ awọn araadugbo Adegbayi, niluu Ibadan, lẹnu.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, o ti to ọsẹ mẹta ti awọn adigunjale naa ti n ṣọṣẹ ni agbegbe yii. Oludamọran pataki lori eto aabo si Gomina Ajimọbi ti ipinlẹ Ọyọ, Ṣẹgun Bọlarinwa, sọ pe ikọ eleto aabo naa ni wọn pe ni ipe pajawiri lasiko ti awọn adigunjale naa n ṣọṣẹ nileetura Emirate to wa laduugbo yii. Bọlarinwa ni meji ninu wọn lo ti wa lọdọ awọn ikọ eleto aabo naa, ti ọkan ninu wọn si sa lọ pẹlu ọgbẹ ibọn.

(40)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.