Ijọba ologun le Fẹla kuro ni Naijiria poo! Ọdun 1977 ni

Spread the love

Nigba ti awọn Fẹla sare de City Hall, nibi ti wọn ti n mura lati ṣere fun gbogbo ilu ti wọn kan awọn ṣọja, aya awọn naa ja. Wọn ti ti ibi ti wọn yoo ti ṣe ere pa, wọn ko si jẹ ki wọn ko awọn irinṣẹ ti wọn yoo lo wọle sibẹ. Koda, wọn ko jẹ ki wọn sun mọ ibẹ rara, awọn ṣọja duro tibọn-tibọn ni, awọn mi-in si mu koboko to gun jan-anmi kan bayii dani, bi ẹnikẹni ba sun mọ wọn ti wọn ba wa a nikan ẹ, tọhun yoo maa mumi si i ni. Fẹla wo awọn maneja rẹ ti wọn yi i ka ati awọn ọmọ elere rẹ ti wọn tẹle e, gbogbo rẹ si su oun paapaa, koda, bo ti jẹ alagidi to. Ko si ọkankan laarin awọn ṣọja naa to le pe mọra ki wọn tilẹ jọ sọrọ boya ọrọ wọn aa jẹ ye ara wọn tabi ohun to ṣẹlẹ yoo ye e, awọn godogodo ṣọja Hausa to jẹ eewọ lede oyinbo lọdọ wọn ni wọn wa nibẹ, wọn ko mọ kinni kan ju bilala ati ibọn ọwọ wọn lọ.

Awọn ti wọn fi wọn sibẹ paapaa bi wọn ba de ọdọ wọn, Hausa ni wọn fi n ba wọn sọrọ, eyi ti ko ba si ti gbọ Hausa daadaa ninu awọn ọga wọn paapaa ko le sun mọ wọn. Iru awọn ṣọja bayii ni wọn ko sibẹ, Fẹla si mọ pe oun ko le sun mọ wọn, nitori bi oun sun mọ wọn, ko si ọrọ gidi ti yoo ti ẹnu wọn jade soun, afi ti wọn ba maa bẹrẹ ija pẹlu oun. Bẹẹ aṣiwere eeyan ni yoo maa ṣagidi pẹlu ibọn, nitori bi ibọn ba dahun lojiji, alagidi yoo gbọrun lọ ni, ibọn yoo si wa nibẹ, ẹni to gbe e dani paapaa yoo maa ṣe aye rẹ lọ. Ṣugbọn inu Fẹla ko dun rara o, abi ta ni yoo ṣe! “Ki lo n ṣe awọn eeyan yii! Ṣe wọn fẹẹ pa mi patapata ni!” Awọn ọrọ to n jade lẹnu rẹ ree nitori ko mọ ohun mi-in ti yoo tun sọ. Awọn ṣọja ti dana sun ile rẹ, wọn si gba ilẹ ọhun lọwọ ẹ, wọn lo ti di tijọba. Wọn ti otẹẹli to ti n ṣere pa, ibomi-in to ti fẹẹ ṣere lawọn ṣọja tun ti pa yii!

Boya nitori pe iṣẹ ofin lo fẹẹ kọ tẹlẹ ko too di oṣere ni o, ko sẹni to mọ, ṣugbọn kinni kan ti awọn eeyan mọ Fẹla mọ naa ni pe ki i rufin, loootọ iwa ti yoo hu yoo jọ ti arufin gan-an. Eyi lo ṣe maa n ṣoro fawọn ọlọpaa lati ri i sọ sẹwọn, nitori nigba ti wọn ba ro ẹjọ naa lọ ti wọn ro o bọ, Fẹla yoo jare wọn. Ohun ti ijọba Ọbasanjọ igba naa ko si fẹ gan-an ree, wọn mọ pe bo ba gbe awọn ṣọja yii de ile-ẹjọ ti wọn fi ri ẹjọ naa ṣe daadaa, yoo jare wọn, owo ti yoo si gba lọwọ wọn yoo to o lati fi kọle nla mi-in, bẹẹ ni wọn yoo si gba ile rẹ ti wọn gba lọwọ ẹ pada, wọn yoo ni wọn ko lẹtọọ lati gba ile to fi owo rẹ kọ, ati ilẹ to ni lati ọjọ to pẹ. Iyẹn ni wọn ṣe n sa fun un, ti wọn ko ṣe ba a de ile-ẹjọ, ọna kan ṣoṣo naa ti wọn si mọ ni agidi, iyẹn lati fi ipa mu un, lo ṣe jẹ bo ba ti ṣe ohun kan tabi ti ọrọ ba ti pa wọn pọ, awọn ṣọja ni wọn yoo lo fun un.

Nigba ti Fẹla ti ri i pe awọn ṣọja ti wọn wa ni City Hall yii ko ṣee baja, ti wọn ko si ṣee sun mọ, o ni ki awọn maneja rẹ jẹ ki awọn maa lọ. Bẹẹ ni wọn ko si ọkọ, wọn si lọ. Awọn maneja ti wọn fẹẹ maa binu, Fẹla sọ fun wọn pe wọn ko le ba awọn ṣọja ti wọn wa nibẹ ja, nitori iṣẹ ti wọn ran wọn lawọn n jẹ, aṣẹ ti wọn pa fun wọn ni wọn n mu ṣẹ, koda, awọn ko mọ ohun to n ṣẹlẹ, wọn ko si mọ kinni kan ninu ọrọ to wa nilẹ yii, bi eeyan ba fẹẹ ja rara, awọn ọga wọn to ran wọn niṣẹ ni eeyan yoo doju ija kọ. Fẹla ni ko si ija kankan ninu ọrọ yii mọ, ile-ẹjọ lawọn yoo pada si, ki maneja tete lọọ pe awọn to ni City Hall lẹjọ, ki ile-ẹjọ le sọ fun wọn pe wọn ko laṣẹ lati ti gbọngan nla naa pa pe ki awọn ma ṣere nibẹ nigba ti wọn ti gba owo ibẹ lọwọ awọn. Fẹla nigbagbọ pe ile-ẹjọ yoo da awọn lare.

Bayii ni lọọya awọn Fẹla gba ile-ẹjọ lọ, Tunji Braithwaite, akọni niwaju adajọ. Oun lo pe ẹjọ lorukọ ẹgbẹ akọrin “African 70 Organisation”, ẹgbẹ olorin Fẹla lo n jẹ bẹẹ. Nigba ti lọọya naa n lọ, o mu ọkunrin ti wọn n pe ni Ọladipọ Ọjọmọ dani, ọkan ninu awọn maneja Fẹla ni. Ọkunrin yii lo ba Lagos City Hall ṣadehun, oun lo sanwo, orukọ rẹ lo si wa ninu risiiti pe oun fẹẹ lo ibẹ, nitori pe awọn Fẹla fẹẹ ṣere lo ṣe gba ibẹ, ki i ṣe pe o ni nnkan mi-in to fẹẹ ṣe.Tunji Braithwaite naa ti mọ pe iru ẹjọ yii ki i ṣe ẹjọ ti i pẹ rara, ko-lọ-nilẹ-ko-dowo ni. O ni Ọlọrun ti ba oun mu awọn ijọba ologun yii, ko si ibi ti wọn yoo gba yọ bọ lasiko yii, wọn ti ko si awọn lọwọ, awọn naa yoo si fi imu wọn danrin.Wọn ni owo rẹpẹtẹ ni awọn Lagos City Hall yoo san, nigba ti wọn ba si sanwo fun Fẹla, laye wọn, wọn ko tun ni i ṣe iru rẹ mọ.

Iwaju adajọ kan ti wọn n pe ni Adajọ Ademọla Candido Johnson ni wọn gbe ẹjọ naa lọ, bẹẹ ni ki i ṣe pe wọn kan gbe ẹjọ naa siwaju ẹ, wọn tun fi awọn kọndiṣan kan le e. Ẹbẹ ni wọn bẹ adajọ naa, wọn ni ẹjọ ti awọn gbe wa ki i ṣe eyi ti i pẹ rara. Wọn ni ẹjọ pajawiri ni. Idi ti ko si ṣe gbọdọ pẹ ni pe wọn ni ọjọ meji ni Fẹla mura lati ṣere nibẹ, ṣugbọn awọn ijọba ologun ti wọn laṣẹ lori Lagos City Hall yii ko jẹ ko ṣere nibẹ ni ọjọ akọkọ, ọjọ keji lo si ti tun sun mọle yii, ko ma di pe wọn ko ni i jẹ ko ṣere nibẹ lawọn ṣe tete wa, ki ile-ẹjọ le da awọn lare kia, ki Fẹla si le maa ṣe ere rẹ lọ. Ṣe loootọ, ọjọ meji ni Ọladipọ Ọjọmọ buuku. Ọjọ akọkọ ni ọjọ Satide ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun 1977, ọjọ keji si ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ karun-un, oṣu keje, 1977. O ni idi pataki ti wọn ṣe buuku awọn ọjọ mejeeji yii bayii. Nitori pe irin-iṣẹ wọn ki i ṣe eyi ti wọn le maa ko kiri laulau ni gbogbo igba, ti wọn ba ti ṣere nibẹ, afi ki wọn fi i silẹ ki wọn tun le ri i lo lẹẹkeji si i. Wọn ti mọ pe yoo ṣoro ki awọn to irinṣẹ naa kalẹ ni ọjọ Satide tan, ki awọn tu u lọjọ Sannde, ki awọn tun maa waa pada to o ni ọjọ Mọnde. Iyẹn ni wọn ṣe ṣe ọjọ keji naa bẹẹ, wọn yoo ṣere ni ọjọ ti oṣu Juunu pari gan-an, wọn yoo si tun ṣere ni ọjọ Iṣẹgun akọkọ ninu oṣu Julai. Nigba ti ijọba ti waa fagile e, ti wọn ko jẹ ki wọn lo ibẹ ni ọjọ Satide, iyẹn ni wọn ṣe sare gba ile-ẹjọ lọ ni Mọnde, ti wọn sare pe ẹjọ naa, ti wọn si bẹ Adajọ Candido Johnson ko le ba wọn gbọ ẹjọ naa kiakia. Ṣugbọn adajọ naa ko tete raaye, o sun ẹjọ siwaju, o sun awọn mi-in sẹyin, ko si ri ọna to le gba gbọ ẹjọ awọn Fẹla, afi ni ọjọ karun-un, oṣu keje, 1977, gan-an

!

Bẹẹ ni. Ọjọ karun-un, oṣu keje, yii ni ọjọ ti wọn yoo ṣere ni Lagos City Hall, Fẹla si ti ni ki awọn ọmọ elere rẹ ko irinṣẹ ati gbogbo ẹrọ wọn sitosi, bi wọn ba ti da awọn lẹjọ bẹẹ, awọn yoo mu awọn beliifu lati lọọ gbe iwe ẹjọ le awọn ṣọja lọwọ ni. Yatọ si pe wọn yoo ṣere lọjọ naa, wọn yoo tun sọ pe ki awọn to ni Lagos City Hall sanwo foun, bẹẹ ni wọn yoo si fun un laaye lati maa ṣere nibẹ nigbakigba to ba fẹ. Gbogbo eleyii ni wọn beere fun ninu ẹjọ ti wọn pe, wọn si ti mọ pe bi adajọ ba ti da ẹjọ yii bẹẹ, ko si wahala kankan. Braithwaite tilẹ ti sọ fun Fẹla pe ko si ọna meji ti wọn yoo fi da ẹjọ naa, gbogbo ohun ti awọn beere fun ni adajọ yii yoo fun awọn, nitori oun naa kuku mọ pe ododo ọrọ lawọn n sọ, ododo lo wa nilẹ yii, ko si si ohun ti ijọba ṣọja, tabi Ọbasanjọ, tabi Danjuma, olori awọn ṣọja, le ṣe si i.

Ọrọ naa tilẹ kuku ti tun kari ilu, ṣe ẹni to gbe adiẹ otoṣi lọrọ Fẹla, o ti gbe ti alaroye, nitori ariwo ni ọrọ naa yoo da, ko si ni i si ibi ti wọn ko ti ni i gbọ bo ti n lọ ati bo ti jẹ gan-an. Ori ero ati ori ariwo ni Fẹla funra rẹ mu wa saye, ohunkohun to ba n ṣe, ati nibikibi to ba wa, awọn ero yoo kuku kan maa ya lọ sibẹ ni. Bo ti ri niyi nigba ti wọn tun gbọ pe Fẹla pe awọn Lagos City Council lẹjọ, nitori wọn ko jẹ ki oun lo ibẹ lati ṣe ere oun. Awọn ero pe si ile-ẹjọ lọjọ naa, awọn mi-in si ti mura pe ko si pe awọn n pada lọ sile mọ, bi wọn ba ti le da Fẹla lare, lati ile-ẹjọ naa lawọn yoo ti gbe e lọ si gbọngan iṣere naa ni City Hall, awọn yoo si duro ti i titi ti yoo fi to irinṣẹ rẹ, ti yoo bẹrẹ ere ni, bi ṣọja kan ba duro tabi to ba sọ pe ki awọn ma wọle lẹyin ti ile-ẹjọ ti da awọn lare yii, awọn yoo jọ na an tan bii owo ni. Iyẹn lero ṣe pọ nile-ẹjọ o.

Bi eeyan ba de ile-ẹjọ lọjọ yii, yoo ro pe ẹjọ naa le ju bẹẹ lọ ni, yoo ro pe ọrọ ti wọn n fa yii, ọrọ to le da ijọba ologun Naijiria ru ni. Awọn lọọya pe lọ biba ni o. Awọn lọọya nla nla. Tunji Braithwaite lo ṣaaju, bẹẹ lawọn bii Alao Aka-Baṣọrun lawọn yoo ran an lọwọ, ati Kanmi Iṣọla Osobu, ati Olu Onagoruwa, nitori gbogbo awọn yii ni ajafẹtọ-ọmọ-eniyan nigba naa, wọn si mọ pe ohun tawọn ijọba ṣọja n ṣe fun Fẹla yii, wọn n fi ẹtọ rẹ dun u ni, wọn n fi iya jẹ ẹ lai nidii, wọn kan fẹẹ ba iṣẹ aje rẹ jẹ ni. Ohun to jẹ ki gbogbo wọn ya lọ si ile-ẹjọ ree, wọn fẹẹ gbọ ẹjọ ti adajọ naa yoo da, ati bi yoo ṣe ṣe ọrọ naa. Adajọ paapaa ri awọn lọọya wọnyi ẹru ba a, sibẹ, o kanri mọ iwe rẹ, o ni ohun ti kaluku gbọdọ mọ ni pe oun ko ni i dajọ naa lati fi ṣegbe eeyan, ohun ti ẹjọ ba wi, ti ẹri ba sọ lori ọrọ yii loun yoo sọ jade.

Iyẹn lonikaluku ṣe bẹrẹ si i rojọ o, ti ati adajọ atawọn eeyan si tẹtilelẹ, ti wọn n gbọ ẹjọ onikaluku. Ọladipọ Ọjọmọ ti i ṣe maneja awọn Fẹla naa lo kọkọ rojọ, ṣe oun gan-an lọrọ kan, oun lo ri ile to ri ode. O ni oun loun lọọ sanwo fun awọn ti wọn ni Lagos City Hall, owo ti oun si lọọ san fun wọn naa ni pe awọn fẹẹ lo gbọngan wọn lati fi ṣe ere, ọjọ meji loun si buuku, gbogbo owo ti wọn si beere lọwọ oun loun san. Bẹẹ ni wọn ko kọ iwe soun lẹyin ti wọn ti foun ni risiiti pe ki oun ma waa lo ibẹ mọ, wọn ko tilẹ ba oun sọ kinni kan, afi nigba ti awọn debẹ lọjọ naa lati to irinṣẹ awọn to jẹ awọn ṣọja lawọn kan nita, ti wọn si fi aake kọri, ti wọn ni bi awọn ba fi le sun mọ awọn, awọn yoo fi ara gbọta. Ọkunrin naa ni ko si bi awọn ti le sun mọ awọn eeyan yii lọjọ naa, nitori niṣe ni wọn n sọrọ pẹlu ikanra, toju wọn si le koko.

Maneja Fẹla yii ni ọrọ kekere kọ lọrọ naa, nitori awọn ti wọn ni Lagos City Hall ba iṣẹ aje awọn jẹ, gbogbo owo ti awọn ti na, gbogbo ipolowo ti awọn ti ṣe, gbogbo awọn ero ti awọn ti pe, gbogbo owo ti awọn ti fi ra ohun ti awọn fẹẹ lo ati awọn eelo gbogbo ti awọn ti ko jọ, pẹlu awọn eyi ti awọn rẹnti ti awọn ti sanwo fun, gbogbo rẹ lo bọ si igbo atuu, awọn ko si ri kọbọ gba pada ninu owo ti awọn na, gbogbo owo naa lo bomi lọ. O ni ohun to waa jẹ ki awọn wa ni pe awọn fẹẹ gba owo ti awọn na, awọn fẹẹ gba a ko pe perepere, ki awọn si tun gba ere to yẹ ki awọn jẹ, nitori awọn ni wọn yẹ adehun, awọn ni wọn ko jẹ ki awọn ṣere mọ. Yatọ siyẹn, Ọjọmọ ni ki ile-ẹjọ yaa tete paṣẹ fun awọn ti wọn ni Lagos City Hall yii pe ki wọn jẹ ki awọn lo o loni-in yii, nitori awọn ti tun dana ere awọn sibẹ, wọn ko si gbọdọ tilẹkun mọ awọn.

Gbogbo ile-ẹjọ kun lọ hun-un nigba ti maneja Fẹla ro ẹjọ rẹ, Adajọ Candido Johnson paapaa si miri jege, o sare tun dorikodo, o si n kọwe lọ bii arira, ko sẹnikan to mọ ohun to n kọ. Lẹyin to ti kọwe rẹ tan lo ni ki wọn mu maneja awọn Lagos City wa, ki oun ati lọọya wọn bọ siwaju, ko waa sọ tẹnu rẹ, ki wọn le mọ iru ẹjọ ti wọn yoo da fun wọn. Awọn eeyan tilẹ ti n sọ pe ko si ẹjọ ti wọn yoo da, ko si si ọna fun ọlọtẹ, yoo gbawe ibanujẹ ni. Awọn lọọya to tẹle Fẹla wa naa ti dide naro, wọn gbe iwe bamba bamba dani, ẹlomi-in fi gege rẹ ha koro eti ninu wọn, wọn fẹẹ mọ ohun ti awọn to ni Lagos City Hall yoo sọ, nitori lẹyin ọrọ wọn ni wọn yoo da ibeere oriṣiiriṣii bo wọn, ki wọn le fi han gbogbo aye pe irọ ni wọn n pa. N lawọn maneja Lagos City Council ba bọ siwaju adajọ o, pẹlu awọn lọọya tiwọn naa.

Ohun ti wọn kọkọ sọ to ya gbogbo eeyan lẹnu ni pe wọn ni awọn ko mọ Fẹla tabi ẹgbẹ akọrin kan to n jẹ “African 70 Organiasation”, bẹẹ ni awọn ko ni adehun kankan pẹlu wọn. Wọn ni Fẹla ko wa sọdọ awọn, ko sọ pe oun fẹẹ ṣere, bẹẹ ni ẹgbẹ ‘African 70’ naa ko sọ pe oun fẹẹ waa ṣere lọdọ awọn, bi wọn ṣe waa wa sile-ẹjọ ti wọn ni awọn ko jẹ ki awọn ṣere yii, nnkan iyanu gbaa lo jẹ fawọn. Wọn ni bo ba jẹ ti ọkunrin to duro yii, iyẹn Ọladipọ Ọjọmọ, wọn ni awọn mọ oun daadaa, adehun si wa laarin awọn, nitori o wa si ọdọ awọn pe oun fẹẹ rẹnti ọọlu awọn, awọn si fi gbọngan naa silẹ fun un. Ni aaye to ti yẹ ko kọ ohun to fẹẹ ṣe nibẹ, ko kọ ọ sibẹ, o kan faala lasan si i ni. Koda, ko fi adirẹsi ile Fẹla tabi ti ẹgbẹ rẹ si i, ko si sọ pe nitori wọn loun ṣe waa gba ọọlu, oun fẹẹ lo ọọlu lo sọ fawọn.

Adajọ gbọ ọrọ naa, awọn lọọya naa gbọ, ṣugbọn kinni naa ko tete ye awọn ero iworan, awọn mi-in paapaa n beere lọwọ ara wọn pe ki lo n sọ, “Abi ẹ ẹ gbọ, o ma loun o mọ Fẹla ri!” Loju gbogbo awọn ti wọn gbọ ọrọ naa, isọkusọ lo jọ. Ṣugbọn ọrọ ko jọ bẹẹ loju adajọ, niṣe lo ni ki wọn mu risiiti ti wọn kọ fun Ọjọmọ wa, ati fọọmu ti Ọjọmọ fiili nigba to sanwo. Ninu fọọmu loootọ, orukọ Ọjọmọ lasan ati adirẹẹsi ile rẹ lo wa nibẹ, nibi to si ti yẹ ko sọ pe awọn yoo ṣere nibẹ ko kọ ọ si i, o kan faala lasan si i ni, ko sọ ohun ti awọn fẹẹ lo ibẹ fun. Boya o mọ-ọn-mọ ṣe eyi ni o, tabi ko ka a si, oun nikan lo le ṣalaye. Ṣugbọn ọrọ naa lo di wahala nile-ẹjọ, awọn lọọya ja titi lori ẹ, ṣugbọn ibi kan naa lọrọ n ja si, ko sorukọ Fẹla tabi ti ẹgbẹ rẹ ninu risiiti tabi ninu fọọmu, eyi ni pe ọrọ naa ko kan Fẹla rara.

Awọn ti Fẹla pe lẹjọ naa ni ṣe awọn naa ri i, awọn ko ni adehun kan pẹlu Fẹla pe yoo lo ọọlu awọn, afi bi awọn ṣe bẹrẹ si i gbọ ariwo lojiji lori redio ati ninu beba pe Fẹla fẹẹ waa ṣere lọdọ awọn. Wọn ni awọn yẹ iwe awọn wo, awọn ko si ri orukọ rẹ ninu risiiti awọn. Wọn ni elere nla ni Fẹla, o si ni ọpọ ero lẹyin, bo ba waa fẹẹ ṣere niru ọdọ awọn, o ni awọn eto aabo ti awọn gbọdọ ṣe, ṣugbọn nigba ti ko sorukọ rẹ ninu awọn to buuku ọọlu ibẹ, awọn ko le ṣeto aabo kan, ki ọrọ ma si ṣe di wahala lawọn ṣe tilẹkun awọn pa, ti awọn si bẹ awọn agbofinro ki wọn ma jẹ ki ẹnikẹni wọ ibẹ. Ọrọ ti pesi jẹ o, nitori ẹjọ ti adajọ da naa niyẹn, o ni ofin ko mọ Fẹla ninu ẹjọ to pe yii, nitori ọrọ to wa nilẹ yii ko kan an rara, bi ẹjọ kan ba wa ninu ọrọ yii, Ọjọmọ ni yoo pe ẹjọ, ṣugbọn ko ṣọra rẹ paapaa, nitori oun naa ko sọ ohun ti oun fẹẹ fi ọọlu to waa gba ṣe fawọn to ni in, eleyii si le gbe ẹjọ rẹ ṣubu.

Ọrọ naa jo Fẹla ati awọn eeyan rẹ lara, owo gbogbo lo wọ igbo atuu bayii, ko si jọ pe ijọba ologun yoo pada lẹyin rẹ bọrọ. Nigba naa lọkunrin olorin naa binu, o ni oun ko ni i duro ni Naijiria mọ, oun yoo fi Naijiria silẹ fun wọn. Njẹ nibo ni Fẹla n lọ? Fẹla ni ilu odikeji loun n lọ, oun yoo maa lọọ ṣere oun ni Ghana, nibi ti awọn araaye yoo ti maa gbohun oun. Bayii ni Fẹla tun bẹrẹ si i mura Ghana.

 

(27)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.