Ijọba Ogun yi ipinnu pada lori wiwo ẹgbẹrun ile

Spread the love

Ṣẹnkẹn ni inu awọn eeyan adugbo Workers Estate, Laderin, niluu Abẹokuta, n dun bayii pẹlu bi ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Ogun ṣe fẹnuko lati dawọ ibudo reluuwee ti wọn fẹẹ kọ sibẹ duro, ti ẹgbẹrun kan ile ti wọn ti ya sọtọ lati wo lulẹ ko si ni i jẹ wiwo mọ, nitori ijọba ti wa ibomi-in ti wọn yoo gbe ibudo reluwee naa lọ bayii.

Akanṣe iṣe to jẹ tijọba apapọ ni ibudo reluwee yii, eto ti wọn si ṣe kalẹ ni pe Workers Estate to wa ni Laderin ni wọn yoo kọ ọ si, ti wọn si ti fi ami si ara ile ti ko din lẹgbẹrun kan pe afi ki ijọba wo wọn palẹ, ki eto reluwee naa too le bọ si i.

Ṣugbọn pẹlu abẹwo minisita fun igbokegbodo ọkọ lorilẹ-ede yii si ipinlẹ Ogun lọjọ Aiku, Sannde, ijẹta yii, Ọgbẹni Rotimi Amaechi, ati ifikunlukun oun ati gomina ipinlẹ naa, Sẹnetọ Ibikunle Amosun, eto naa yipada. Wọn fẹnuko si pe ki wọn kuku gbe ibudo reluwee naa lọ si Moshood Abiọla International Trade Fair Complex, iyẹn ile itaja nla to wa loju ọna Kọbapẹ, Oke-Mosan, l’Abẹokuta.

Amaechi waa sọ pe ayipada yii ko ni i di pipari ibudo naa lọwọ rara, oṣu kejila, ọdun yii, tijọba fun awọn oṣiṣẹ ti wọn n ṣiṣẹ nibẹ lati pari ẹ naa ni wọn gbọdọ pari ẹ. Yatọ si ibudo reluwee yii, minista naa ṣalaye pe ijọba yoo tun kọ ile itura ati ile itaja igbalode sibẹ pẹlu.

Bakan naa ni Gomina Amosun sọ ọ di mimọ pe ijọba yoo wa ibomi-in to yẹ lati gbe ile itaja to fẹẹ di ibudo reluwee naa lọ. Yatọ si pe ayipada yii yoo jẹ kawọn ti wọn fẹẹ wole wọn tẹlẹ fọkan balẹ pe ko sohun to jọ bẹẹ mọ, yoo tun din owo gọbọi tijọba ko ba san bii gba ma-binu fawọn eeyan naa ku gidi.

Biliọnu mẹta din diẹ Naira (2.8billion) ni wọn ti yatọ sọtọ lati san fawọn onile Laderin tẹlẹ, ṣugbọn pẹlu eto tuntun yii, owo naa ko le to bẹẹ mọ rara.

Nigba to n sọrọ siwaju si i lori eto ile wiwo, Gomina Ibilunke Amosun ṣalaye pe ki i ṣe ohun to dun mọ oun lati maa wo ile awọn eeyan, o ni nigba ti ko ba si ọna mi-in mọ ni ijọba maa n gbe igbese ile wiwo.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ilu Eko, l’Ebute-Mẹta, ni wọn ti bẹrẹ iṣẹ ọna reluwee ti yoo gba Ibadan kọja, ti yoo si pari siluu Kano yii (Lagos-Ibadan-Kano Rail Project), ni wọn pe e.

Ọna reluwee yii lo ni lati gba Papaplanto, nipinlẹ Ogun kọja, ko too de Ibadan, ti Kano yoo si jẹ ibudokọ igbeyin fun un. Papalanto yii ni wọn ti ya sọtọ tẹlẹ pe ibudo yoo wa, ṣugbọn nitori iṣẹ gbagede okoowo to n lọ lọwọ nipinlẹ naa, iyẹn Abeokuta Central Business District, ijọba ipinlẹ yii bẹ ijọba apapọ pe ki wọn kuku gbe ibudo reluwee ọhun wa si Abẹokuta, ko le rọrun fawọn ero to ba fẹẹ wọkọ.

(31)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.