Ijọba Ogun bẹrẹ ajọṣe pẹlu France lori eto Ilẹ Dọtun

Spread the love

Abẹwo ti aarẹ orilẹ-ede France, Emmanuel Macron, ṣe sorilẹ-ede wa lọsẹ to kọja ti so eso rere fun ipinlẹ Ogun, nitori ijọba ipinlẹ naa ti tọwọ bọ iwe ajọṣe lori sisọ eeka ilẹ ẹgbẹrun kan ati mẹjọ dọtun lawọn ilu bii Imẹkọ ati Aworo nipinlẹ Ogun.

Gomina ipinlẹ yii, Aṣofin Ibikunle Amosun tọwọ bọwe adehun naa nilee ijọba l’Abuja, niṣoju Aarẹ Muhammadu Buhari atawọn ikọ orilẹ -ede France to wa nibẹ lọjọ kẹta oṣu yii.

Ohun pato ti ajọṣepọ ọlọdun mẹẹẹdogun naa wa fun ni lati sọ awọn ilẹ ti wọn ya sọtọ bii igbo ọba di ohun ti yoo wulo fun iṣẹ ọgbin, ẹja sinsin, ipese ayika to le mu alaafia ba ara awọn eeyan nipasẹ igi gbingbin, ipese ounjẹ ati iṣẹ ọlọkan o jọkan fawọn ara ilu lati ṣe.

Bakan naa ni wọn ni awọn agbẹ ọlọsin nnkan jijẹ yoo ri anfaani ajọṣepọ yii jẹ, nitori ijọba yoo fun wọn nilẹ lati ṣeto ọsin wọn, wọn yoo si ya wọn lowo diẹ ti wọn le fi gbooro iṣẹ wọn si i.

(22)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.