Ijọba Ọbasanjọ lo daran, awọn ni wọn dana sun ile Fẹla, o si di dandan ki wọn fori fa a

Spread the love

Gbogbo eeyan lo n wo ẹnu Adajọ Lateef Dosunmu, wọn n wo ẹnu rẹ ko sọrọ, wọn ko mọ ohun ti yoo ti ẹnu rẹ jade. Ṣe ọtun ti rojọ, osi si ti rojọ tan bayii. Ninu ẹjọ ti Fẹla Anikulapo Kuti ati awọn ẹbi rẹ pe ijọba apapọ atawọn ọga ologun Naijiria ni, lori ẹsun pe wọn dana sun ile ẹ lọjọ kejidinlogun, oṣu keji, ọdun 1977, wọn si ba ọpọlọpọ nnkan jẹ. Ẹni ti ọrọ kan gan-an ti rojọ, iyẹn Fẹla funra ẹ, ọkunrin janganjangan bii irin. Iya rẹ naa ti rojọ, Arabinrin Olufunmilayọ Kuti tawọn ṣọja ju lati ori oke aja keji bọ silẹ lọwọ kan, ti wọn si ji gbogbo goolu rẹ ko lọ. Aburo Fẹla naa ti rojọ, iyẹn Bẹẹkọ, ẹni to sọ pe oju windo lawọn ẹruuku ti ba ju oun sita, ti wọn si ko nina kan bo oun debii pe oju oun n pooyi, oun ko si riran mọ rara, ko too waa di pe wọn ba ọsibitu oun kekere to wa ninu rẹ naa jẹ kanlẹ pẹlu gbogbo irinṣẹ to wa nibẹ.

Awọn obinrin Fẹla ti awọn ṣọja na bii ki wọn ku naa kuku ti wi, pẹlu awọn ti wọn ba sun ni baifọọsi. Ẹni ti wọn gun lọbẹ ti ifun rẹ yọ jade naa ti sọrọ, o ni bi ko jẹ ori iya oun ni, ọrun loun iba wa bi awọn ti n sọrọ naa, ko si sẹnikan ti iba gba oun. Ọmọbinrin ti wọn fi ẹnu ibọn gun loju “kinni” ẹ gan-an naa royin, o tọlẹ la, o ni bo ba jẹ oyun wa ninu oun ni, yoo walẹ lẹsẹkẹsẹ ni. Awọn panapana sọrọ, wọn ni bo ti wu awọn ki awọn pa ina to n jo nile Fẹla to, to jẹ awọn ti debẹ pẹlu irinṣẹ, nigba tawọn ko ni iṣẹ meji ti awọn n ṣe ju iṣẹ panapana lọ, awọn ṣọja ko jẹ o. Wọn ni bi awọn ko ba tete ba ẹsẹ awọn sọrọ, iya ti Judasi jẹ ku lọjọ kin-in-ni ana, awọn lawọn yoo jẹ ẹ. Wọn ni eyi lawọn gbọ ti awọn fi tu danu, bi awọn si ti n lọ ni eefin ina naa n gbalẹ si i. Bi kaluku ti rojọ ree, o waa ku ki Adajọ Dosunmu da a.

Amọ ki Adajọ naa too sọrọ, niṣe ni lọọya ijọba fo dide fuu lẹẹkan naa. Ọgbẹni S. G. Laoye ni lọọya ijọba, o si mọ ayinike ati ayinipada ofin. Didide to dide lọjọ naa ki i ṣe fun anfaani awọn Fẹla ṣaa o, nitori awọn ọrọ to n tẹnu rẹ jade niwaju adajọ, ọrọ to le mu ki awọn olupẹjọ sẹ ori mọ ọn laya ni. Abi nigba to wo oju adajọ to bẹrẹ si i tu kẹkẹ ọrọ, ti awọn ọrọ rẹ si yatọ si eyi to ti n sọ bọ latẹyin patapata. Bo ba tiẹ jẹ oun nikan ni, boya ọrọ naa iba sẹpẹrẹ diẹ, ṣugbọn o tun mu ogboju lọọya mi-in to jẹ ijọba loun naa n ṣiṣẹ fun lẹyin, n lawọn mejeeji ba bẹrẹ si i da ifa ọrọ naa sibi ti ko ti le fọre. J.O. Ige lorukọ agbẹjọro keji yii, bi Laoye ba si ti sọrọ kan ni Ige yoo sọ pe oun kọnkọọ, iyẹn ni pe gbogbo ohun ti ọkunrin lọọya to ṣaaju rẹ sọ naa loun faramọ. Loootọ lọrọ wọn daa, ṣugbọn ko ta leti awọn Fẹla.

Agbẹjọro Laoye sọ pe gbogbo eyi ti awọn ti n ba bọ latẹyin, niṣe loun fi gbigbọ ṣe alaigbọ, ṣugbọn nibi ti ọrọ de duro bayii, oun yoo kuku tuṣọ loju ọrọ, oun yoo ṣalaye ohun ti ko ye awọn Fẹla ti wọn pe ẹjọ yii fun wọn. O ni bi wọn ṣe ri i nni, ko sẹnikan to lagbara tabi to lẹtọọ, tabi to laṣẹ labẹ ofin lati pe ijọba ologun lẹjọ. O ni wọn ki i pejọba lẹjọ, ẹni to ba n pejọba lẹjọ kan n fi akoko ara rẹ ṣofo ni, nitori ijọba ki i jẹbi ẹjọ. O ni iyẹn lo ṣe jẹ nigba ti lọọya awọn Fẹla, Ọgbẹni Tunji Braithwaite, n sọrọ, to n laagun ni ẹba-eti, ẹrin loun n rin sinu ni toun, nitori oun mọ pe gbogbo awuyewuye to n ṣe yii, o kan n yingbado sẹyin igba lasan ni, ko yatọ si ọkunrin alagbara to n pọnmi sinu apẹrẹ, nigba to ba lo gbogbo agbara rẹ tan, yoo ya a lẹnu ju pe oun ko ni i ri omi kọọpu kan mu dele.

Laoye ni bi ọrọ ijọba ologun ṣe ri ni pe bo ba jẹ awọn ni eeyan ṣẹ, to ṣe nnkan ti ko dara si wọn, eeyan to ba ṣe e yoo bẹ ijọba naa ni, yoo si sanwo itanran fun wọn. Ṣugbọn bo ba jẹ ijọba lo ṣe ohun ti ko dara, ijọba ologun, ẹni ti wọn ṣe e si naa ni yoo tun pada lọọ bẹ wọn, nitori ijọba lo nile, ijọba lo loko, koda ẹni to n binu paapaa, ijọba lo ni in. O ni bi ọrọ ba ri bayii, iwe kan wa ti ẹni ti ijọba tabi iranṣẹ rẹ ba fiya jẹ maa n kọ, iwe ẹbẹ ni, Petition of Right ni wọn n pe e, ẹni ti ijọba ba ṣẹ lẹṣẹ kan lo maa n kọ ọ, yoo si fi ṣalaye ohun ti ijọba ṣe ti ko dara, yoo waa bẹ wọn pe ki wọn fun oun ni nnkan kan. O ni ẹni ba ṣe iyẹn nikan ni ijọba maa n ri si ọrọ wọn, ti wọn yoo si ba a wa nnkan kan gẹgẹ bii owo aanu, bi wọn o ba si raaye lati foju aanu wo iru ẹni bẹẹ, tiẹ ba a niyẹn, ko maa ran an nibi to ba ti ya lo ku.

O ni ohun to da oun loju ni pe awọn Fẹla ko ṣe iru iyẹn, wọn ko lo anfaani bẹẹ, awọn kan da agidi bolẹ, wọn ni ijọba ba nnkan awọn jẹ, awọn si gbọdọ gbowo lọwọ ijọba. Laoye ni nibo ni wọn ti n ba ijọba ologun ṣeru ẹ! O ni ka tiẹ tun waa da a silẹ ka tun un ṣa, gbogbo ẹjọ ti wọn ro kalẹ yii, o ni oun ko ri ibi ti ọrọ naa fi kan ijọba ati awọn eeyan rẹ tawọn Fẹla n pariwo yii. Ọkunrin lọọya ijọba yii ni ariwo ti awọn n gbọ ti wọn si ti tun fidi ẹ mulẹ nibi ni pe awọn ṣọja kan ti ẹnikan ko da mọ lo dana sunle Fẹla, awọn ni wọn ba awọn ọmọọṣẹ ẹ sun, awọn ni wọn lu awọn eeyan ni ilukulu nibẹ, ti wọn si tun ji nnkan ko, bawo waa ni Fẹla ṣe taku pe oun yoo fiya jẹ ijọba ati awọn kan, nigba ti ki i ṣe awọn ni wọn dana sunle ẹ. Ṣebi ika to ba ṣẹ lọba paapaa n ge, ẹni ba ṣa gba ni leti la a doju ija kọ.

Laoye ni niṣe ni Fẹla ati iya rẹ, ati aburo rẹ, fi onija silẹ, ti wọn n gba alapẹpẹ loju, nitori oun ko ri ibi ti ọrọ ti wọn sọ kalẹ yii fi kan Ọgagun Adedayọ ti wọn lo wa ni baraaki Abalti, bẹẹ loun ko ri ohun to kan ọga awọn ṣọja patapata to n gbe Ikoyi ninu ọrọ to ṣẹlẹ ni Mọṣalaṣi Idi-Oro. O ni nigba ti wọn tun sọ ọ lọ ti wọn sọ ọ bọ, wọn ni awọn pe ileeṣẹ ologun lẹjọ, ṣe ileeṣẹ ologun lo ran awọn ṣọja tẹnikan ko mọ yii jade ni, abi wọn ri iwe aṣẹ kan ti ẹnikẹni kọ le awọn ṣọja to ṣe iṣẹ ibi naa lọwọ, ka baa le sọ pe ka mu ẹni to fun wọn niwee aṣẹ yii. Ọgbẹni Laoye ni nigba ti ko ti si gbogbo ohun ti oun ka kalẹ yii, bii ẹni to n fi akoko ile-ẹjọ ṣofo, to si n ko ọkan awọn eeyan soke lasan ni ẹjọ tawọn Fẹla pe yii, nitori wọn kan n daamu awọn eeyan, wọn si n daamu ijọba to n fọkan ṣiṣẹ ilu lọ ni.

Iyẹn nikan kọ o, Laoye yii tun ka saamu ọrọ, o ni, bi awọn ba tilẹ tun fẹẹ sọrọ, ṣe miliọnu mẹẹẹdọgbọn waa jẹ owo kekere ti ẹni kan yoo binu san, ati pe ki lo bajẹ nile Fẹla to le to bẹẹ, eelo ni wọn si fi n kọle to waa di pe wọn yoo ni ki wọn ko owo rẹpẹtẹ bẹẹ fẹni kan. O ni gbogbo ẹjọ ti awọn ẹlẹrii, ati awọn Fẹla funra wọn n ro lo n tako ara wọn, nitori bi ẹni kan ba darukọ pe iye bayii lawọn na, ọtọ ni iye ti ẹlomi-in yoo pada waa da lori ọrọ kan naa. Bi ẹni kan ba ni wọn ji ẹru oun ko, ẹru naa si to iye bayii, ọtọ ni iye ti ẹlomi-in yoo waa pe e, nigba ti Fẹla si ni wọn ba irinṣẹ oun jẹ, owo irinṣẹ naa si jẹ iye kan, ọtọ ni iye ti awọn ọmọọṣẹ rẹ ti wọn mọ nipa irinṣẹ yii pada pe e. Laoye ni bi eeyan ba waa fẹẹ tilẹ ṣiro iye owo wọn to sọnu, tabi nnkan wọn to bajẹ, bawo leeyan yoo ṣe ṣe e nigba ti ọrọ wọn ko bara mu.

Laoye ni ṣugbọn gbogbo ọrọ ti oun sọ yii, ibi kan naa lo kuku fori sọ. O ni awọn Fẹla n binu, wọn ni wọn dana sun ile awọn, wọn si n darukọ awọn eeyan kan si i. O ni ninu gbogbo awọn ti wọn darukọ yii, ewo lo wa nile Fẹla ni ọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, ṣe Kọlọnẹl Adedayọ ni tabi T. Y. Danjuma to jẹ ọga awọn ṣọja pata. O ni awọn yii ko si nibẹ, wọn ko si kopa ninu ki wọn dana sunle tabi biba dukia jẹ, nitori bi wọn ba wa nibẹ ni, fọto iba gbe e jade. Niwọn igba ti wọn ko ti si nibẹ lọjọ naa, ko ni i dara rara lati fi orukọ wọn si i pe ki wọn sanwo itanran tabi da sọrọ ti wọn o mọwọ mẹsẹ nibẹ. Laoye ni bi iyọ ko ba dunbẹ, keeyan ma fikanra mewe jare, awọn ti Fẹla doju ija kọ yii kọ lo yẹ ko dojukọ, ko wa awọn ṣọja ti wọn dana sunle rẹ siwaju. O ni k’Adajọ Dosunmu ma fakoko ṣofo mọ, ki wọn da ẹjọ awọn Fẹla yii nu kiakia.

Nibẹ ni inu ti bi lọọya awọn Fẹla, Tunji Braithwaite, ẹni ti i maa soyinbo bii pe Lọndọọnu gan-an ni wọn bi i si, to si gbe dagba, kinni ọhun yọ lẹnu rẹ bii nnkan. O kan jẹ pe ko si ẹrin loju rẹ lọjọ yii ni, niṣe lo fo dide bii ẹni ti ẹgun n gun, inu ti bi i gidi. O ni iru ọrọ runrun wo lọrẹ oun n sọ yii – ṣe awọn lọọya kuku buru, bi wọn n foyinbo bura wọn bayii, wọn yoo si maa pe ara wọn ni “ọre mi onilaakaye”, lọọya ki i pe ara wọn ni “ọta mi” layelaye. O dojukọ Adajọ Dosunmu, o ni ko gbọ isọkusọ ti lọọya ijọba n sọ o, o ni ṣe oun naa le gba iru ọrọ bẹẹ yẹn wọle. Braithwaite ni ọmọ ki i daran ki apa rẹ ma ka a ni, nibi gbogbo lagbaaye, bi ijọba kan ba daran, awọn ti wọn n ṣejọba naa ni wọn yoo fori fa a. O ni ijọba awọn Ọbasanjọ ti daran, adaluru ati adanasunle ni wọn, dandan si ni ki wọn tan ọran ti wọn da.

Braithwaite ni ọrọ yii ko pariwo rara, ẹni to gbe panla ti jẹwọ, ki lo waa tun ku ti a n sọrọ asọlaagun si. O ni awawi lo ku ti ọrẹ oun lọọya ijọba n wi, nitori funra awọn eeyan rẹ naa ni wọn sọ pe nitori pe ija de laarin ọmọ Fẹla kan ati ṣọja kan ni wọn ṣe dana sunle ẹ, kin ni wọn tun waa n sọ pe wọn ko mọ ẹni to sunle si, ṣebi awọn ni wọn mọ ṣọja to ja pẹlu ọmọ Fẹla, wọn ṣa mọ awọn ṣọja ti wọn ko si oju titi lati maa dari ọna, wọn si mọ awọn ṣọja to wa nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, ki waa ni wọn ko mu wọn jade si. Ṣebi awọn ṣọja ti wọn wa nibi ti ija ti de laarin awọn ati awọn ọmọ Fẹla naa ni wọn pada wa sile Fẹla, ti wọn si lọọ ko awọn ẹlẹgbẹ wọn wa, ti wọn dana sun ile naa lẹyin ti wọn ti gbaṣẹ lọwọ ọga wọn ni baraaki ti gbogbo wọn jọ n gbe, bẹẹ inu baraaki yii naa ni wọn ko Fẹla ati gbogbo araale rẹ lọ.

Braithwaite ni ẹri wo ni lọọya ijọba tun n wa, ṣebi awọn fi fọto han an, oun naa si ri fọto ṣọja to n gbe bẹntiroolu lọ sile Fẹla, oun naa si ri awọn ṣọja ti wọn n gun oke ile Fẹla, oun naa si ri ina to n sọ nibẹ ati bi awọn ṣọja ti n sare kiri, iru ẹri wo waa tun ni ọkunrin yii ni ko si o. Braithwaite ni bi ẹri gbogbo ko ba tilẹ to, ṣebi Laoye ati ẹni keji rẹ mọ pe Abalti Baracks, nibi ti awọn ṣọja yii n gbe, ni wọn ko Fẹla ati iya rẹ, ati awọn ọmọ ẹyin rẹ, ati aburo rẹ lọ. Igba ti wọn tun debẹ, ki i ṣe pe wọn fi wọn silẹ bẹẹ o, wọn tun fiya jẹ wọn daadaa, ti wọn n na wọn ni idi ibọn, ti wọn si n sa wọn soorun, titi ti wọn fi waa ro o lọkan ara wọn lati gbe wọn lọ si ọsibitu nigba ti wọn ri i pe awọn eeyan naa n ku lọ. O ni bo ba jẹ awọn ni wọn lu wọn, awọn ni wọn gbe wọn lọ si ọsibitu, ki waa ni ọkunrin yii loun o mọ ẹni to dana sunle si.

Yatọ si bẹẹ, ọkunrin lọọya yii ni ṣebi Laoye wa nibẹ, oun naa ṣa foju ara rẹ ri i nigba ti awọn ẹlẹrii loriṣiiriṣii n tọka si awọn ṣọja ti wọn wa nibẹ lọjọ naa, ti wọn n fi wọn han pe awọn niyi, awọn mọ wọn, nitori wọn wa nibẹ, awọn si ri wọn, ti awọn ṣọja naa ko si le tako wọn, tabi ki wọn sọ pe awọn ko si nibẹ, ṣebi wọn kan n wo suu nitori pe ijọba ti ni ki wọn ma sọro ni, tabi ta ni ko mọ ọgbọn ka fi ẹran sẹnu ka wa a ti nibẹ. O ni bo ba si jẹ ti ijọba ati awọn ti wọn n ṣe e ni, ko si awọn agbofinro kan ti wọn yoo ṣe ohun aburu to pọ to bẹẹ yẹn si eeyan pataki laarin ilu, ti ijọba yoo sọ pe oun ko mọ si i, tabi oun o gbọ, iru ijọba bẹẹ ti ku niyẹn. O ni awọn ṣọja ko ni i jade pupọ to bẹẹ yẹn ko ma jẹ ẹni kan ti fun wọn laṣẹ lati jade ni, bẹẹ ni wọn ko si ni i gba aṣẹ lati ọdọ ọga kuẹkuẹ, lati ọdọ olori wọn ni wọn yoo ti gbaṣẹ.

Braithwaite ni awọn ṣọja Abalti yii ko ni ọga pata meji ju Adedayọ lọ, bẹẹ ni oun naa si gbọ nigba ti Bẹẹkọ sọ pe Ọgagun Adedayọ yii waa ba oun nibi ti awọn ṣọja ko awọn si, to ni “Ṣe awọn ara Agege Motor Road yẹn ree?”, nigba ti wọn si da a lohun pe awọn ni, to ni, “Ẹ ṣe e fun wọn daadaa!”, to si jẹ bo ṣe sọ bẹẹ lawọn ṣọja tun ko lilu gidi fawọn, titi ti ninu awọn fi daku. Braithwaite ni Adedayọ mọ pe nnkan to lewu ni eyi ti wọn ni ki oun ṣe yii, ko si si ko ma jẹ pe o ti gba aṣẹ lọwọ ọga tirẹ naa, bẹẹ ko ni ọga meji ju olori awọn ṣọja lọ, GT. YH. Danjuma. O ni ṣebi nibi ti awọn ọrọ naa ti we mọ ara wọn niyẹn. Braithwaite ni Igunnu lo ni Tapa, Tapa lo n’Igunnu, ijọba lo ni ṣọja, awọn ṣọja naa lo si n ṣejọba. Bawo waa ni lọọya ijọba yoo ṣe sọ pe ọrọ to wa nilẹ yii ko kan wọn, ase lasan ni.

Nigba naa ni oun waa wo Adajọ Dosunmu, o doju kọ ọ, o si mi kanlẹ fungba diẹ. O ni ko wo oju oun daadaa, oun fẹẹ bẹ ẹ lẹbẹ kan, nitori oni si kọ, nitori ọjọ iwaju ni. O ni ko ma jẹ ki awọn ti wọn n ṣejọba yii koba oun o, nitori alakooba lo pọ ninu wọn, ṣugbọn ohun ti oun yoo maa ranti ni pe awọn ṣọja yii yoo gbe ijọba silẹ nijọ kan, ṣugbọn oun gẹgẹ bii adajọ yoo wa nibẹ fun ọpọlọpọ igba, ati ọpọlọpọ ọdun lẹyin ti awọn ba ti lọ. O ni nitori bẹẹ loun ṣe n bẹ ẹ ko ma gbọ ọrọ ti Laoye sọ yẹn, pe ko da ẹjọ ti awọn ti wa lẹnu ẹ lati ọjọ yii nu. O ni ko ma tilẹ fesi si i rara debi ti yoo mu un lo, nitori amọran to le ko baayan ni. Braithwaite ni gbogbo aye lo n wo ẹjọ yii bo ti n lọ o, wọn fẹẹ mọ ibi ti yoo fori ti si, gbogbo aye fẹẹ mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ si Fẹla, ati iru ẹjọ ti awọn adajọ Naijiria fẹẹ da lori iru ọrọ bayii.

Nigba ti yoo fi sọrọ debi yii, oun naa ti n laagun, bo si tilẹ jẹ pe ibi ti wọn wa ki i ṣe ibi ti ooru ti n mu wọn to bẹẹ naa, sibẹ, bi inu ti bi i to, ati bo ṣe n fikanra sọrọ naa ti jẹ ki ara rẹ gbona lati inu wa, o si n laagun karakara. Gbogbo awọn ara kootu paapaa ti naro ara, ko sẹni ti idi rẹ lelẹ lori aga mọ, wọn n woju adajọ, nitori kaluku ti ri i pe ọrọ to wa nilẹ naa ti ju ibi ti wọn ro o lọ. Adajọ paapaa ti kọwe, ọwọ rẹ ti fẹrẹ bo, nitori gbogbo bi Braithwaite ti n sọrọ nni, bẹẹ lọwọ Adajọ Dosunmu ko duro. bi Braithwaite ba ti sọ gbolohun kan, adajọ naa yoo kọwe lọ bii ilẹ bii ẹni, yoo si tun gboju soke lati mọ ibi ti ọkunrin naa n ba ọrọ rẹ lọ, bi iyẹn ba si ti tun ju ọrọ ofin kan lulẹ, iwe kikọ tun bẹrẹ niyẹn fadajọ aye. Nigba naa ni Adajọ Dosunmu gboju soke, o ni oun ti gbọ gbogbo alaye wọn, oun yoo kede ọjọ idajọ laipẹ, akọwe kootu yoo si ranṣẹ si gbogbo wọn.

Bayii ni akọwe kootu pariwo, “Kọọọọtu!” Ohun rẹ si ja too bii ti obinrin alabosi ti ọkọ rẹ fun labara gbigbona, awọn ero kootu si dide, kaluku n ba ile rẹ lọ, ọjọ idajọ ni gbogbo wọn yoo maa reti.

(36)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.