Ijọba Ọbasanjọ gba Kalakuta, ile Fẹla, awọn ṣọja ni bi awọn ba tun ri i nibẹ awọn aa yinbọn fun un

Spread the love

Adajọ Kalu Anya ti yanju ọrọ Fẹla. Ki i ṣe pe adajọ naa yanju ọrọ naa daadaa, adajọ ri ijọba lo lati ba ti Fẹla jẹ ni. Ko si ọrọ kan bayii to sọ to gbe Fẹla, gbogbo ọrọ to sọ lodi si ọkunrin olorin naa ni. Bẹẹ ni ko si aba kan to da bayii to le ran Fẹla lọwọ, gbogbo aba to da sinu abajade iwadii to ṣe, ọna lati tubọ sọ Fẹla di ọta ijọba ni. Boya oun funra ẹ lo ṣe e bẹẹ ni o, boya wọn ran an lati ṣe bẹẹ ni o, iyẹn ni ẹnikẹni ko mọ. Ṣugbọn bo ti gbe awọn agbekalẹ naa silẹ, ati awọn ohun to ri to loun ko ri, ati awọn eyi ti ko ri to ni oun ri, niṣe lo da bii pe wọn ran an ni iṣẹ to jẹ, bi wọn ko ba si ran an, aa jẹ pe oun naa koriira Fẹla debii pe bo ba ri i ninu ookun, yoo la nnkan mọ ọn lori, bo ba le ku ko ku ni. Idi ni pe ọpọlọpọ nnkan ti ọkunrin naa ri, to si foju han si gbogbo ilu, ni adajọ yii gboju kuro nibẹ.

Titi di igba ti wọn n ṣewadii ọrọ wọn, bii ẹẹkan tabi ẹẹmeji ti wọn gbe Iya Fẹla funra rẹ, Arabinrin Funmilayọ Ransome Kuti, wa sibi igbẹjọ yii, ọsibitu ni wọn ti n gbe e wa. Lati ọjọ ti awọn ṣọja ti wọn ya wọ ile Fẹla ti sọ ọ mọlẹ lati ori pẹtẹẹsi ile giga naa, lati igba naa lo ti wa lọsibitu, nitori wọn da a lẹsẹ, wọn si da a leegun ẹyin. Eyi to si dun awọn eeyan ju ninu ọrọ naa ni pe niṣe ni ọkunrin adajọ yii sọrọ nibi igbẹjọ naa bii pe loootọ loootọ lo ni irẹlẹ ati itẹriba fun Iya Fẹla, to n kẹ ẹ, to n gẹ ẹ ni gbogbo igba to fi waa ba wọn nibẹ. Ṣugbọn nigba ti yoo gbe ẹjọ rẹ jade, ko sọ pe oun ri Iya Fẹla tabi pe ọrọ to sọ nipa bi awọn ṣọja ti sọ oun lati ori oke bọ silẹ ja mọ kinni kan, ko si darukọ obinrin akikanju naa sinu awọn iwe rẹ gbogbo, kaka bẹẹ, o ni irọ ni awọn ọmọbinrin Fẹla ti wọn ni awọn ṣọja lu awọn n pa.

Bẹẹ ni ko ju ọsẹ kan ti igbimọ yii pari ijokoo wọn, iyẹn lẹyin ti wọn ko ti jokoo mọ, ti wọn tilẹkun mọri, ti wọn n kọ abajade iwadii wọn naa, ti ariwo fi ta pe Iya Fẹla ko le sọrọ mọ, ko le jẹ, ko le mu, bẹẹ ni ko si da ẹnikẹni mọ. Ọsibitu ti wọn gbe e lọ lati igba to ti ni ijamba ni ile ọmọ rẹ yii naa ni eleyii ti ṣẹlẹ, wọn si tun sare gbe e lọ si ọsibitu to ṣe ju bẹẹ lọ. Awọn ti wọn n ṣejọba kọkọ rọ pe irọ lo n pa ni, afi nigba ti wọn gbọ pe ọrọ naa ki i ṣe ere rara. Obinrin naa jade ninu eyi, iyẹn ni pe o tun n sọrọ, o si n da awọn eeyan mọ, o jọ pe o ti yi kinni naa jẹ. Ṣugbọn ọrọ naa lo pada pa a nitori lati igba ti Adajọ Kalu Anya ti gbe abajade iwadii igbimọ rẹ jade yii, Iya Fẹla ko fi ọsibitu silẹ nigba kan, nitori ohun ti wọn ṣe lẹyin ti adajọ yii ti gbe abọ iwadii rẹ le wọn lọwọ ko bọ si i, o si fihan pe loootọ ni wọn fẹẹ ṣe Fẹla leṣe.

Ijọba Ọbasanjọ ko duro rara, lẹsẹkẹsẹ, lọjọ kan naa ti abajade igbimọ yii jade, lọjọ naa lawọn naa ti gbe ofin buruku kan jade, ofin naa si ni pe awọn ti gba Kalakuta, ile Fẹla. Bawo ni wọn ṣe gba a, ijọba Eko ni wọn lo lati gba a. Gomina ologun Adekunle Lawal lo si paṣẹ yii lọjọ naa lọhun-un. Bi eniyan ba ni ilẹ tabi ile ni ibi kan, ohun ti yoo maa sare lati ni ni iwe kan ti wọn n pe ni Sii-of-Oo (C-of-O). Ohun to wa ninu C-of-O yii ko dara fun gbogbo ẹni to ba ni ile tabi ilẹ, nitori ohun to n sọ ni pe ijọba lo ni ile, ijọba rẹnti ilẹ naa fun awọn eeyan ti wọn ni in ni. Ilẹ ti wọn waa rẹnti fun wọn yii, ti wọn ko ba lo o daadaa, tabi ti wọn ba fi n ṣe ohun ti ko tẹ ijọba lọrun, ijọba lẹtọọ lati gba iwe C-of-O yii pada, ki wọn si gba ilẹ kuro lọwọ ẹni ti wọn ti fi i fun, ohun yoowu ti wọn si ṣe si ọri ilẹ naa ko kan wọn.

Bi ọrọ naa ti ri ni pe bi wọn kọ ile alaja-mẹẹẹdọgbọn sori ilẹ kan, ko si eyi to kan ijọba tabi ẹni to ni ile, ohun ti ijọba yoo maa tẹnumọ ni pe ile awọn ni awọn fẹẹ gba, nitori awọn lawọn ni in. Ko si ibi ti eeyan yoo gbe ọrọ naa de labẹ ofin ti wọn ko ni i jare rẹ, nitori o ti wa ninu ofin tẹlẹ pe igbakigba ni onilẹ le gba ilẹ rẹ pada bi ẹni ti oun rẹnti rẹ fun ko ba lo o ni ọna to tẹ oun lọrun, ko si si ẹni to le sọ pe ọna naa tẹ ẹ lọrun bo ba ti ni ko tẹ oun lọrun. Ohun ti yoo sọ fun un ni pe oun fẹẹ lo ilẹ oun, tabi pe oun fẹẹ gba a pada, ko gbe ile rẹ kuro lori ilẹ naa, nitori iru adehun to wa laarin wọn. Ijọba nikan lo ni iru agbara bẹẹ, awọn nikan ni wọn ni adehun bẹẹ, awọn nikan ni wọn si le lo iru ida bẹẹ, nitori ninu ofin Naijiria, ijọba lo ni gbogbo ilẹ, ijọba agbegbe kan, aṣẹ ti wọn ba si pa lori rẹ ko ṣee yipada.

Iru aṣẹ ti wọn lo fun Fẹla niyẹn. Lẹyin ti abajade iwadii awọn adajọ yii ti jade, ti gbogbo aye si n pariwo pe kin ni wọn yoo ṣe yii, bawo ni wọn ṣe fẹẹ ṣe ọrọ Fẹla si bayii, kin ni ijọba Ọbasanjọ yoo ṣe, ijọba ti wa nipade tiwọn, ti wọn si ti n ro bi awọn yoo ti ṣe fiya jẹ ọga olorin naa, iya to lagbara. Lẹsẹkẹsẹ ni wọn si gbe kinni naa jade, wọn ni awọn ti gba ile Fẹla, ko gbọdọ de ile naa, ko gbọdọ de agbegbe naa, ko si gbọdọ wọ ibẹ fun ohunkohun, nitori ilẹ naa ti di ti ijọba. Ki i ṣe ile naa nikan ni wọn gba, wọn ni gbogbo ile to wa nitosi rẹ, gbogbo agbegbe naa, gbogbo rẹ ni awọn gba, awọn ko si gbọdọ gbọ ki ẹnikan ni oun loun ni ilẹ, tabi oun tun fẹẹ kọ ile sori ilẹ naa, lati ibẹrẹ siriiti wọn titi de opin rẹ. Iyẹn lati ibẹrẹ biriiji Yaba ni Jibowu, titi de jọkiṣan Agege Motor Road, ni Mọṣalaṣi.

 

Ileeṣẹ kan wa ni agbegbe yii nigba naa ti wọn n pe ni Dorman-Long Engineering Company, ijọba ni awọn fun wọn laaye, ki wọn ṣi maa ṣe iṣẹ wọn lọ nibẹ, ṣugbọn ki wọn maa fi oju wa ibi ti wọn yoo kọ ileeṣẹ wọn si, nitori gbogbo ilẹ ti awọn gba yii, lẹsẹkẹsẹ ni awọn gba a, ko si le pẹ ti wọn yoo fi gbe katapila wa sibẹ lati waa kilia ilẹ naa, nitori awọn fẹẹ kọ ileewe si i ni, bi wọn ko si kọ ileewe, awọn yoo fi i ṣe nnkan meremere mi-in, ki ẹnikẹni ṣa ma de ori ilẹ naa, nitori o ti di ti ijọba. Awọn to ni ile ati ohun-ini si agbegbe naa bẹrẹ si i sare kiri, wọn kawọ gbenu nitori wọn ko mọ ọna ti wọn yoo gba ati ohun ti wọn yoo ṣe, paapaa nigba ti ijọba ti ṣofin pe lẹsẹkẹsẹ ni ki wọn kuro ni ori ilẹ naa, ki wọn wa ibomiiran ti wọn yoo maa gbe, ẹni ti ko ba si tete ko awọn ohun-ini rẹ jade, ijọba yoo jẹ wọn mọ ogun ni.

Otẹẹli ti Fẹla ti maa n kọrin rẹ ti wọn pe ni Empire Hotel, iwaju ile Fẹla gan-an lo wa. Bi awọn kan ti n pe e ni Kalakuta naa lawọn mi-in n pe ni African Shrine, nigba to jẹ ibi ti Fẹla ti n ṣe ere ati aṣa ibilẹ rẹ niyẹn. Otẹẹli naa lo da bii ọfiisi fun awọn ọmọ rẹ, lọsan-an loru, ẹni ti ko ba ti si ninu ile ninu wọn, otẹẹli yii ni wọn yoo ti ba a. Ni gbogbo alẹ, ibi ti Fẹla ti n ṣe ere ree, ko si si ọjọ kan ti awọn onifaaji ki i wa sibẹ lati waa gbọ orin ati ilu Fẹla, ti wọn yoo wo awọn ọmọge rẹ to n jo, ti awọn alafẹ obinrin yoo si ba alafẹ ọkunrin ṣọrẹ, ti faaji yoo si ṣan nibẹ rẹpẹtẹ. Ṣugbọn ijọba paṣẹ lọjọ yii kan naa pe ki wọn ti otẹẹli naa pa lẹsẹkẹsẹ. Wọn ni wọn ko gbọdọ lo ile naa fun otẹẹli mọ, bẹẹ ni wọn ko si gbọdọ ta ọti nibẹ, nitori ijọba ti gba iwe aṣẹ itọti ti wọn fun wọn, ati iwe aṣẹ otẹẹli, wọn ni ibẹ ti di eewọ fun ile itura.

Ọrọ naa ko ye awọn eeyan. Bi Fẹla ba ṣe ohun ti ko dara ti ijọba si fiya jẹ ẹ, ewo ni ti otẹẹli olootẹẹli ti wọn tun gbegi le nigba ti ki i ṣe pe olootẹẹli naa lo ṣẹ wọn, ti otẹẹli naa ki i ṣe ti Fẹla funra rẹ. Bẹẹ nigba naa, ko si otẹẹli to lokiki tabi to tun jẹ tawọn gbajumọ ni gbogbo agbegbe naa, lati Yaba titi de Surulere, ati Idi-Oro de Muṣin to gbajumọ bii Empire Hotel, ọpọ awọn oṣere lo maa n fẹẹ lọọ ṣere nibẹ, agaga ni asiko ti Fẹla ko ba si nile. Gbogbo awọn elere bii Sunny Ade, awọn Ebenezer Obey, awọn Victor Uwaifo, gbogbo wọn ni wọn n lo sibẹ lati lọọ ṣere wọn, awọn eeyan si ti mọ ibẹ bii ibudo fun awọn oṣere ati awọn ti wọn n gbe aṣa ga. Ṣugbọn nitori ti Fẹla yii, ijọba ti otẹẹli naa pa, wọn si ni wọn ko gbọdọ lo ibẹ laye mọ gẹgẹ bii ile itura. Wọn ko gbọdọ ṣeeṣi ta ọti nibẹ paapaa, bẹẹ ni ko si aaye fun ijo.

Kin ni ijọba sọ pe o de ti awọn fi gba ile Fẹla? Alaye ti wọn ṣe ni pe awọn ko le gba ki ẹnikan maa da ilu laamu, tabi ki ẹnikan maa fi ilẹ ti awọn fun un ṣe ipanle. Wọn ni Fẹla ti sọ ara rẹ di ologomugomu si gbogbo adugbo naa, debii pe ko si ẹni kan to n gbe ibẹ ti ki i ṣe pẹlu ibẹru lo fi n gbe. Fẹla ti ko gbogbo wọn laya jẹ. Eleyii ki i ṣe bẹẹ rara o. Ko si ẹni ti o n gbe adugbo naa ti inu rẹ ko dun pe itosi ile awọn Fẹla loun n gbe. Bi wọn ko ri awọn ọmọ Fẹla ti wọn n wọ aṣọ pelebe pelebe kiri, wọn yoo ri awọn oṣere oriṣiiriṣii ti wọn n lọ ti wọn n bọ ni ile Fẹla, nigba to si jẹ pe olorukọ nla ni Fẹla funra rẹ, awọn mi-in maa n lọ si ẹnu ọna ile rẹ lati mọ igba ti oun funra rẹ yoo jade, tabi ti yoo rin ṣere lọ. Awọn eeyan fẹẹ mọ Fẹla, awọn ti wọn si wa ni adugbo rẹ fẹran rẹ, nitori oṣere nla ni.

Yatọ si eleyii naa, nitori pe awọn ọmọ ti wọn n ba Fẹla ṣere le gan-an, ti wọn si le ja, ko si ọmọọta, tabi ole kan ti i da wọn laamu ni adugbo yii, ko si ole to n ja nibẹ rara. Bi awọn ọmọ lile ti wa lẹyin Fẹla to ti wọn si n ṣere, ti wọn n mugbo ni gbogbo agbegbe ibi to ba ti n ṣere, ohun ti ẹnikẹni ko ni i gbọ nibẹ ni pe wọn ja mọto gba, wọn fibọn jale, tabi wọn ko ile onile. Niṣe lo da bii pe awọn adigunjale ati awọn ole afogiri wọnyi ṣepade pe ẹnikẹni ko gbọdọ de adugbo ti Fẹla n gbe. Bo si ṣe ri niyẹn, ko si ẹni ti yoo lọ si ile Fẹla lọọ fajangbọn, tabi da awọn araadugbo rẹ laamu gẹgẹ bii ole. Sugbọn ijọba sọ ọrọ didun ki wọn le gba Kalakuta kuro lọwọ Fẹla, ki wọn si sọ ọ di tiwọn, ki wọn si fi i ṣe ohun ti wọn ba fẹẹ fi i ṣe. Bakan naa ni ijọba sọrọ lori awọn ọmọ keekeeke ti wọn n tẹle Fẹla.

Ni ile Fẹla, ominira wa nibẹ loootọ, ẹnikẹni to ba wa sibẹ pe oun fẹẹ ṣere, Fẹla ki i le e, paapaa to ba ti wulo fun iṣẹ ti wọn n ṣe, boya o mọ orin i kọ daadaa, to si lohun orin, tabi ilu lo mọ-ọn lu to tun ni ẹbun rẹ, bo si jẹ ijo lo n jo to jẹ onijo ara ọtọ. Bo ba ti de ile Fẹla to sọ pe oun mọ kinni naa i ṣe, ti wọn si dan an wo ti wọn ri i pe loootọ ni, kia ni wọn yoo gba a lati maa kọrin, ati lati maa ba Fẹla ṣere. Ọpọ awọn ọmọ ti wọn n ṣe bayii nigba naa, awọn ọmọ ti wọn sa kuro ni ileewe ni. Ẹlomiiran yoo ni oun ko kawe mọ, ọmọ ẹyin Fẹla loun fẹẹ maa ṣe, nitori ijo ni iṣẹ ti oun fẹran ju, tabi pe orin ni oun mọ lati kọ julọ, oun o si fẹ iṣẹ mi-in rara. Ohun ti awọn ọmọ yii ṣe n sa lọ si ẹyin Fẹla ni pe aye ọjọ naa yatọ si ti asiko yii pupọ, ko si obi kan ti yoo fẹ ki ọmọ rẹ ṣe iṣẹ orin, tabi iṣẹ ilu, tabi iṣẹ ijo.

Funra awọn ọmọ ni wọn n sọ pe iṣẹ ti awọn yoo ṣe niyẹn, ọmọ to ba si ti mu iru iṣẹ ijo tabi ti orin bẹẹ, wọn yoo le e jade nile ni, bi wọn ko si le e, nigba ti wọn ba fẹẹ pa a pẹlu ẹgba atori tabi koboko, ọmọ naa yoo fẹsẹ fẹ ẹ. Bi ọpọlọpọ awọn ọmọ yii ti n de ẹyin Fẹla niyi. Ọpọlọpọ awọn obi ni wọn yoo bẹrẹ si i ba awọn ọmọ wọn ja pe kin ni wọn wa lọ si ile Fẹla, bi ẹlomiiran ba si gbọ pe ọmọ oun wa nibẹ, yoo mọ ọna ti yoo fi mu un. Awọn obi miiran ki i ṣe bẹẹ, ọlọpaa ni wọn yoo lọọ pe, wọn yoo si ni ki ọlọpaa lọọ mu Fẹla, nitori oun lo gba ọmọ wọn sile, awọn mi-in yoo si sọ pe o ji ọmọ awọn gbe ni. Ṣugbọn ọpọ awọn ọmọ yii ni Fẹla funra rẹ ki i mọ, awọn maneja ti wọn n gbaayan si ere ati ijo ni wọn maa n gba wọn, o digba ti wọn ba n ṣere ko too da wọn mọ laarin wọn. Nipa bẹẹ, ko si ẹjọ kan ti ẹnikan ri Fẹla ba ṣe.

Ṣugbọn eleyii ko fun un ni orukọ rere laarin awọn obi ti wọn bimọ wọn, wọn yoo si maa fi bu awọn ọmọ wọn nile pe, “Ṣe o fẹẹ ya ọmọ Fẹla ni!” tabi “Ki o too ya ọmọ Fẹla si mi lọrun ninu ile yii, oju wa ni yoo ṣe!” Nidii eyi, gbogbo awọn ọmọ ti wọn ba ti ri lẹyin Fẹla, paapaa awọn ọmọbinrin, ọmọ alaigbọran ni wọn n pe wọn, nitori awọn ọmọ ti wọn sa kuro nile lo maa n pọ ju ninu wọn. Nigba to si jẹ igbo mimu ati siga mimu ko ṣe ajoji nile Fẹla, wọn yoo sọ pe amugbo ni wọn, Fẹla lo n kọ wọn ni igbo mimu. Eleyii naa ni ijọba tun sọ mọrọ, wọn ni Fẹla n kọ awọn ọmọ ọlọmọ ni iṣekuṣe ati iwakiwa ti ko ba awujọ mu. Ijọba ko sọ pe funra awọn ọmọ yii ni wọn n lọ si ile Fẹla o, pe Fẹla ko ranṣẹ pe ẹnikan ri tabi ko lọ sile ẹnikẹni lati mu ọmọ, tabi pe ọkunrin olorin naa ko da awọn ọmọ yii mọ bi wọn ba ṣẹṣẹ de ọdọ rẹ.

Lọrọ kan, ijọba ni awọn ko ni i fi aaye gba Fẹla ko maa ba aye awọn ọmọ keekeeke jẹ, awọn o ni i jẹ ko sọ ile rẹ di ibi ti awọn ọmọ alaigbọran ti wọn sa nile iya ati baba wọn yoo fi ṣe ibugbe, nibi ti awọn ọdaran yoo maa kori jọ si, awọn ko ni i gba Fẹla laaye ko maa daamu ijọba ati awọn agbofinro gbogbo. Ijọba ni iṣẹ ti awọn gba, ko ju ki awọn daabo bo ẹmi awọn eeyan, ki awọn si fun wọn ni igbe-aye rere lọ, awọn ko si ni i gba ẹni kan ṣoṣo laaye lati di awọn lọwọ iṣẹ yii, gbogbo ohun to ba gba lawọn yoo fun un lati ri i pe ẹnikẹni ko daamu ijọba. Wọn ni bo ba jẹ ere ati ohun ti Fẹla fẹẹ ṣe ree, ko wa ibomi-in ti yoo ti maa ṣe e. Wọn ni iyẹn lo ṣe jẹ ofin ti awọn ṣe yii, lẹsẹkẹsẹ ni yoo fi ẹsẹ mulẹ, ẹnikẹni ko si gbọdọ da a kọja, afi ẹni to ba fẹẹ fara jiya, afi ẹni to ba fẹẹ fara gbẹgba.

Ẹsẹkẹsẹ lofin naa si mulẹ loootọ o, nitori niṣe ni wọn tubọ rọ awọn ṣọja si gbogbo agbegbe naa, ti awọn ṣọja gbebọn lọwọ ti wọn tun mu koboko dani, ẹni to ba si gba agbegbe naa yoo ro pe oju ogun ni. Wọn ni wọn ko gbọdọ ri ọmọ Fẹla kan ko ta regberegbe de adugbo naa mọ, bẹẹ ni wọn ko gbọdọ gbọ pe ẹnikan n pariwo tabi fajangbọn, ẹni ti awọn ba ti ri mu, yoo fi ẹnu fẹra bii abẹbẹ ni. Ta ni yoo tilẹ duro niwaju awọn ẹruuku loootọ, kaluku rin jinna si ile Fẹla, koda, Fẹla funra rẹ ko de ile ara rẹ, ara iya rẹ ko kuku si ya, aburo rẹ naa ko le yọju sibẹ, bi wọn yoo ṣe ko iwọnba ẹru ti ko ba jona mọle lo ku ti wọn n ṣe.

Bayii ni ijọba Ọbasanjọ gba Kalakuta, ile Fẹla, lọwọ rẹ, ọrọ naa si ba ọpọlọpọ awọn araalu ninu jẹ, wọn ni wọn fiya jẹ Fẹla, wọn kan lo agbara ijọba le e lori lasan ni.

(58)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.