Ijọba ipinlẹ Ogun ṣekilọ fawọn lanlọọdu ti awọn ajinigbe n lo ile wọn

Spread the love

 

Kayọde Ọmọtọṣọ, Abẹokuta

Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti ṣekilọ fawọn lanlọọdu ti awọn ajinigbe n lo ile wọn pe lọjọ ti aṣiri wọn ba tu, ijọba yoo wo ile naa palẹ, wọn yoo si gbẹsẹ le iwe aṣẹ ilẹ naa (C of O). Ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, ni gomina sọrọ naa lasiko to n ṣefilọlẹ igbimọ ti yoo ṣe iranlọwọ fun eto aabo nipinlẹ Ogun (Ogun State Security Trust Fund), nibi ti awọn aladaani yoo ti le ran ijọba ipinlẹ naa lọwọ lori eto aabo. Gomina ni ifilọlẹ eto naa jẹ amuṣẹ ileri toun ṣe lasiko ipolongo ibo pe oun ko ni i fọwọ yẹpẹrẹ mu eto aabo ipinlẹ naa.

O ni eto iranlọwọ fun aabo naa jẹ ti ileeṣẹ aladaani, ninu eyi ti wọn yoo ti ran ijọba ipinlẹ naa lọwọ lori ọna lati mu eto aabo rinlẹ si i nipinlẹ Ogun. Ninu atẹjade ti Oluranlọwọ pataki lori eto iroyin rẹ, S.F Ojo, fi ṣọwọ si awọn oniroyin lo ti ṣalaye pe ijọba nigbagbọ pe agbekalẹ eto yii yoo mu eto aabo gbopọn si i nipinlẹ Ogun.

Ẹni to jẹ alaga igbimọ yii ni Ọgbẹni Bọlaji Balogun, awọn ọmọ igbimọ to ku si ni igbakeji ọga ọlọpaa lorileede yii tẹlẹ, Olushọla Subair, Ṣeyi Kumapayi to jẹ adari Bank Commercial, Ṣeyi Oyefẹsọ ti First Bank, adari ileefowopamọ Wema, Wọle Akinlẹyẹ, ti Ọpẹyẹmi Agbaje yoo si jẹ akọwe wọn.

Gomina ni ojuṣe igbimọ naa ni lati wa owo ti wọn yoo fi pese ohun eelo fun awọn oṣiṣẹ alaabo nipinlẹ naa, eyi ti yoo mu adinku ba iwa ọdaran nipinlẹ Ogun. Bakan naa, awọn igbimọ yii ni yoo mojuto ọna ti wọn ba gba na owo naa, ki eto aabo baa le fẹsẹ rinlẹ si i.

Nigba to n fesi, alaga igbimọ naa, Bọlaji Balogun, dupẹ lọwọ gomina fun akitiyan rẹ lati ri i pe eto aabo fẹsẹ rinlẹ si i nipinlẹ naa. O waa ṣeleri pe awọn yoo ṣa gbogbo ipa awọn lati jiṣẹ ti ipinlẹ Ogun ran awọn lai figba kan bọ ọkan ninu

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.