Ijọba ipinlẹ Eko ti fun ẹbi oṣiṣẹ LASTMA ti wọn ṣekupa lowo

Spread the love

Wọn ti fun mọlẹbi Rotimi Adeyẹmọ, oṣiṣẹ ajọ LASTMA ti ọlọpaa kan yinbọn pa lọdun to kọja ni miliọnu mẹwaa Naira ti ijọba ipinlẹ Eko ṣeleri fun wọn lọsẹ to kọja.

Alukoro ajọ naa, Mamud Hassan, lo sọ eleyii di mimọ fun akọroyin wa lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja. O ni Akọwe ileeṣẹ to n ri si igboke-gbodo ọkọ, Dokita Taiwo Salam, lo lọọ fun idile naa ni iwe sọwe-dowo ọhun lọjọ Eti, Furaidee, ọsẹ to kọja, nile wọn to wa ni Ipaja, niluu Eko.

Atẹjade ti alukoro naa fi sita sọ ọ di mimo pe Salam ṣapejuwe Rotimi gẹgẹ bii oṣiṣẹ to jafafa lẹnu iṣẹ, ipinlẹ Eko ko si ni i gbagbe ipa manigbagbe to ko lẹka eto irinna naa. O rọ awọn mọlẹbi lati mu eto ẹkọ awọn ọmọ naa lọkun-un-kundu, to si fi kun un pe awọn ti ṣagbekalẹ ami-ẹyẹ kan ti awọn aa fi maa ṣeranti Rotimi ati oṣiṣẹ ajọ naa kan, Siraj Bakare, ẹni toun naa padanu ẹmi rẹ lẹnu iṣẹ.

Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun to kọja, ni Inspẹkiitọ ọlọpaa kan, Ọlakunle Ọlọnade, yinbọn pa Rotimi lasiko to n ṣiṣẹ ẹ laduugbo Iyana Ipaja, niluu Eko. Lẹsẹkẹsẹ lawọn eeyan naa lu ọlọpaa yii bii bara, ko si pẹ rara toun naa fi jade laye. Alukoro ọlọpaa, Chike Oti, ṣalaye nigba naa pe Imohimi Edgal ti paṣẹ pe ki wọn yọ Ọlakunle niṣẹ, lẹyin ti wọn ba oku rẹ ṣẹjọ tan.

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.