Ijọba ibilẹ: Ile-ẹjọ to ga ju da Ẹda-Oniyọ lare lẹyin ọdun mọkandinlogun

Spread the love

Ile-ẹjọ to ga julọ nilẹ yii ti da Ọba Julius Ọladipọ Awolọla, Ẹlẹda tilu Ẹda-Oniyọ, atawọn eeyan ilu naa lare lori ibudo to yẹ kijọba ibilẹ Ilejemeje, nipinlẹ Ekiti, fikalẹ si lẹyin ọdun mọkandinlogun tẹjọ naa bẹrẹ. Ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja nidajọ naa waye niluu Abuja.

 

Idajọ igbimọ ẹlẹni-marun-un ti Onidaajọ Ọlabọde Rhodes-Vivour ṣaaju naa ni pe ijọba to gbe sẹkiteriati Ilejemeje kuro ni Ẹda-Oniyọ lọ si Iye-Ekiti ru ofin, wọn ko si lẹtọọ lati gbe igbesẹ naa.

 

Iwadii ALAROYE fi han pe lẹyin oṣu mẹta pere ti wọn da ipinlẹ Ekiti silẹ lọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa, ọdun 1996, nijọba ipinlẹ naa gbe olu ijọba ibilẹ Ilejemeje lọ si Iye-Ekiti. Eyi lo mu Ọba Awolọla lọọ fẹhonu han nile ijọba ilẹ yii l’Abuja, ṣugbọn olori ijọba igba naa ni ki i ṣe oun loun paṣẹ ọhun.

 

Nigba ti ko si ọna abayọ ni kabiyesi, lorukọ awọn eeyan ilu rẹ, gba ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ekiti lọ lọdun 1999. Lọdun 2001 ni kootu dajọ pe ọba yii jare, ko yẹ ki wọn gbe ibudo Ilejemeje kuro ni Ẹda-Oniyọ.

 

Ṣugbọn ijọba igba naa gba ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lọ lati tako idajọ yii. Lọjọ kẹfa, oṣu kẹta, ọdun 2006, ni kootu naa dajọ pe ijọba jare lori igbesẹ ti wọn gbe. Eyi lo mu Ọba Awolọla gba ile-ẹjọ to ga ju nilẹ yii lọ lọdun 2008, nipasẹ Amofin Oluwadamilare Awokọya.

 

Nigba to n ka idajọ naa lorukọ awọn mẹrin to ku lopin ọsẹ to kọja, Onidaajọ Paul Galinje ṣalaye pe bi wọn ṣe gbe ibudo ijọba ibilẹ Ilejemeje si Ẹda-Oniyọ lati ibẹrẹ pẹpẹ ba ofin mu ni gbogbo ọna, ko si sẹni to yi ofin naa pada, eyi ni igbesẹ lati gbe e kuro nibẹ ṣe tako ofin.

 

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.