Ijọba Ekiti san miliọnu mẹrinlelogun fun idanwo WAEC

Spread the love

Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, ti fọwọ si sisan miliọnu mẹrinlelogun (24,000,000), Naira fawọn ọga-agba ileewe girama ijọba kaakiri ipinlẹ naa fun idanwo aṣekagba WAEC ti yoo waye laarin oṣu to n bọ si oṣu kẹrin, ọdun yii.

Owo naa lo jẹ asansilẹ fawọn akẹkọọ to din diẹ ni ẹgbẹrun mẹta ati irinwo (13, 390) ti wọn ṣetan lati ṣedanwo ọdun yii.

Ikede yii waye latẹnu ọga-agba ileeṣẹ eto ẹkọ, sayẹnsi ati imọ-ẹrọ tipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Ayọdeji Ajayi, lopin ọsẹ to kọja.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ẹgbẹrun kan ati ẹgbẹrin-le-aaadọta (1, 850) Naira lo ni ijọba san lori ọmọ kọọkan lati mojuto awọn owo ti wọn nilo fun idanwo naa. O ni ko si idi ti olori ileewe kankan yoo fi gba owo lọwọ awọn akẹkọọ mọ lori ọrọ WAEC, ati pe ijọba ti pese awọn ohun eelo ẹkọ mi-in tileewe kọọkan nilo.

O waa ṣekilọ pe ko sileewe ti wọn gbọdọ ka magomago idanwo mọ lọwọ nitori ijọba ko ni i gba iru rẹ laaye ni gbogbo ọna, ẹni tọwọ ba si tẹ yoo da ara rẹ lẹbi.

(29)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.