Ijọba Buhari, ẹ n fi titi-marosẹ Eko s’Ibadan yii ni wa lara o

Spread the love

Loootọ ni ijọba apapọ ti sọ pe ọdun 2021, ọdun mẹta sasiko yii, lawọn yoo too pari ọna Eko s’Ibadan, ṣugbọn awọn ohun to n ṣẹlẹ, inira buruku to n koju araalu, ko jẹ ki ọkan awọn eeyan balẹ, niṣe lo si mu ọdun mẹta ti wọn da yii da bii ọgbọn ọdun. Ati pe ọrọ ijọba wa yii ko ṣee tẹle rara, irọ ojoojumọ, irọ oriṣiiriṣii ko jẹ ki ẹnikẹni gba wọn gbọ mọ, agaga lori ọrọ ọna marosẹ Ibadan si Eko yii o. Aimọye igba ni wọn ti pariwo pe ọna naa yoo pari ni 2017, yoo pari ni 2018, yoo yanju ni 2019, eyi ti a si tun gbọ bayii ni pe ọdun 2021 ni yoo pari. Ewo la fẹẹ gbagbọ o, ati pe ki lo sọ fun wa pe wọn ko tun ni i sọ ọdun 2021 naa di ọdun 2023. Idi ti awọn nnkan tiwa fi ri bayii ko ye ẹni kan. Gbogbo ọrọ tiwa ni i mu wahala dani ṣaa. Afi bii pe Naijiria yii nikan ni wọn ti n ṣe titi, tabi pe awọn oṣiṣẹ Julius Berger ti wọn ṣe ọna fun wa yii ki i ba wọn ṣiṣẹ nibomi-in, titi de awọn orilẹ-ede to yi wa ka bii Ghana, Togo ati Bẹnnẹ. Ki lo de ti tiwa kuku fi ri rakaraka bayii. Owo ti wọn yoo fi ṣe ọna mẹta-mẹrin fun wọn ni Ghana ni wọn yoo fi ṣe ọna kan ṣoṣo fun wa ni Naijiria, bẹẹ awọn ọna naa ko ni i ju ara wọn lọ. Bi wọn ba tun waa ṣe bẹẹ tan, titi ti wọn ṣe fun wọn ni Ghana ko ni i bajẹ laarin ọdun marun-un o kere tan, ṣugbọn tiwa ko ni i lo ọdun meji ti yoo fi maa san pẹẹpẹẹ, ti koto yoo si bẹrẹ si i yọ nibẹ kiakia. Ni orilẹ-ede ti ori awọn alaṣẹ ti pe daadaa, wọn ko ni i ṣe iṣẹ ọna nla bii ti Ẹspirẹẹsi Ibadan yii bayii. Ki wọn too dawọ le e ni wọn yoo ti ṣe ọna ti awọn eeyan yoo maa gba, oriṣiiriṣii ọna keekeekee ni wọn yoo ti ṣe silẹ, nibi ti awọn eeyan le gba, yatọ si ki gbogbo mọto maa rọ gba oju ọna kan naa ti wọn ni awọn n tun ṣe. Ẹ wo iye oku to ti sun loju ọna yii, o fẹrẹ jẹ pe ojumọ kan, oku kan ni. Ẹ wo iye ti ijọba n sọnu lojoojumọ nipa eto ọrọ-aje ti yoo duro si oju kan nigba ti wahala ọna yii ba ṣẹlẹ, ti awọn ti wọn n lọ sibi ọja tabi awọn ti wọn n ba iṣẹ pataki ti yoo mu owo wọle fun wọn, ti wọn yoo si ri ibi san owo ori funjọba, ko ni i ri ọna lọ. Awọn eeyan kan jade ni Eko ni aago meji ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, aago mejila aabọ oru ni wọn too wọ ilu Abẹokuta. Bẹẹ lo ri fawọn ero Ibadan ati awọn mi-in to n ba ibomi-in lọ. Ọna Ibadan yii ni ọna ti mọto n gba julọ ni gbogbo agbegbe West Afrika, iye mọto to n gbabẹ laarin iṣẹju kan si le ni ogun. Ọna naa ni ijọba Naijiria fọwọ yẹpẹrẹ mu yii, ti wọn yoo sanwo loni-in, ti wọn ko ni i sanwo lọla, ti awọn minisita yoo maa fi owo kun owo iṣẹ naa lọdọọdun, ti kaluku yoo si maa ji eyi to ba kangun si i. Ọjọ wo la fẹẹ ṣe iru eleyii gba! Ki lo de ti nnkan tiwa ri bayii ni Naijiria! Abi awọn kan wa nibi kan ti wọn n ṣepe fun wa ni! Awa o le ṣe nnkan kan ko yanju ṣaa! Eleyii ma ga o!

 

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.