Ijọba awọn oyinbo ni Britain binu gidi si Balewa, nigba tawọn naa ti ọmọ ilu wọn mọle

Spread the love

Ọrọ awọn oṣiṣẹ ati awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ laye ọjọsi ko jọ ti akoko yii rara, ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe naa ni wọn yoo ṣe, nitori ẹnu wọn ko. Ootọ ni Balewa halẹ pe oun yoo da awọn ẹgbẹrun kan oṣiṣẹ silẹ, to si ni ki wọn da wọn silẹ loju-ẹsẹ, ṣugbọn ko sẹni kan to da a lohun, awọn oṣiṣẹ ko dahun, bẹẹ ni awọn to gba wọn siṣẹ ko si le kọwe fẹnikan wọn. Bẹẹ ni ko si ileeṣẹ kankan to ṣi ilẹkun, awọn oṣiṣẹ ko jẹ. Awọn ọlọpaa wa lawọn ileeṣẹ yii o, wọn ni kawọn oṣiṣẹ ma ba nnkan jẹ lawọn ṣe duro sẹnu ọna, tabi ko ma si oṣiṣẹ kan ti yoo di awọn ti wọn ba fẹẹ ṣiṣẹ wọn lọwọ. Ṣugbọn ko si oṣiṣẹ kan to de ẹnu ọna ibi iṣẹ yii, awọn ọlọpaa kan wa nibẹ wọn n ṣere, nigba ti wọn ti ṣe oju koko titi ti wọn ko ri ẹnikan ti wọn yoo kanra mọ. Bẹẹ ni aṣẹ ti Balewa pa lori awọn oṣiṣẹ naa ko ṣiṣẹ, olori ijọba Naijiria naa ko si mọ ohun ti yoo ṣe.

Ọrọ naa iba si tilẹ tete yanju bi ko jẹ ti awọn nọọsi ti wọn jade pe awọn n palẹmọ o, awọn naa fẹẹ darapọ mọ awọn oṣiṣẹ to n daṣẹ silẹ, awọn naa ko fẹẹ ṣiṣẹ kankan mọ. Ẹgbẹrun mẹfa lawọn nọọsi naa, bi wọn ba si daṣẹ silẹ loootọ, gbogbo ọsibitu ni o ni i ni nọọsi, eto ilera ati iwosan awọn eeyan yoo si bajẹ kọja ohun ti apa ijọba kan yoo ka. Nigba naa ni awọn oloṣelu ti wọn mọ nipa iru nnkan bayii dide, wọn ni ki Balewa ṣe suuru, ko pe awọn oṣiṣẹ yii, ki wọn si jọ sọ kinni naa. ibinu ko le jẹ ki Balewa pe awọn oṣiṣẹ naa, paapaa nigba ti awọn bii Ladoke Akintọla ati ọga oun Balewa funra rẹ, Ahmadu Bello n sọ fun un pe bo ba ti le jokoo pẹlu awọn oṣiṣẹ yii, gbogbo ohun ti wọn n beere fun ni yoo ṣe, wọn ni ko wa ọna mi-in to le fi mu wọn ni, bi bẹẹ kọ, awọn oṣiṣẹ yii yoo maa fi ojoojumọ yọ ijọba rẹ lẹnu ni.

Ko si ọna mi-in ti ijọba le gba, afi ko fi ọlọpaa halẹ mọ awọn oṣiṣẹ yii, bo si tilẹ jẹ pe lojoojumọ lawọn olori awọn oṣiṣẹ yii n lọ sọdọ awọn ọlọpaa, ti wọn n da wọn jokoo lati aarọ ṣulẹ, ko si kinni kan to tidi rẹ yọ, awọn oṣiṣẹ ko pada si ẹnu iṣẹ wọn, wọn si n leri pe awọn ko ni i lọ, afi ti ijọba ba ṣe ẹkunwo owo-oṣu ti igbimọ Morgan ni ki wọn fun awọn. Wọn ni bi ijọba ko ba sanwo-oṣu, ti wọn ko si ṣe awọn eto tuntun ti igbimọ naa dabaa ẹ, ki wọn ma reti oṣiṣẹ kan lẹnu iṣẹ, bi wọn ba ri oṣiṣẹ kan, ki wọn mọ pe o waa ji wọn lẹru ko lọ ni. Ohun ti awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ yii waa ṣe to tubọ bi ijọba ninu ni pe wọn ṣeto lati mu awọn ọlọpaa mọra. Wọn fẹẹ fa awọn ọlọpaa mọra, wọn ni bi ijọba ba si fẹẹ fi owo kun owo-oṣu awọn, afi ki wọn fun awọn ọlọpaa lowo, nitori iya to n jẹ awọn lo n jẹ awọn ọlọpaa naa.

Awọn olori ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ yii ni ko si bi awọn ṣe le gba ẹkunwo ti awọn yoo ni ki awọn ọlọpaa ma gba, nigba ti awọn ọlọpaa ko si le daṣẹ silẹ, ti wọn ko le ba ijọba ja nitori ofin iṣẹ wọn, afi ki awọn ti awọn jẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ ja fun wọn. Wọn ni ki ijọba mọ pe bi wọn ti n sanwo-oṣu tuntun naa fawọn ni wọn yoo san fawọn ọlọpaa, nitori oṣiṣẹ Naijiria lawọn naa i ṣe. Bii ẹni to fẹẹ da ileeṣẹ ọlọpaa ru leleyii loju ijọba, wọn ni bawọn ọlọpaa ba gbọ, wọn yoo sọ ọ laarin ara wọn, kaka ki wọn si gbeja ijọba, awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ yii ni wọn yoo maa gbeja, eyi si le da nnkan ru gidigidi ni. Loootọ lawọn ọlọpaa si ti n gbọrọ yii, ọpọlọpọ wọn si ti n dunnu pe awọn naa ti rẹni ja fun awọn, wọn ni owo-oṣu awọn naa yoo le si i, wọn ni awọn yoo maa ran awọn oṣiṣẹ lọwọ ni, awọn o jẹ ba wọn ja mọ. Kijọba ṣe ohun ti wọn n beere fun wọn.

Balewa ati awọn eeyan rẹ ti gbọ ọrọ naa, iyẹn awọn ọga rẹ ni o, wọn si ti sọrọ naa laarin ara wọn, wọn ni bi awọn oṣiṣẹ yii ba fi le ṣe ohun ti wọn n ṣe naa ni aṣegbe, ti wọn ri awọn ọlọpaa fa mọra, ki ijọba Balewa tete maa ko ẹru rẹ ni, nitori awọn ọlọpaa ko ni i gbọrọ si wọn lẹnu mọ rara. Nibẹ ni wọn ti sare jiroro, wọn ni ohun ti awọn sọ tẹlẹ naa lawọn yoo ṣe, ọrọ naa gbọdọ di mimuṣẹ bayii, ki awọn ko awọn oṣiṣẹ naa, ẹsun ti wọn yoo si fi kan wọn ti wa nilẹ, wọn fẹẹ doju ijọba de, wọn fẹẹ fi tipa gbajọba lọwọ Balewa, gbogbo ariwo ti awọn alatako ba fẹẹ pa ki wọn tete pa a. Loootọ wo mọ pe ọrọ naa ko ri bẹẹ, ko si si ohun to jọ ọ, ṣugbọn bi wọn ba ko awọn oṣiṣẹ yii ti wọn ti wọn mọle lori ẹsun pe wọn fẹẹ fipa gbajọba Naijiria, ti wọn ko wọn de kootu lẹsẹkẹsẹ, ko sẹni ti yoo gbeja wọn mọ, awọn oṣiṣẹ to ku yoo si pada sẹnu iṣẹ wọn.

Bẹẹ ni ijọba Balewa ṣe. Ojiji ni wọn ṣe kinni naa, ọrọ naa si ya gbogbo eeyan lẹnu. Ọjọbọ kan bayii ni, ọjọ Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹfa, ọdun 1964, niṣe ni awọn ọlọpaa ya sigboro, awọn ọlọpaa naa si le laaadọta, awọn ọga wọn lo fọn wọn kaakiri. Ṣe oyinbo ni olori awọn ọlọpaa ilẹ Naijiria nigba naa, oyinbo ọhun lolori wọn l’Alagbọn.  Lynn lorukọ rẹ, oyinbo to n ṣiṣẹ fawọn Sardauna ni, nitori a maa sọ pe ọmọ Hausa loun, bo tilẹ jẹ pe alawọ funfun loun. Oyinbo yii ni wọn fi mu Ọbafẹmi Awolọwọ, oun lo lọ sile baba naa ni Ikẹnnẹ, oun lo si sọ pe oun ba ọta ibọn ati ibọn nibẹ, bo tilẹ jẹ pe Awolọwọ sọ pe irọ buruku lo n pa. Gbogbo eelo ati awọn eeyan ti wọn mu fun ẹsun Awolọwọ yii, Lyn yii lo wa wọn jade, ẹjọ to si gbe kalẹ naa ni o fi ran Awolọwọ sẹwọn.

Nidii eyi, ẹni to ba ti gbọ orukọ ọga ọlọpaa ti wọn n pe ni Lyn, agaga to ba jẹ nidii ọrọ a-n-fipa-gbajọba ni, tọhun yoo sa jinna ni, nitori bi tọhun ko ba tete sa danu, ti wọn ba fi ko ṣẹkẹṣẹkẹ si i lọwọ bẹẹ, ẹwọn ni yoo lọ. Ọkunrin Lynn yii naa lo da awọn ọlọpaa sita, o si ti sọ awọn ti wọn yoo mu wọn fun wọn. Ile Alaaji Haruna Adebọla ni wọn kọkọ lọ, wọn si bẹrẹ si i saaji ile naa wo, wọn gbọn ile rẹ yẹbẹyẹbẹ. Wọn o sọ ohun ti wọn n wa fẹnikan, koda wọn ko wi fun ọkunrin olori ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ naa paapaa, oun naa kan ri ọpọlọpọ ọlọpaa nile rẹ lẹẹkan ni, wọn si ni awọn waa saaji ile rẹ wo ni, awọn n wa nnkan kan, awọn ko si ni i sọ ohun ti awọn n wa fun un. Iru ki leleyii lọkunrin naa n wi, nigba to si beere pe ṣe nitori ọrọ pe awọn oṣiṣẹ da iṣẹ silẹ ni wọn ṣe waa n yẹ ile oun wo, wọn ni ki i ṣe bẹẹ, ọtọ loun ti awọn n wa.

Odidi wakati meji ataabọ ni wọn lo ninu ile rẹ, bẹẹ ile kekere bayii ni, wọn si duro sinu yara oun nikan fun odidi wakati kan, nigbẹyin ni wọn jade nigba ti wọn ko ri nnkan ti wọn n wa. Amọ lasiko ti wọn n saaji ile Alaaji Adebọla yii, awọn mi-in wa nile Michael Imoudu, awọn naa n yẹ ile rẹ wo lati oke delẹ, wọn n saaji rẹ, wọn ni awọn n wa kinni kan. Nigba ti wọn de ile rẹ yii, oun ko tete jẹ ki wọn wọle, nitori oun funra rẹ wa nile. O ni kin ni wọn n wa, wọn si sọ fun un pe oun lawọn waa ri. Imoudu ni kin ni wọn fẹẹ ri oun fun, pe to ba jẹ ọrọ awọn oṣiṣẹ to n daṣẹ silẹ lọwọ ni, ki i ṣe oun ni wọn yoo waa ri, ki wọn lọ si ọdọ awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ nibi ti aṣẹ ti n jade, ki i ṣe lọdọ toun ni wọn yoo ti gbọ nnkan kan. Nigba naa lawọn ọlọpaa yii sọ fun Michael Imoudu pe ki i ṣe ọrọ oṣiṣẹ to n daṣẹ silẹ lawọn ba wa o.

Nigba naa ni Imoudu too jẹ ki wọn wọ ile oun, o si ni ki awọn ọlọpaa naa kọkọ wa ki oun yẹ ara awọn naa wo ko too di pe wọn wọnu ile oun wa. Ohun to fa a ti Imoudu fi ṣe bẹẹ ni pe awọn ọlọpaa ti Lynn ba ran jade ko ṣee fọkan tan, ko si ohun ti wọn ko le ṣe. Bi wọn ba sọ ẹru ofin si ile onitọhun tan, wọn yoo ni ile rẹ lawọn ti ba a. Eleyii lo ba Imoudu lẹru to fi sọ pe ko si ẹni ti yoo wọ ile oun ninu awọn ọlọpaa naa bi oun ko ba kọkọ yẹ ara wọn wo. N lawọn ọlọpaa naa ba duro, wọn ni ko ṣaaji awọn, nigba to si saaji wọn tan lo too jẹ ki wọn wọ inu ile rẹ. Awọn ọlọpaa naa duro sinu ile rẹ, wọn yẹ yara rẹ wo, ati palọ, ati ile ikẹru-si, wọn ko si jade ninu yara rẹ fun bii wakati mẹta. Lẹyin ti wọn ti yẹ ile oun naa wo ti wọn ko ri ohun ti wọn ni awọn n wa, wọn ni awọn n lọ, amọ ki Imoudu de agọ awọn ko waa ri wọn.

Imoudu sọ fun wọn pe oun ko ni i wa ni toun o, afi ti wọn ba waa fi tipatipa gbe oun, nitori ko si ohun ti oun fẹẹ ri wọn fun. N lawọn ọlọpaa ba ni awọn ti gbọ, awọn yoo lọọ sọ fọgaa awọn to ran awọn niṣẹ. Bi Michael Imoudu ti n ba awọn ọlọpaa to wa a wa fa a naa lawọn mi-in n da wahala tiwọn silẹ ni ile Wahab Goodluck. Goodluck yii naa, olori ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ni, o si wa ninu awọn to taku pe awọn oṣiṣẹ ko ni i pada sẹnu iṣẹ wọn. Lojiji lawọn ọlọpaa ya bo ile oun naa, wọn ni awọn n wa kinni kan, ko ṣilẹkun ile rẹ silẹ fawọn gbayau, awọn ko fẹ ko di awọn lọwọ, nitori bo ba di awọn lọwọ, awọn yoo kọ ọ sinu iwe pe o n di iṣẹ ijọba lọwọ, awọn yoo si fi tipatipa wọ ọ de agọ ọlọpaa awọn, bo ba si debẹ, ohun ti oju rẹ ba ri, oun naa ko ni i le fẹnu ara rẹ sọ. Wahab Goodluck loun o jampata, ki wọn saaji ile oun daadaa.

Wọn wa ile naa titi loootọ, wọn lọ siwaju, wọn lọ sẹyin, wọn si pariwo titi nibẹ, ṣugbọn wọn ko ri kinni kan. Nigba ti wọn ko ri nnkan kan yii, ti wọn si ni awọn fẹẹ maa lọ ni Goodluck ṣẹṣẹ waa beere lọwọ wọn pe kin ni wọn n wa gan-an, ki lo bọ sọnu ti wọn ko sọ foun ti wọn fi n saaji ile oun. Awọn ọlọpaa ni awọn mọ ohun ti awọn n wa, ko si si eyi to kan an ninu ọrọ naa, bo ba jẹ awọn ri i ni, awọn yoo ti sọ fun un, nigba ti awọn ko si ri ohun ti awọn wa wa, ko jẹ ki awọn maa lọ, ko ma da kun iṣoro ara rẹ, ohun ti ko ba mọ, ko ma da si i rara. Goodluck yii naa tun bi wọn pe ṣe ọrọ ija awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ yii naa ni, wọn ni ki i ṣe iyẹn, bo ba jẹ iyẹn ni, awọn iba ti sọ fun un. Ọrọ naa si ru Goodluck loju, paapaa nigba ti wọn tun sọ fun un pe ki oun naa yọju si awọn lọgba wọn, ko waa ri ọga awọn ti wọn n pe ni Lynn.

Bẹẹ naa ni wọn tun lọ si ile awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ to lorukọ, wọn si saaji ile wọn yikayika, lẹyin naa ni wọn si wọ ọpọlọpọ wọn pe ki wọn waa ri awọn ni teṣan ọlọpaa ni Alagbọn. Nigba ti wọn de Alagbọn, ti ọpọlọpọ wọn foju kan Lynn ni wọn too mọ ohun to ṣẹlẹ gan-an, ṣugbọn ki i ṣe pe wọn mọ naa, wọn kan n gbọ ohun ti wọn wi ni, Lynn n beere lọwọ wọn pe ṣe wọn wa ninu awọn ti wọn fẹẹ fipa gbajọba lọwọ Tafawa Balewa ti i ṣe olori Naijiria. Ko sẹni to gbọ iru ọrọ bẹẹ ri ninu wọn, ṣugbọn awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ yii ti mọ ọrọ oṣelu Naijiria, wọn mọ pe wọn fẹẹ ko ṣẹkẹṣẹkẹ si awọn lọwọ ni. Iyẹn lo jẹ ki kaluku wọn pariwo, ti wọn si yari mọ awọn ọlọpaa yii lọwọ pe awọn ko mọ ohun ti wọn n sọ rara, awọn ko ba ẹni kankan gbimọ lati gbajọba, awọn ko si mọ ẹni yoowu to n mura lati gbajọba.

Awọn eeyan wọnyi ko mọ ohun to n lọ, afi nigba to di ọjọ keji ti wọn gbọ ariwo. Wọn ko mọ pe gbogbo bi awọn ọlọpaa ti wọn wa sile wọn yẹn, wọn ti mu ọkunrin oyinbo onirungbọn kan, Victor Leonard Allen lorukọ rẹ. Wọn ti mu ọkunrin yii, wọn si ti ti i mọle, wọn ni wọn ba awọn iwe kan lọwọ rẹ to jẹ eyi ti wọn fẹẹ fi gbajọba. Oyinbo ni Allen, Britain lo ti wa, olukọ ni ni yunfasiti, Leeds University ni England lo ti wa. Ki i ṣe ajoji to ba ẹburu wọlu o, ọkunrin naa n ṣe iṣẹ iwadii lori ọrọ awọn oṣiṣẹ ati ijọba ni ilẹ Afrika, ohun ti wọn fun un ni iwe iṣẹ lati lọọ wadii nipa rẹ niyẹn, wọn si sọ pe oṣu mẹfa ni yoo lo ni Naijiria. O ti wa ni Naijiria lati inu oṣu keji, ọdun 1964 yii, o si di inu oṣu kẹjọ ki iṣẹ rẹ too pari. Amọ ninu oṣu kẹfa ti wahala awọn oṣiṣẹ bẹrẹ yii, ijọba Naijiria lọọ mu un lojiji, wọn si ti i mọle.

Ọjọ keji ni wọn gbe e de ile-ẹjọ, ile-ẹjọ Majisireeti ni Eko ni wọn gbe e lọ, nibẹ ni Olupẹjọ, Ọgbẹni Charles Kaduru to jẹ supritẹndẹnti awọn ọlọpaa ti sọ pe awọn mu ọkunrin oyinbo yii nitori o fẹẹ doju ijọba Naijiria bolẹ, oun pẹlu awọn oṣiṣẹ fẹẹ gbajọba lọwọ Balewa ni. Iwaju Adajọ AbdulRaheem Bakare ni wọn gbe e lọ, nigba ti wọn si ro gbogbo ẹjọ naa kalẹ, wọn ni ki Allen sọrọ boya ki wọn gba beeli rẹ tabi ko maa lọ si ọgba ẹwọn ni Kirikiri, nibi ti awọn yoo ti i mọle si titi ẹjọ rẹ yoo fi bẹrẹ ni pẹrẹwu. Allen ni oun ko mọ ohun ti wọn n sọ, ṣugbọn oun fẹ ki wọn fun oun ni beeli, ki oun le maa ṣiṣẹ oun lọ, nitori iṣẹ loun waa ṣe ni Naijiria, oun ko mọ kinni kan nipa ọrọ ijọba ti wọn fẹẹ gba lọwọ ara wọn. Adajọ Bakare ni oun fẹẹ fun un ni beeli, ṣugbọn nibo lo n gbe. Allen ni oun ko ni ibi ti oun n gbe, nitori arinkiri ni iṣẹ oun, ki oun gbe otẹẹli loni-in, ki oun gbe ileewe kan lọla loun n ba kiri.

Ọrọ naa ko tẹ adajọ yii lọrun, o ni bi Allen ko ba ti ni ibi kan pato to n gbe, oun ko le gba beeli rẹ, Kirikiri loun yoo fi i ranṣẹ si. Bẹẹ si ni adajọ naa ṣe. Ṣugbọn awọn aṣoju ilu oyinbo ni Naijiria dide lẹsẹkẹsẹ si ọrọ yii, ijọba ilẹ gẹẹsi naa ni nibo ni palapala ti n bọ, kin ni awọn Balewa yoo ṣe we okun mọ ẹni to waa ṣe iṣẹ rẹ lẹsẹ, kin ni wọn yoo fi ọrọ oṣiṣẹ orilẹ-ede wọn ko ba wọn. Nigba ti awọn eeyan naa ri i pe ọrọ yii yoo fọn wọn nikun, kia ni wọn ti pe ipade awọn olori ijọba Naijiria gbogbo. Akintọla wa lati Ibadan, Ahmadu Bello wa lati Kaduna, Denis Osadebey wa lati Binni, Michael Okpara si wa lati Enugu. Nibẹ ni wọn ti fẹnu ọrọ jona pe ki wọn ba awọn oṣiṣẹ yii ṣepade, ki wọn si yanju ọrọ naa ko too di ohun ti yoo sọ ijọba Naijiria lẹnu, tabi ti yoo sọ Balewa funra rẹ di ẹlẹtẹẹ loju aye.

Bẹẹ ni wọn bẹrẹ si i ṣe ipade pẹlu awọn oṣiṣẹ, wọn ni ki wọn waa sọ ohun ti wọn fẹ funjọba. Fun bii ọjọ marun-un ni wọn fi jọ n pade lojoojumọ, ti wọn si n yẹ ọrọ naa wo. Bi awọn oṣiṣẹ ti n sọ ohun ti wọn fẹ, bẹẹ ni ijọba n sọ ohun ti wọn le ṣe fun wọn. Nigbẹyin, wọn fi ẹnu ọrọ naa jona, ijọba si gba lati san owo ti awọn oṣiṣẹ n fẹ fun wọn. N nija ba pari o. Eyi lo ṣe jẹ lẹyin ọsẹ kẹrin tawọn oṣiṣẹ fi daṣẹ silẹ, wọn pada sẹnu iṣẹ wọn. Bi wọn ti pada sẹnu iṣẹ wọn yii, bẹẹ ni ko sẹni to gbọ pe wọn fẹẹ fi ipa gbajọba lọwọ Balewa mọ, wọn ko ba Allen, oyinbo, ṣẹjọ mọ, bẹẹ ni wọn ko si lọ si ile awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ pe awọn n wa nnkan kan ninu ile wọn. Ọrọ naa pari, alaafia si pada bọ, awọn oṣiṣẹ ati Balewa tun dọrẹ ara wọn.

 

 

 

 

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.