Ijọba Ṣọja fi dogbódogbò oun han adajọ, kawọn Fẹla fẹẹ bọ ara rẹ sihooho, o loun fẹẹ ọmọbinrin oun fi pẹlẹbẹ tiwọn naa han an, ladajọ ba sare gboju ẹ sẹgbẹẹ kan

Spread the love

Ni ọjọ kẹrinla, oṣu kẹta, ọdun 1977, nigba ti awọn ọmọbinrin, iyẹn awọn oṣere akọrin agbaye ti wọn n pe ni Fẹla Anikulapo Kuti, pe jọ si ile-ẹjọ Majisreeti ni Yaba, awọn marun-un lawọn adajọ ko ri ninu wọn. Mẹtalelogoji ni gbogbo awọn ti wọn fẹsun kan pe wọn ba maṣinni alupupu (Ọkada) awọn ṣọja kan jẹ, wọn si huwa to le da ilu ru ni ọjọ kejidinlogun, oṣu keji, ọdun 1977, niwaju ile Fẹla ni ojule Kẹrinla, Opopo Agege Motor Road, ni Mọṣalaṣi Idi-Oro. Ṣugbọn nigba to yẹ ki ẹjọ naa bẹrẹ pẹrẹwu, wọn ko ri awọn marun-un ninu awọn ọmọ Fẹla yii, awọn mejidinlogoji pere ni wọn ri ko wa sile-ẹjọ. Awọn marun-un ti wọn ko ri naa ni Adunni Idowu to jẹ ọmọ ogun ọdun, Comfort George to jẹ ọmọ ọdun mẹẹẹdogun pere, Bọsẹ John ti oun jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun, Fọlakẹ Ọladele toun naa jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun, ati Iyabọ Isiaka ti oun jẹ ọmọ ogun ọdun.

Awọn maraarun ko wa sile-ẹjọ. Adajọ, olupẹjọ ati awọn ero iworan kọkọ ro pe wọn yoo wa sibẹ ni, wọn si n tẹsẹ duro de wọn, nitori wọn ni awọn ọmọbinrin naa ṣe koko pupọ ninu ẹjọ ti wọn pe yii, ẹlẹrii ijọba ni wọn, awọn ni wọn si le sọ ohun to ṣẹlẹ ti wọn yoo fi ri idi okodoro ọrọ, ti wọn yoo si mọ iru ẹjọ ati ijiya to ba tọ si Fẹla ati awọn eeyan rẹ. Igba ti wọn ko waa ri awọn ọmọbinrin yii nkọ bayii, bawo ni wọn yoo ti ṣe. Ni inu ba bi ọlọpaa to jẹ olupẹjọ ijọba, iyẹn John Alao, lo ba kọju si adajọ. “Oluwa mi, ṣe ẹ ri ọrọ to wa nilẹ yii ko le rara. Ẹyin ẹ paṣẹ fun awa lọwọ kan pe ka lọọ fi tipatipa gbe wọn wa nibi ti wọn ba wa, ẹ o si ri i pe nigba ti a oo ba fi pada jokoo nibi, a oo ti ko wọn wa. Ko si wahala nibẹ, ọrọ naa ko le rara, ki ẹyin kan paṣẹ fun wa lasan ni.” John Alao lo n bọ bẹẹ, iyẹn ọlọpaa ijọba.

Bo ti sọ bẹẹ ni agbẹjọro awọn Fẹla, Alao Aka-Baṣọrun, ba fo dide. O ni, “Oluwa mi, ọrọ to wa nilẹ yii ko ma le to bi ọrẹ wa ọlọpaa ti n wi yii! Abi ki la ba lọ ki la ba bọ, ti a oo waa tori ti a fẹẹ pa ẹfọn ti a oo gbe ọmọri-odo, ti a ba ṣeeṣi la a mọ iyawo onile lori nkọ!” Alao Aka Baṣọrun ni ara awọn ọmọọbinrin naa ni ko ya, lilu ti awọn ṣọja lu wọn ko ti i tan lara wọn, bi oun si ti n sọrọ yii, wọn wa ni ọsibitu kan ni Surulere, nibi ti wọn ti n gba itọju. O ni ọsibitu aladaani ni, nitori awọn ọsibitu ijọba ti wọn ti ko wọn lọ tẹlẹ ko tọju wọn to bo ṣe yẹ, iyẹn ni wọn si ṣe ko wọn lọ si ọsibitu aladaani, ti wọn ba ti gbadun, ere lẹlẹ ni wọn yoo sa wọ kootu wa jare. Aka Baṣọrun ni ọrọ ti oun n sọ ko ni bojuboju kankan ninu, bi ọlọpaa to n fọ koko yii ba fẹẹ ri wọn, ko tẹle oun bayii bayii, oun yoo mu un de ibi ti awọn ọmọbinrin naa wa.

Ọlọpaa naa kun hunrun-hunrun niwaju adajọ, o ni oun ko ma raaye a n rin kiri ni toun o, ohun to kan oun ko ju ki awọn ọmọ yii ti wa kootu lọ, ki ẹjọ bẹrẹ, ki awọn si mọ ibi ti awọn n lọ gan-an. Nigba naa ni Adajọ Majisreeti yii, Ọgbẹni A.A.A Agbẹbi sọrọ, o ni oun paapaa foju ara oun ri awọn ọmọbinrin naa lọjọ ti wọn kọkọ wa si kootu, oun ri i pe ọpọlọpọ wọn lo ṣubu yakata ni kootu, bẹẹ lo jẹ niṣe ni wọn sare gbe awọn mi-in jade, pe bi a ba fẹẹ sọ tootọ funra wa, awọn ọmọ naa fara ṣeṣe gan-an ni o. Nitori bẹẹ, Adajọ Agbẹbi ni oun fun wọn laaye ki wọn tọju ara wọn daadaa, ṣugbọn ki wọn ri i pe wọn ti gbadun ko too di ọjọ kẹrin, oṣu karun-un, nitori lọjọ naa lawọn yoo bẹrẹ ẹjọ yii ni pẹrẹwu. O waa yiju si aka Baṣọrun, o ni ko kilọ fun awọn ọmọbinrin to n wa si kootu paapaa ki wọn ṣe jẹjẹ, kootu ki i ṣe ile-ijo o.

Adajọ ko le ṣe ko ma da ọjọ gbọgbọrọ bẹẹ fun idajọ ọhun, ko si le ṣe ko ma faaye gba awọn ọmọ Fẹla lati tọju ara wọn, nitori ọrọ ẹjọ Fẹla yii ti di wahala si ijọba lọrun gidi. Ọrọ naa n ba orukọ ijọba ologun Ọbasanjo jẹ lẹyin odi, gbogbo eeyan lo si n kọ ọrọ odi sinu awọn iwe iroyin, paapaa awọn iwe okeere, ti wọn n sọ pe awọn ko ri iru ijọba ika bẹẹ yẹn ri. Yatọ si eyi, awọn oniroyin ti kọ ọrọ naa pẹlu ariwo debii pe gbogbo araalu ati awọn eeyan agbaye ni wọn n reti ohun ti wọn fẹẹ ṣe fun awọn ṣọja ti wọn dana sun ile akọrin naa, wọn si fẹẹ roju awọn ṣọja ti wọn ba nnkan meremere bẹẹ yẹn jẹ nigba ti ki i ṣe pe oju ogun ni wọn lọ. Awọn oniroyin ti lo fọto ti Bẹẹkọ ko lọ siwaju ile igbimọ nijọsi, gbogbo aye si ti ri i pe ko si tabi-ṣugbọn nibẹ, awọn ṣọja ni wọn dana sun ile naa, ohun ti ijọba fẹẹ ṣe fun wọn ni wọn n reti.

Orukọ ijọba to n bajẹ yii ko tẹ awọn Ọbasanjọ lọrun, wọn o kan mọ bi wọn yoo ṣe tete sare fi opin si i ni. Ki orukọ naa ma bajẹ jinna, niṣe ni wọn ki ọkunrin oniroyin ilu oyinbo kan mọlẹ, wọn gbe e ni janto, wọn si da a pada si orilẹ-ede rẹ lọwọ kan. John Darnton lorukọ oyinbo naa, oniroyin New York Times ni. Lati igba ti ẹjọ naa ti bẹrẹ lo ti n kọ iroyin loriṣiiriṣii, gbogbo ohun to ba si ri ni Eko ati eyi to gbọ lo n gbe jade, bẹẹ lo ti kaakiri gbogbo ibi ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹ, to si ti ba awọn araadugbo sọrọ, ohun ti iwe iroyin naa si n gbe jade l’Amẹrika le, bẹẹ oun to jẹ aṣoju wọn l’Ekoo lo n fi gbogbo rẹ ranṣẹ si wọn. Nitori ẹ lo ṣe jẹ nigba ti awọn ọlọpaa tun pade ọkunrin Darnton yii ni National Theatre, Iganmu, niwaju igbimọ Anya to n gbọ bi iṣẹlẹ naa ṣe waye, niṣe ni wọn ṣu u rugudu.

Wọn gbe e janto ni o, wọn ni ọga awọn n pe e ni teṣan, awọn ọlọpaa to si ragabu ẹ lẹẹkan naa le ni meje si mẹjọ. Ọrọ naa ka awọn Ẹmbasi Amẹrika lara, wọn ni ki lo de gan-an. Ṣebi ki i kuku tiẹ ṣe Naijiria nikan ni ọkunrin oniroyin yii n ṣoju fun, gbogbo Afrika ni, o kan jẹ Ikoyi, l’Ekoo, ni ọfiisi rẹ wa ni. O ti wa ni Naijiria paapaa, o ti le ni ọdun kan ko too di pe ija de yii, awọn ijọba paapaa si ti n kan saara si i pe o maa n kọ ọrọ daadaa ranṣẹ si iwe iroyin wọn l’Amẹrika, to jẹ niṣe ni wọn maa n pọn ọn le bi wọn ba ti ri i, afi bi ọrọ Fẹla ti waa de yii to sọ wọn di ọta ara wọn. Bi wọn si ṣe gbe e lọjọ ti a n wi yii, ọdọ awọn ọga wọn ni wọn gbe e lọ, ko si pẹ ti wọn gbe iwe ẹ jade, wọn ni ko maa pada lọ si Amẹrika, awọn ko fẹ oun ati iwe iroyin rẹ mọ, o jọ pe orin Fẹla ti ko si i lagbari, ko si mọ ohun to n kọ jade mọ.

Nibi yii gan-an lo ti han pe nnkan ko lọ deede fun ijọba paapaa lori ọrọ ti Fẹla yii, wọn ti tọwọ bọ ọ tan ki wọn too mọ pe ohun ti yoo nira fawọn ni. Lootọ ni wọn le Darnton ara Amẹrika jade, ṣugbọn awọn oniroyin to ku ko yee ṣu lọ, ṣu bọ, niwaju igbimọ to n wadii awọn ohun to ṣẹlẹ lọjọ ti wọn dana sun ile Fẹla yii, bi Adajọ Kalu Anya si ti n pariwo to pe ki wọn ma kọ ohun ti oun ko ba sọ, awọn aṣiri to n jade nibẹ paapaa ko ṣee bo mọ abẹ ewe, gbogbo aṣiri ati awọn ọrọ naa lo si n fihan pe awọn ṣọja yii lo ṣe aṣeju, wọn tori eku kekere, wọn dana sun ile ni. Adajọ Anya ti pe awọn panapana ti wọn ko tete pa ina to n jo nile Fẹla, o ti ni ki wọn maa bọ, o pe awọn ṣọja naa wa ki wọn waa sọ tẹnu wọn, ati awọn ọlọpaa paapaa, nitori awọn wọnyi lọrọ kan niwaju igbimọ, Adajọ Anya ni wọn lọrọ lati sọ.

Awọn panapana wa, awọn ọlọpaa naa wa, ṣugbọn wọn ko ri ṣọja ẹyọ kan bayii nibẹ, wọn ṣe bii ẹni pe ọrọ naa ko kan awọn ni. Awọn panapana to wa, awọn ti wọn sọ pe awọn de ile Fẹla bayii lasiko ti ina naa n jo ni. Daniel Ahia ni oun loun ṣaaju awọn panapana naa de ile Fẹla, gbogbo erongba awọn si ni ki awọn pa ina to n jo naa kia, ko too di pe o ran mọ ile mi-in, tabi ti yoo ba ile naa jẹ kọja atunṣe. Daniel ni iyẹn loun ṣe ṣaaju, ti oun si ko awọn panapana to ku sodi, pe ki awọn ṣe iṣẹ naa bii iṣẹ lọwọ kan. Ṣugbọn nigba ti wọn debẹ, ọga wọn to n pana naa ni ohun ti awọn ro kọ ni awọn ba, ati pe bi ko ba jẹ ti ọga ṣọja kan ti oun jẹ Mejọ (Major) ninu awọn ologun, ati ọlọpaa Supo kan ti wọn n pe ni Supiritẹndẹnti, boya lawọn iba mori dele lọjọ naa, nitori loootọ loootọ, oju ogun le o jare!

Daniel ni, “Ṣẹ ẹ ri i nigba ti mo debẹ, bi awọn ṣọja ti ri wa bayii ni wọn sare si wa, ti wọn si bo mọto wa bii igba ti eera ba bo ṣuga. Ki i ṣe pe wọn sare waa ba wa ki wọn le pade wa, wọn waa lu wa ni. Niṣe ni wọn gba mọto naa gbagba,  gbagba, ti wọn n la idi ibọn wọn mọ ọn, ti wọn si mura lati ba a jẹ. Bo ba tilẹ jẹ mọto ni wọn bajẹ, ṣe yoo ṣe e tunṣe, ṣugbọn niṣe ni wọn sare wa si idi siarin mọto naa, ti wọn wọ oun fura oun bọ silẹ, wọn si ko kinni kan bo oun, bitin lo n jẹ. O ni nibi ti wọn ti n na oun ti wọn n si n beere pe ki loun n wa, ki lo bọ sọnu lọwọ oun, nibẹ ni awọn ọga ṣọja ati ọlọpaa ti oun wi ti jade sawọn, ni wọn ba fi ọgbọn ba awọn ṣọja naa sọrọ, ti wọn si rọra yọ oun, wọn ni bi oun ba ni ẹmi ara oun i lo, ki oun ma duro mọ, ere tete ni teku ageege! Daniel ni bawọn ṣe tu danu ni tawọn niyẹn o!

Ni ti Ọgbẹni Godwin Quaishigah, panapana loun naa o, ọga si ni, o ni awọn ti mura wa nijọ naa, imura ti awọn si mu wa ni kawọn pa ina naa kia. Gbogbo eroja ti awọn yoo lo lawọn ko dani paapaa, awọn si ti jiroro laarin ara awọn pe bi awọn ba ti debẹ, ki iṣẹ bẹrẹ pẹrẹwu ni. Ṣugbọn bi awọn ti n gbe mọto awọn silẹ pe ki awọn tilẹ lọọ wo oju ilẹ, bẹẹ ni ọga ṣọja kan waa ba awọn pẹlu okunrin kan ti oun naa jẹ ologun, ṣugbọn ti ko wọṣọ, awọn ni wọn si sọ fun awọn pe eti awọn meloo, nigba ti awọn si sọ pe meji ni, wọn tun beere pe ki lawọn fi n gbọ, lawọn ba ni ọrọ ni, ni wọn ba ni bo ba ri bẹẹ, ki awọn tete fa eti awọn, pe bi awọn ko ba ṣe bẹẹ, bi awọn ṣọja to wa lọọọkan yẹn ba fi kofiri awọn, ti wọn si waa ka awọn mọ ibi ti awọn wa, afaimọ ko ma jẹ ọrun ni ẹlomi-in yoo ti pa ina to waa pa.

Godwin ni ta ni yoo waa gbọ ọjọ iku rẹ ti yoo maa rẹrin-in, awọn ko le duro mọ, niṣe lawọn yaa ko ẹru awọn, lawọn ba fere ge e. Ọkunrin yii ni loootọ lo dun awọn pe awọn ko le ṣe iṣẹ ti awọn ti mura lati waa ṣe, ṣugbọn awọn ko sa ni i fẹmi ara awọn di ọrọ tawọn ko mọwọ tawọn ko mẹsẹ, ofin iṣẹ awọn si ti ṣalaye pe, bi awọn ba de ibi kan ti ẹmi awọn ba wa ninu ewu, ki awọn pẹyinda, ki awọn ri i pe ko si oṣiṣẹ panapana kan to ku sibi ina onina. Adajọ Anya paapaa mi kanlẹ, o si da bii pe ọrọ naa ko fẹẹ ye e mọ. Ọga panapana kan ti wa to ni oun de ile Fẹla, ko si si ẹni to di oun lọwọ, koda awọn ṣọja lo tun n gbe oun gun oke, awọn ni wọn si ṣe ọna foun lati kọja dewaju ile Fẹla, bo ba si jẹ awọn to ku ko irinṣẹ wa ni, awọn yoo pana naa. Ṣugbọn awọn ọga mi-in lo tun de ti wọn lawọn ṣọja le awọn danu yii, ta la waa fẹẹ gbagbọ o!

Ọrọ naa ko ti i tan sibẹ paapaa. Awọn ọlọpaa naa ranṣẹ wa, ọga ọlọpaa kan ti wọn si n pe ni Abubakar Tsav lo ṣaaju wọn. Tsav ni oun gangan ni ọlọpaa to wa nidii ẹjọ naa, ọpọlọpọ ẹjọ ti Fẹla ati awọn ọmọ rẹ si n ro niwaju igbimọ, ọkunrin ọlọpaa naa ni irọ ni. O ni fun apẹẹrẹ, ko sẹni kankan to ku ninu awọn ọmọ Fẹla sọsibitu. O ni Sheri ti wọn n sọ yii, iyẹn ti wọn n sọ pe o ku, awọn eeyan ẹ lo waa mu un lati Kwara, bi oun si ti n sọrọ yii, o wa ni Ilọrin, lọdọ awọn to bi i, awọn yẹn si ti sọ pe o wa laaye, ati pe loju ẹmi awọn, ko ni i ba Fẹla ṣere mọ. O ni ki oun too wa si ọdọ wọn, oun ti ba Sheri sọrọ, Sheri si fọkan oun balẹ pe alaafia loun wa, oun ko kan ni i wa si Eko laye oun mọ ni, oun ko si ba Fẹla ṣe ere kankan mọ. O ni ọmọ naa ki i ṣe agbalagba, ko ti i pe ọmọ ọdun mejidinlogun, nitori bẹẹ, awọn obi rẹ laṣẹ lori ẹ, ohun ti wọn ba fẹ lo gbọdọ ṣe.

Tsav ni ko sẹni to na ẹnikan nibẹ gẹgẹ bi iroyin ti oun gbọ, loootọ ni Fẹla ati awọn ọmọ rẹ ṣeṣe, ṣugbọn ki i ṣe pe ẹnikan lo ṣe wọn leṣe bẹẹ, nibi ti wọn ti n sa kaakiri ni wọn ti ṣubu, awọn funra wọn ni wọn n ṣe ara wọn leṣe. Abubakar Tsav ni ko sẹnikan to na wọn paapaa, wọn kan n sọ ohun ti wọn n sọ yii ki ọrọ le dun ni. Nigba naa ni Fẹla fo dide nibi to wa, lo ba bẹrẹ si i bọ ṣokoto rẹ kiakia. Ni Adajọ Anya ba beere pe, “Fẹla, ki lo de, ki lo n ṣe?” Fẹla dahun, “Kin ni mo n ṣe bii ti bawo? Ọlọpaa yii sọ pe ko si ẹni to na ẹnikan, funra wa la ṣe ara wa leṣe, mo si fẹẹ bọ ṣokoto mi ki n le fi oko ati ẹpọn mi han yin, ki ẹ ri ibi ti awọn ọmọ ale yẹn ti fi bileedi ya mi nibẹ, ki ẹ si ri awọn ibi ti wọn ti fi koboko da ara oriṣiiriṣii si idi mi. Nnkan ti mo fẹẹ ṣe niyẹn nao!”

Kiakia lawọn ọmọbinrin Fẹla naa si ti bẹrẹ si i bọ ṣokoto, lawọn oni-sikẹẹti n tu u danu kia, bẹẹ lawọn mi-in ti n fa pata wọn sisalẹ. Adajọ Anya tun ni, “Ki lawọn eleyii naa fẹẹ ṣe!” Ọkan ninu awọn obinrin naa dahun pe awọn fẹẹ fi abẹ awọn han ọga ọlọpaa Tsav ni, ko le ri ibi ti awọn ṣọja ti fi iṣan buruku to wa labẹ wọn fa awọn ni “toto” ya. N ni Adajọ Anya ba tun pariwo, “Ẹ ma ṣe bẹẹ, ẹ ma ṣi kinni yin han wa nibi jare!” Ọga ọlọpaa Tsav sọ pe nigba ti oun n fi ọrọ wa awọn obinrin naa lẹnuwo tẹlẹ, ohun ti wọn sọ naa niyẹn, pe ki oun waa wo “toto” awọn, ti wọn si fẹẹ maa bọ pata, ki oun too sọ fun wọn pe eewọ ni lọdọ tawọn, obinrin ki i deede tu ara rẹ si ihooho bẹẹ, nigba ti ki i ṣe pe ogun de.

Ṣugbọn Fẹla sọrọ, o ni bi Adajọ Anya ko ba ti jẹ ki oun bọ ṣokoto oun, ki oun si fi dogbodogbo abẹ oun han an, ti ko tun jẹ ki awọn ọmọbinrin oun naa ṣi nnkan wọn pẹlẹbẹ fun un, a jẹ pe oun ni ko fẹẹ ri i, ko si kọ ọ siwee pe oun loun ko fẹẹ ri i o, gbogbo ọrọ ti awọn ba si sọ lori bi awọn ṣọja ṣe fiya jẹ awọn lo gbọdọ gbagbọ, lai sọ pe irọ lawọn n pa. Bẹẹ ni Fẹla mura lati ja ara rẹ sihooho niwaju Adajọ, ṣugbọn Adajọ Anya ni oju oun o ni i rọran. Lẹjọ naa ba tun n tẹsiwaju.

(31)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.