Ijọba Ṣọja Awọn aṣofin fẹẹ bẹrẹ oṣelu ni 1977, n lawọn Ọbasanjọ ba binu rangbọndan

Spread the love

Igba kan ti wa ti Naijiria naa ti dara ri. Koda, orilẹ-ede naa dara gan-an ni. Ni asiko ti awọn ọmọ ile-igbimọ aṣoju-ṣofin jokoo, ti wọn n jiroro lori ofin ilẹ wa yii, asiko naa ni awọn Musulumi lọ si orilẹ-ede Mecca, wọn lọ fun Hajj ọdun 1977. Ṣugbọn lọdun naa, kinni kan ṣẹlẹ ni Mẹka yii to jẹ bi wọn ba n sọ ọ leti eeyan lasiko yii, tọhun yoo ro pe ọrọ ti ko le ṣẹlẹ laye yii ni, bẹẹ o ṣẹlẹ. Wọn n ta owo Naijiria niluu Mẹka ni. Awọn kan lọ si Mẹka naa, wọn si dọgbọn lati ko owo Naira lọ sọhun-un, nigba to si di igba kan ti nnkan le, wọn bẹrẹ si i ta owo Naijiria naa ni ilu Saudi. Bi eeyan ba gbọ pe wọn n ta owo Naijiria ni Saudi, bawo lọrọ naa yoo ṣe jẹ, ki lo de ti wọn n ta a, awọn wo ni wọn si n ra owo naa lọwọ wọn. Ohun to ṣẹlẹ ni pe nigba naa, bi owo Naijiria ba wọ Saudi, bii igba ti wọn ko owo Dọla delẹ yii loni-in yii ni.

Bi awọn eeyan yoo ti du owo Dọla nilẹ yii loni-in ni wọn n du owo Naira, ti wọn si n ra owo naa ni banki wọn. Awọn ọmọ Naijiria funra wọn ni wọn ko owo naa lọ, ohun to si fa a ni pe o ni iye ti eeyan le mu dani to ba fẹẹ lọ si Mẹka lati lọọ ṣe Haji, o ni iye Riyal, owo ti wọn n na ni Saudi, ti wọn yoo fun un, wọn yoo si sọ pe ko gbọdọ mu dani ju bẹẹ lọ. Ṣugbọn awọn ọmọ Naijiria kan wa ti iru owo bẹẹ ko to rara, wọn fẹẹ mu owo to pọ dani, nitori pupọ wọn ni wọn fẹẹ ra ọja rẹpẹtẹ bọ lati Saudi yii, awọn mi-in fẹẹ ta ọja ti wọn ba ra yii ni, awọn mi-in si fẹẹ ra awọn goolu olowo nla ti wọn yoo maa lo, owo ti wọn si mu lọ ko to wọn. Eyi ni wọn ṣe maa n fi Naira pamọ sinu ẹru wọn ki wọn le ri ohun na lọhun-un, bo tilẹ jẹ pe eyi naa ko ba ofin mu rara, awọn ara Saudi naa ko fẹ ki eeyan ko owo bẹẹ wọ ilu lai gbe e gba ọna ofin.

Ni ọdun 1977 yii, ninu oṣu kọkanla yii, ogun Naira (N20) ni wọn n ta ni aadọrin Riyal (SR70), bẹẹ ki i ṣe iye to yẹ ki wọn ta a niyẹn, bi wọn ba mu ogun Naira silẹ, ọgọrun-un ati marun-un Riyal lo yẹ ki wọn gba, nitori iye ti wọn n ṣẹ owo naa nigba yẹn niyẹn. Beeyan ba mu Naira kan dani nigba naa, Riyal marun-un o le diẹ ni yoo gba, ṣugbọn itakuta ti awọn ti wọn lọ si Mẹka n ta owo naa jẹ ki awọn oniṣowo owo, paapaa awọn banki, maa jere gọbọi, wọn si n ra owo naa lọwọ wọn. Ọrọ naa di ariwo nigba ti awọn oniroyin Daily Times to lọ si Mẹka lọdun naa gbe e jade pe wọn ta owo Naijiria ni Saudi o. Awọn ijọba Saudi ni awọn yoo mu awọn ti wọn n ta owo naa ati awọn ti wọn n ra a, ṣugbọn wọn ko ri ẹnikẹni mu, nitori awọn banki wa ninu awọn ti wọn n ra a lọwọ awọn eeyan naa, ere gọbọi si lawọn ti wọn n ra Naira yii si n jẹ.

Nigba ti ọrọ naa jade, awọn ti wọn n ṣe apero lori ọrọ ofin ilẹ wa naa pe ara wọn jọ, wọn sọrọ naa bii ere laarin ara wọn  pe awọn gbọdọ mọ ọna ti wọn yoo fi ṣe e ti ko ni i si ẹni ti yoo maa ji owo Naira lati ta sẹyin odi, ti wọn ko si ni i sọ owo naa di eyi ti wọn yoo maa ra kaakiri lai jẹ pe awọn ti wọn n ta a ni banki ni wọn n ṣeto naa. Wọn sọ nijọ naa pe owo Naira ko ni i di yẹyẹ, owo naa yoo si maa lagbara si i ni laarin awọn owo gbogbo ti wọn n na lorilẹ-ede agbaye. Ṣugbọn o wa ninu itan pe igba kan wa ti owo Naira yii ju owo ti wọn n na ni Saudi ati ni ọpọlọpọ awọn ilẹ agbaye mi-in lọ. Awọn aṣoju-ṣofin naa mọ eleyii nibi ipade wọn, wọn si ni ijọba yoowu to ba jẹ gbọdọ ṣe gbogbo eto lati ri i pe owo Naijiria ko ni i fi igba kan lọ silẹ nibikibi, kaka ko lọ silẹ, yoo maa lọ soke si i ni.

Ṣugbọn ni gbogbo igba ti wọn n sọrọ, ti wọn n ronu lori ohun ti yoo ṣẹlẹ si owo Naira yii, nnkan mi-in ti ṣẹlẹ laarin wọn. Ọtọ ni ohun tawọn eeyan ro pe wọn n ṣe ninu ipade ti wọn wa, afi nigba ti ohun ti ọpọ eeyan ko fọkan si ṣẹlẹ laarin wọn. Loju ẹsẹ, ati nibi ipade ti wọn wa yii, ti wọn ko ti i dajọ ti oṣelu yoo bẹrẹ tabi igba ti wọn yoo maa ṣe e, awọn ti wọn wa nibi ipade yii ti pin ara wọn si ọna bii mẹta, awọn ọna ti wọn si pin ara wọn si yii, ẹgbẹ oṣelu ti wọn fẹẹ da silẹ ni. Lojiji lọrọ naa jade sita, ti iroyin si gbe e, pe awọn aṣoju-ṣofin yii ti bẹrẹ ipade laarin ara wọn o, wọn si ti fẹẹ da ẹgbẹ oṣelu tuntun silẹ. Ẹgbẹ oṣelu kẹ, ariwo tawọn eeyan pa niyi, ọrọ naa si ba ijọba ologun funra wọn lojiji nitori ki i ṣe ohun ti wọn ran awọn aṣofin naa lati lọọ ṣe niyẹn. Ta lo wa nidii ẹ, ta lo bẹrẹ ẹ? Iyẹn lawọn eeyan n beere o.

Ohun to ṣẹlẹ ni pe awọn oloṣelu ti mọ pe nibi ti ijọba ologun awọn Ọbasanjọ ba eto wọn de nigba naa, ko le pẹ ti eto oṣelu tuntun yoo fi bẹrẹ, ti ẹgbẹ oriṣiiriṣii yoo maa jade si gbangba. Nitori bẹẹ, ko sẹni kan to fẹẹ duro titi di igba ti ọrọ naa yoo ba oun lojiji, iyẹn lawọn oloṣelu yii ṣe n ba ara wọn sọrọ, ti wọn n jiroro, bi wọn si ti n sọrọ lori ofin Naijiria yii, bẹẹ ni wọn n sọ iru ẹgbẹ ti kaluku yoo lọ fun ara wọn. Ṣe iru ẹyẹ lẹyẹ n wọ tọ, bi o ba fi ọrẹ rẹ han mi, n oo mọ iru eeyan to o jẹ, awọn oloṣelu wọnyi mọ ara wọn, awọn ti iwa wọn si jọ ara wọn fẹẹ bara wọn ṣe. Ṣugbọn ofin wa, ijọba ti sọ pe awọn ko ti i gbẹsẹ kuro lori ofin to de oṣelu ṣiṣe, nitori bẹẹ ni ko ṣe si ẹnikan to gbọdọ da ẹgbẹ silẹ tabi ko awọn eeyan jọ lati maa ṣe oṣelu, ẹni to ba ṣe bẹẹ ti ọwọ awọn ba tẹ ẹ, oluwa-rẹ yoo fẹnu fẹra bii abẹbẹ, nitori awọn yoo ba a fa a gidigidi.

Ohun to ti n ka awọn oloṣelu yii lọwọ ko lati ọjọ yii wa niyẹn. Amọ nigba ti wọn pade nibi igbimọ aṣoju-ṣofin to fẹẹ jiroro lori ofin tuntun fun Naijiria yii, kia ni wọn bẹrẹ si i rin sun mọ ara wọn, kaluku si n wọ inu ẹgbẹ ti yoo wọ lọ. Ṣe gbogbo awọn ti wọn wa ninu igbimọ lọjọ naa, ọpọlọpọ wọn lo ti di ipo oṣelu mu daadaa. Awọn ti wọn ti ṣe minisita laye ijọba awọn oloṣelu to lọ, bii Shehu Shagari, Mitam Yusuf, Olu Awotesu, atawọn mi-in ti wọn jẹ ọmọ awọn ẹgbẹ oṣelu atijọ ni wọn wa nibẹ periperi. Awọn ọmọ Sardauna Ahmadu Bello pọ ninu ipade yii daadaa, awọn ọmọlẹyin Ọbafẹmi Awolọwọ wa ninu wọn, bẹẹ si ni awọn ti Nnamdi Azikiwe, kaluku wọn lo ti gbe ẹwu oṣelu wọn ti wọn ti bọ ju sibi kan lati ọjọ yii wọ, wọn fẹẹ bẹrẹ ohun ti wọn ṣe ku lọjọsi lakọtun. Nibi igbimọ aṣoju-ṣofin yii ni wọn si ti fẹẹ bẹrẹ.

Awọn ọga wọn ti fi ọrọ powe ranṣẹ si wọn, awọn naa si ti mọ itumọ awọn ohun ti wọn sọ. Awolọwọ ti sọrọ si gbangba, ọrọ rẹ si ni awọn ọmọlẹyin rẹ di mu, ohun to sọ ti ye wọn. Awọn oniroyin ni wọn beere lọwọ ẹ nigba to ku diẹ ki ijokoo awọn eeyan naa bẹrẹ, wọn ni ṣe yoo da si ọrọ oṣelu lasiko ibo to n bọ abi yoo fi kinni naa silẹ fawọn mi-in ni. Baba naa ko fi ọrọ si abẹ ahọn sọ to fi da wọn lohun pe iku ni i gba aṣọ lara ewurẹ, bi oun ba ṣi wa laye ti oun n mi, oun ko ni i fi oṣelu ṣiṣe silẹ, nitori oun yoowu to ba ti jẹ iṣẹ ti yoo ran gbogbo ilu lọwọ, ti yoo si yọ mẹkunnu kuro ninu inira ti yoo gbe wọn sinu idẹra, lara iṣẹ ti Ọlọrun fi ran oun niyẹn, oun si mọ pe ko si ibomiiran ti oun ti le ṣe iṣẹ naa ju idi oṣelu lọ. Nitori bẹẹ, bi wọn ba ti ni oṣelu ya, oun yoo gbe ẹwu oun wọ, awọn jọ n lọ ni.

Nitori pe Nnamdi Azikiwe ti wọn jọ ṣejọba nigba awọn oloṣelu akọkọ ti sọ nigba kan ri pe oun ko ba wọn ṣe oṣelu Naijiria mọ o, oun ko raaye ẹ, oun ko si tun fẹ wahala kan funra oun, awọn oniroyin tun wa oun naa lọ, wọn si bi i leere pe pẹlu ọrọ to ti sọ sẹyin tẹlẹ pe oun ko ṣe oṣelu mọ, ti kinni naa si ti tun n pada bọ bayii, ṣe bo ti wi naa ni yoo ri ni abi yoo pada sẹyin nidii ohun to ti sọ. Azikiwe, oloṣelu eletekete, bo ba n lọ si irin-ajo, to ti wẹwu, to si gbe baagi rẹ bayii, yoo sọ fawọn to ba yi i ka pe oun ko ti i mọ bi oun yoo lọ tabi oun ko lọ ni. Ohun to si sọ naa niyẹn. O ni ki awọn oniroyin ma ṣe wahala jinna, oun ṣi n ronu lọwọ, oun ko ti i mọ ibi ti oun yoo ya si nidii ọrọ naa, ṣugbọn o  da oun loju pe nibikibi ti ironu oun ba yọri si, gbogbo wọn ni wọn yoo mọ laipẹ jọjọ.

Eyi ni pe bi awọn ọmọlẹyin Sardauna ti n mura lati kopa ninu eto oṣelu awọn Ọbasanjọ ni 1979, bẹẹ lawọn ọmọlẹyin Awolọwọ naa n mura, ti awọn ti wọn jẹ ọmọ Azikiwe naa ko si kawọ gbera, awọn naa n ba ara wọn sọrọ, wọn si n ṣepade loriṣiiriṣii. Ohun to waa ṣẹlẹ ni pe gbogbo wọn pata yii, ninu igbimọ aṣoju-ṣofin to n jiroro lori ofin oṣelu tuntun fun Naijiria yii ni wọn wa, lojoojumọ ni wọn n rira, kaluku wọn si n gbọ ohun ti ẹni keji wọn n ṣe. Awọn kan naa wa nibẹ ti awọn naa n ṣeto oṣelu tiwọn, awọn ọdọ ni awọn yii pe ara wọn, iyẹn awọn ti wọn ko ti i ṣe oṣelu kankan ri, to jẹ wọn ṣẹṣẹ n bọ ni. Awọn bii Oluṣọla Saraki, MKO Abiọla, Umaru Dikko atawọn mi-in bẹẹ bẹẹ. Awọn yii kere, tabi ko jẹ wọn ko kopa, tabi ko jẹ ipa ti wọn ko ko to nnkan nigba oṣelu 1952 titi di 1966, wọn si ro pe asiko tiwọn naa ree.

Bayii lo ṣe pe ko pẹ rara ti igbimọ yii bẹrẹ ijokoo ti wọn ti pin si bii ọna mẹrin, awọn oloṣelu atijọ ti pin si mẹta, awọn oloṣelu tuntun si wa lọna kan, wọn n jijadu kinni naa laarin ara wọn. Ko ma waa di pe awọn kan yoo ṣaaju awọn mi-in lo jẹ ki kaluku maa ko ẹgbẹ tirẹ jọ ni kọrọ. Lojiji ni ọkan ninu awọn ẹgbẹ ti wọn ṣepade ni kọrọ yii gbe iwe jade, wọn ni ki awọn ti wọn ba fẹẹ darapọ mọ wọn maa kọ orukọ wọn silẹ ati adirẹsi, ati tẹlifoonu, ati ibi ti wọn ti le ri wọn. Wọn ko pe ẹgbẹ naa ni ẹgbẹ oṣelu, wọn pe e ni National Union Council, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kọkanla, 1977, ni wọn si gbe orukọ ẹgbẹ wọn yii jade. N lawọn eeyan ba bẹrẹ si i rọ wọ inu rẹ, ẹni to ba si ti mọ bi kinni naa ṣe n lọ, yoo ti mọ pe ẹgbẹ oṣelu lati ilẹ Hausa ti wọn kan n wa awọn eeyan kunra lati ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo ni. Kia lawọn eeyan si bẹrẹ si i forukọ silẹ.

Nigba ti ilẹ ọjọ naa yoo fi ṣu, orukọ rẹpẹtẹ lo ti wa ninu ẹgbẹ tuntun yii, awọn bii Abubakar Rimi, Yaya Gussau, Adamu Ciroma, Umaru Dikko, Ali Monguno, Waziri Ibrahim, George Kurubo, Pius Okigbo, Solomon Lar, Jerome Udoji, Alhaji Shehu Shagari, Sule Takuma, Sọla Saraki, Muhammadu Goni, Shehu Malami, ***Toyhe Coker, Lawal Kaita, John Wash, Alaaji Umaru Baba, Alhaji Hassan Gafal, atawọn mi-in bẹẹ bẹẹ lọ. Gbogbo wọn lo ti fi orukọ ara wọn silẹ, wọn si ti gba pe awọn yoo jọ maa ba ara awọn ṣe, awọn yoo maa ṣe ẹgbẹ naa ki awọn le fi wa ilọsiwaju Naijiria, ki awọn si le da si eto ijiroro lori ofin Naijiria ti awọn wa sibẹ yẹn waa ṣe. Wọn o sọ pe oṣelu lawọn tori ẹ da ẹgbẹ naa silẹ o, wọn ni ijiroro lasan ni, ki awọn kan jọ maa fi ikunlukun lori ọna ti iṣọkan yoo fi wa ni Naijiria ni.

Ṣugbọn awọn oloṣelu ẹlẹgbẹ wọn ti wọn ko si ninu ẹgbẹ tuntun ti wọn n ko jọ yii mọ pe irọ ni wọn n pa, o si jọ pe awọn ni wọn ta ijọba ologun lolobo pe awọn kan ti fẹẹ da ẹgbẹ oṣelu silẹ nibi ipade apero ti awọn wa yii o. N ni ijọba ba sare jade pe “ka ma ri i”, ki gbogbo awọn ti wọn ba lọwọ si palapala bẹẹ tete jawọ o, bi wọn ko ba jawọ, nnkan yoo le fun wọn o. N lawọn oloṣelu yii ba sa pada sẹyin, ni kaluku ba n sọ pe awọn ko mọ, awọn to kọ orukọ awọn kan fẹẹ ko ba awọn lasan ni, wọn ni ko sẹni to sọ fawọn pe ẹgbẹ oṣelu ni wọn fẹẹ da silẹ, ẹlomi-in si ni oun ko tilẹ mọ awọn ti wọn kọ orukọ oun si i, ati pe oun ko ṣetan lati ṣe oṣelu rara, ijiroro lasan ni wọn ni ki awọn waa ṣe, awọn ko si mọ bi awọn kan yoo ṣe sọ ipade naa di ti awọn oloṣelu, wọn ni iwa ika, iwa arekereke ni awọn ti wọn wa nidii eto naa ṣe, wọn kan fẹẹ lo orukọ awọn lasan ni.

Lọrọ kan, ko sẹni to mọ awọn ti wọn fi orukọ wọn silẹ, ẹni to fi orukọ wọn silẹ, ati bi wọn ti pade lati darukọ ẹgbẹ tuntun naa. Awọn eeyan naa taku, wọn ni awọn ko mọ kinni kan ninu ohun ti awọn eeyan n sọ, wọn si ni awọn kan ti awọn ko fẹẹ darukọ lo wa nidii ọrọ naa, ati irọ buruku ti wọn pa mọ awọn. Awọn ọmọlẹyin Awolọwọ ni wọn n pa owe mọ yẹn, nitori ninu gbogbo orukọ ti wọn da, ati awọn ti wọn ni awọn fẹẹ da ẹgbẹ National Union Council yii silẹ, ko si awọn ọmọlẹyin Awolọwọ ninu wọn, afi awọn ti wọn ba fi orukọ wọn sibẹ nigba ti wọn ko si nitosi. Orukọ awọn ti wọn wa nibẹ, awọn ti wọn ti ṣe Ẹgbẹ Dẹmọ ri, tabi ti wọn ti ba NCNC ṣe, tabi ti wọn jẹ ẹni to ba Sardauna ṣiṣẹ ni gbogbo wọn, ko si orukọ awọn ọmọlẹyin Awolọwọ nibẹ, bẹẹ awọn naa wa nipade naa, wọn ko kan pe wọn si ẹgbẹ tuntun yii ni.

Ki i ṣe pe awọn ọmọlẹyin Awolọwọ naa ki i ṣe ipade tiwọn, ko kan sẹni to mọ ibi ti wọn ti n ṣe e, tabi ẹni to ka wọn mọbẹ ni. Awọn ọmọ ti Sardauna ni wọn ti ro pe ko si ibi ti awọn ko ti le ṣe oṣelu, wọn si tun fẹẹ ṣaaju awọn to ku jade, ki wọn le ti rin jinna ki awọn ẹgbẹ oṣelu to ku too maa yọju sita. Igba ti awo ọrọ naa si lu jade ni wọn bẹrẹ si i purọ pe awọn ko mọ kinni kan nipa rẹ, ṣugbọn nigba ti oṣelu bẹrẹ loju mejeeji, gbogbo awọn orukọ to wa nibẹ ni wọn di ọmọ ẹgbẹ NPN, awọn kọọkan lo kan kuro nibẹ ti wọn ba ẹgbẹ GNPP lọ. Ṣugbọn bii awọn ọgọrin ninu awọn ọgọrun-un ti orukọ wọn jade lọjọ akọkọ yii, awọn ti wọn pada waa di ọmọ ẹgbẹ NPN, awọn ti wọn ko si ba wọn da si i, ti wọn jẹ ọmọlẹyin Awolọwọ, awọn naa ni wọn pada waa di ọmọ ẹgbẹ UPN.

Lọrọ kan, nibi ipade apero ofin ilẹ wa ti wọn ṣe ni 1977 si 1978 yii ni awọn oloṣelu ti bẹrẹ eto tuntun, ti wọn si ti mọ ẹgbẹ ti wọn yoo da silẹ, ati awọn ti wọn yoo di ọmọ ẹgbẹ wọn. Nibẹ naa ni wọn ti pin ara wọn si mẹta, awọn Ibo ti mọ pe awọn n ba Azikiwe lọ, afi ti ko ba jade, awọn Hausa ti mọ pe ẹgbẹ yoowu tawọn ọmọ Sardauna ba wa lawọn yoo ṣe, awọn Yoruba si ti mọ pe ọmọlẹyin Awolọwọ lawọn n ṣe, awọn ko si ni i wọ inu ẹgbẹ mi-in laelae.

 

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.