Ijọba Ajimọbi ko naani eto ẹkọ rara Borno gan-an ti ipenija eto aabo wa n ṣe daadaa ju wa lọ- Sharafadeen Alli

Spread the love

Ninu awọn bii ogun ti wọn n dupo gomina ipinlẹ Ọyọ ninu idibo ti yoo waye ninu oṣu kẹta, ọdun yii, marun-un pere lo laamilaaka ninu wọn. Ọkan ninu wọn si ni Amofin Sharafadeen Abiọdun Alli to n dupo naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party (ZLP). Ṣugbọn lati inu oṣu kẹsan-an, ọdun 2017, ni wọn iba ti yinbọn pa a nitori eto idibo ọdun 2019 yii. Ọkunrin to ti ṣe alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ibadan, akọwe ijọba ati olori awọn oṣiṣẹ gomina ipinlẹ Ọyọ ri lasiko ọtọọtọ ri yii ti ṣalaye idi ti awọn tọọgi oṣelu ṣe fẹẹ pa a atawọn ipinnu ẹ lati mu idagbasoke ba ipinlẹ Ọyọ ati ilẹ Yoruba lapapọ. Eyi ni ifọrọwerọ ẹ pẹlu akọroyin wa:

 

ALAROYE: Pẹlu bi Aminat Zakari ti wọn ni yoo moju to eto ibo kika fun ajọ INEC ṣe jẹ ibatan Aarẹ Muhammadu Burari, njẹ ẹ nigbagbọ pe ajọ INEC yoo le ṣeto idibo ti ko ni i ni ojooro ninu?

 

Sharafadeen Alli: Ko si nnkan to buru ninu ki Aminat Zakari jẹ ibatan Aarẹ, ṣugbọn eyi ti ko daa nibẹ ni bo ṣe n sọ pe oun ki i ṣe ibatan Aarẹ. O tumọ si pe oun gan-an ti mọ lọkan ara ẹ pe oun fẹẹ ṣe magomago. To ba jẹwọ pe ibatan oun l’Aarẹ, aye aa mọ pe ootọ inu lo fẹẹ fi ṣe ohun to fẹẹ ṣe. Loootọ, ki i ṣe pe o ṣẹṣẹ wa ninu ajọ INEC, ṣugbọn ko ti i rẹsẹ walẹ to bayii ninu awọn idibo to ṣaaju. Ṣugbọn nigba tawọn eeyan n pariwo pe ko ỵẹ ki Buhari fi i sibẹ, o sọ pe oun ko ba Aarẹ tan. Eyi ko daa. Ko si yẹ ki wọn jẹ ko ṣe e, nitori atubọtan ẹ ko le daa fun ọjọ iwaju Naijiria.

 

ALAROYE: Ki lẹ ri si bi ijọba apapọ ṣe n gbero lati ṣafikun saa ọga agba ọlọpaa lorileede yii, Ibrahim Idris to ti yẹ ko fẹyinti?

Sharafadeen Alli: Oun kọ lẹni akọkọ ti wọn aa fi kun asiko ẹ lẹnu iṣẹ ọlọpaa. Ṣugbọn ohun to yẹ ka beere ni pe ṣe o ṣiṣẹ rẹ bii iṣẹ debi ti inu awọn araalu maa dun ti ijọba ba ṣafikun asiko ẹ? Njẹ awọn ibi ti Aarẹ ni ko lọ, njẹ o lọ. Awọn ibi ti laasigbo ti wa, njẹ o mojuto o daadaa bi? Gbogbo eyi lo yẹ ki ijọba gbeyẹwo ki wọn too le mọ boya o lẹtọọ si afikun iṣẹ.

 

ALAROYE: A gbọ pe nigba tẹ ẹ jẹ alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ibadan, awọn nnkan kan jẹ ipenija fun yin lati ṣaṣeyọri. Njẹ ẹ le ṣalaye awọn ipenija yẹn?

Sharafadeen Alli: Tẹ ẹ ba lọọ beere lọwọ awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ yẹn, wọn aa ṣalaye pe awọn gbadun ijọba mi daadaa. Lọdun 1991 si 1992, mo gba ami-ẹyẹ gẹgẹ bii alaga ijọba ibilẹ to daa ju nipinlẹ Ọyọ. Awa la kọkọ maa sanwo-oṣu ati owo ajẹmọnu. Lọdun 1992, ijọba apapọ ṣafikun owo-oṣu awọn oṣiṣẹ lai si ẹkunwo fun owo awọn ijọba ibilẹ. Wọn si ti gbe bukaata eto ẹkọ le wa lọrun. Lẹyin igba ti awa kuro nijọba lọdun 1993, wahala yẹn si tun wa nibẹ. Awọn olukọ gan-an si mọ ohun to n ṣẹlẹ nigba ijọba wa. Nigba to waa di ọdun 2000 ni wọn too waa gba imọran wa pe ka kọkọ maa yọ owo awọn olukọ kuro ninu owo to ba n lọ sapo ijọba ibilẹ na.

 

ALAROYE: Pẹlu bo ṣe jẹ pe idibo ku oṣu mẹta lẹ dara pọ mọ ẹgbẹ ZLP to fa yin kalẹ lati dupo yii, ṣe asiko naa ko kere ju, ṣe ko si ni i ṣakoba fun yin?

 

Sharafadeen Alli: Asiko ko kere ju, ki awọn eeyan nigbagbọ ninu awọn to n dupo lo ṣe pataki. Idibo to n bọ yii, mo fẹẹ rọ awọn eeyan lati ma ṣe wo ẹgbẹ nikan, ki wọn tun wo iru eeyan ti ẹgbẹ oṣelu kọọkan fa kalẹ. Ero to pọ ju to maa dibo, araalu ni, ki i ṣe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu lo maa dibo. Eeyan lo n ṣe ẹgbẹ, ki i ṣe ẹgbẹ lo n ṣe eeyan. Lagbara Ọlọrun, awa la maa jawe olubori.

 

ALAROYE: Lẹyin idibo ọdun 2015, ẹgbẹ ZLP tẹ ẹ wa yii lẹgbẹ kẹta tẹ ẹ maa ṣe, kin lo n le yin kiri?

Sharafadeen Alli: Iwa ta-ni-yoo-mu mi ati aibọwọ fun ẹtọ ọmọniyan lo le wa kuro inu ẹgbẹ PDP. A dibo yan awọn oloye ẹgbẹ. Awọn wọnyi ni wọn dibo yan awọn adari apapọ ẹgbẹ. Awọn adari apapọ ẹgbẹ waa wo o pe awọn to dibo yan awọn ko lẹtọọ lati wa nipo adari ẹgbẹ ni ipinlẹ wọn, eyi tumọ si pe idibo to gbe awọn paapaa wọle ko tọna. A si gbiyanju lati ri i pe wọn ṣatunṣe si eyi, ṣugbọn ko ṣe e ṣe. Ba a ṣe n wi yii, awọn ẹgbẹ PDP ti gbe ara wọn lọ si kootu lori ọrọ oludije fun ipo gomina, wọn tun wa ni kootu lọwọlọwọ fun ipo oludije fun ipo sẹnetọ. Iru awọn aiṣedeede bayii lo le wa kuro ninu ẹgbẹ PDP. Ni ti ẹgbẹ ADC, nigba ta a bẹrẹ, ko si ẹni to sọ fun wa pe a kan maa fa awọn eeyan kalẹ lati dupo lai dibo ni. Nigba taa debẹ ni wọn sọ fun wa pe awọn to ti wa nipo aṣoju-ṣofin ati aṣofin ipinle tẹlẹ ninu ẹgbẹ yẹn naa la tun maa fa kalẹ.

Yatọ si iyẹn, nigba ti ẹgbẹ ti pinnu lori ẹni ti wọn fẹẹ fa kalẹ gẹgẹ bii oludije, ki lo de ti wọn tun n ta fọọmu fawọn eeyan lati tun maa dije ni iru ẹkun idibo bẹẹ. Nigba ta a fẹẹ ṣeto idibo abẹle lati fa oludije fun ipo gomina kalẹ, a ko tẹle ọna mẹtẹẹta ti ẹgbẹ oṣelu le lo lati fa oludije kalẹ. Nigba to tasiko lati yan oludije fun ipo gomina, ọna mẹta lo wa lati yan oludije ṣugbọn a ko tẹle ilana kankan nibẹ. Lọjọ Sannde to jẹ gbedeke ọjọ ti ajọ INEC fi silẹ fun gbogbo ẹgbẹ oṣelu lati fi orukọ oludije fun ipo gomina wọn ranṣẹ, nigba ti imọ wa ko ṣọkan lori ẹni ti ẹgbẹ wa maa fa kalẹ, lati dupo gomina, a fi Dele Ajadi sibẹ na. Awa mẹtẹẹtala ta a jọ n dupo yẹn wa jọ fọwọ siwee adehun pe ta a ba maa yi igbesẹ ta a ti gbe yii pada, gbogbo wa la gbọdọ jọ mọ si i. Ṣugbọn ọjọ karun-un lẹyin ẹ la gbọ pe wọn ti fi orukọ ẹnikan si i lai jẹ ki gbogbo wa mọ̀ mọ́.

Lọna keji, awọn kan gba pe nitori pe awọn ṣi wa nipo, gbogbo ipo lo gbọdọ bọ si awọn lọwọ. Iyẹn lo fa a ti gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ZLP to wa nijọba ibilẹ Itẹsiwaju fi binu kuro ninu ẹgbẹ ADC, to fi jẹ pe ẹgbẹ ZLP ni gbogbo wọn n ṣe bayii.

 

ALAROYE: A gbọ pe ẹyin ati Lanlẹhin pade nile Agba-oye Rashidi Ladọja, wọn si bẹ Lanlẹhin lati fi gomina didu silẹ fun yin. Ṣe loootọ ni?

Sharafadeen Alli: Ko si ootọ kankan nibẹ. Ki i ṣe ẹnikan lo pe wa fun ipade nibẹ, a kan pade nibẹ lọjọ yẹn ni. Nitori nigba yẹn, emi ti kuro ninu ẹgbẹ ADC, mo ti lọ sinu ZLP. Sẹnetọ Ladọja gan-an iba ti wa ninu ẹgbẹ ZLP nigba yẹn, ṣugbọn awọn eeyan n bẹ wọn nigba naa pe ki wọn ma fi ẹgbẹ ADC silẹ. Mo waa wa l’Ekoo lọjọ yẹn, mo waa ni ki n lọọ ri baba wa Ladọja. Ọjọ kejila, oṣu kejila, ni. Bi mo ṣe de ile wọn l’Ekoo ni mo ba Sẹnetọ Lanlẹhin nibẹ. Gẹgẹ bii tẹgbọn-taburo, a kira wa, a si jọ sọrọ oṣelu. Nigba to di asiko ounjẹ, a jọ jẹun ọsan nibẹ. Nigba ti Agba-oye Ladọja de, mo sọ fun Sẹnetọ Lanlẹhin pe ki wọn ṣe gaafara fun mi diẹ ki n fi ba baba sọrọ, ki i ṣe pe a jọ ṣepade kankan lọjọ yẹn.

 

ALAROYE: Ta a ba ni ka da a sil ka tun un ṣa, meloo ninu yin lẹ ro pe o to gbangba a sun lọyẹ ninu eyin oludije?

Sharafadeen Alli: Ọtunba Akala ti sọ fun ẹyin oniroyin pe emi atawọn la kunju oṣunwọn ju ninu gbogbo awa ta a jọ n dupo gomina. A ti jọ ṣe alaga ijọba ibilẹ ri, a si jọ mọ tifun-tẹdọ bi wọn ṣe n ṣe ijọba ipinlẹ Ọyọ. Ọtunba Akala ti ni iriri ipo gomina ri ni tiwọn, ṣugbọn nnkan kan ti emi fi kun temi ni pe yatọ si pe mo ti ṣe akọwe ijọba ipinlẹ Ọyọ ati olori awọn oṣiṣẹ ti wọn yan sipo ijọba ijọba ipinlẹ yii sẹyin, mo tun ni iriri nipa eto ọrọ aje nitori mo ti ṣe alaga ileeṣẹ okoowo O’dua ri. Lode oni, ijọba o le da nnkan kan ṣe, a ni lati fọwọ sowọ pẹlu awọn ileesẹ aladaani. Ki i ṣe pe ki awọn gomina kan maa fowo ijọba gun baalu kiri gẹgẹ bi ọpọlọpọ wọn ṣe maa n ṣe. Gẹgẹ bii alakooso ileeṣẹ okoowo to jẹ ti apapọ gbogbo ilẹ Yoruba pata, mo ti ni ajọṣepọ pẹlu awọn ileeṣẹ okoowo kaakiri agbaye to le ran mi lọwọ lati mu idagbasoke ba ipinlẹ Ọyọ.

 

ALAROYE: Gẹgẹ bii iriri yin nipo akoso ileeṣẹ to jẹ ti gbogbo ijọba ilẹ Yoruba, ki lẹ ro pe o n ṣe idiwọ fawọn ijọba wa lati ṣaṣepọ ti yoo tete mu idagbasoke wọ ilẹ Yoruba?

Sharafadeen Alli: Ọrọ oṣelu lo n fa a. Awọn gomina aa maa wo o pe ẹgbẹ oṣelu awọn ko papọ. Mo ranti igba ta a fẹ ṣe ọkọ oju irin kaakiri ilẹ Yoruba, ọkan ninu awọn gomina ilẹ Yoruba nigba naa lo gbe ọrọ yẹn kari ju, awọn yooku wa n wo o pe o ṣe jẹ iwọ lo maa wa awọn oṣiṣẹ ti yoo ṣiṣẹ, iwọ nikan lo maa ṣe ọpọlọpọ nnkan ti gbogbo wa jọ maa jẹ gbese le lori. Iyẹn kọkọ mu ifasẹyin ba iṣẹ yẹn lati ibẹrẹ. Ohun ti mo fẹẹ sọ yii yoo pa yin lẹrin-in. O ni iye owo ti awa O’dua ta a ni eto yẹn gbero lati na lori iṣẹ yẹn, ṣugbọn nigba ti awọn gomina yoo gbe àbá iye owo ti wọn fẹ ka na de ni tiwọn, o to ilọpo mẹta owo ti awa Odua ti ṣadehun pẹlu ileeṣẹ yẹn. Bẹẹ to ba si jẹ pe a ṣiṣẹ yẹn nigba yẹn ni, ọna ọkọ oju irin yẹn iba ti kọja Oṣogbo bayii, nitori ero wa ni pe lati Ibadan, a maa ṣe e lọ si Ṣaki. A si maa ṣe e lati Oṣogbo lọ si Akurẹ. A maa waa ra awọn ọkọ rẹpẹtẹ ti yoo maa ko awọn ẹru ti ọkọ oju irin ba ko lọ si inu ilu kaakiri. Emi ti mo ti mọ iṣoro ta a ni, mo mọ ọna ti mo le gba yanju ẹ. A maa ni ajumọṣe pẹlu awọn ileeṣẹ okoowo nla nla lagbaaye. A ko si ni i faaye gba ki ẹnikan jokoo sibi kan ko maa jẹ gaba le awa yooku lori. Awa gomina maa ba ara wa sọrọ, ti Ọlọrun ba le jẹ ka gbọra wa ye, ilọsiwaju maa wa.

 

ALAROYE: Awọn ipinnu wo lẹ ni fawọn ara ipinlẹ Ọyọ bẹẹ ba depo gomina?

Sharafadeen Alli: A n gbero eto ẹkọ to ye kooro. Eyi ṣe pataki pupọ nitori nnkan ko lọ deede lori eto ẹkọ. Ọna meji la fi le mọ boya ijọba n ṣe daadaa lori eto ẹkọ. Bi ijọba ṣe ya owo sọtọ fun eto ẹkọ to ninu bọjẹẹti lọdọọdun ati ipo awọn akẹkọọ ninu idanwo. Ajọ UNESCO gba gbogbo aye nimọran lati ya ida ogun si mẹẹẹdọgbọn sọtọ sinu eto ẹkọ, ṣugbọn ida ti ijọba Ọyọ n na lori eto ẹkọ ko to ida meji. Bakan naa, ipo kẹrindinlọgbọn (26), la n ṣe ninu idanwo, to si jẹ pe tẹlẹtẹ, ipo kin-in-ni si ikarun-un la maa n ṣe.  Idi niyẹn ti wọn ṣe n pe wa ni aji-ṣe-bii-Ọyọ la a ri, Ọyọ ki i ṣe bii baba ẹnikan. Kayeefi ni yoo waa jẹ fun yin lati gbọ pe Borno gan-an ti ipenija eto aabo wa n ṣe daadaa ju wa lọ. Ijọba yii ko naani eto ẹkọ rara. Aṣunwọn kan wa ti ijọba ipinlẹ ti maa n gbowo lọwọ ijọba apapọ lati na lori eto ẹkọ, ṣugbọn ki ijọba ipinlẹ kan too le gbowo yẹn, oun naa gbọdọ ni owo diẹ ninu aṣunwọn yẹn. Ṣugbọn ọdun mejila sẹyin ni ijọba ipinlẹ Ọyọ ti lọọ gbowo yẹn gbẹyin. Eyi tumọ si pe awọn ijọba to jẹ lati asiko naa ko ka eto ẹkọ si. Lori eto ilera, a maa ṣeto ileewosan alabọọde kọọkan si wọọdu kọọkan kaakiri ipinlẹ Ọyọ lati jẹ ki eto ilera sun mọ awọn eeyan. Ta a ba n wa idagbasoke ipinlẹ Ọyọ, Oke-Ogun lo ti maa bẹrẹ, nitori pe ibẹ lounjẹ ta a n jẹ ni ipinlẹ Ọyọ ti wa, yatọ si awọn eso to n wa lati Ọyọ ati Ogbomọṣọ. A maa ṣeto ilana ti a oo maa fi ṣe awọn ire oko lọjọ. Ni gbogbo ibi ta a mọ lagbaaye, olowo lagbẹ, ṣugbọn awọn agbẹ niya n jẹ ju ni Naijiria. Ko yẹ ko jẹ pe ilẹ Hausa ni wọn a ti maa ko tomaati wa si ipinlẹ Ọyọ tabi ibikibi nilẹ Yoruba. Ọrọ awọn oṣiṣẹ ṣe pataki. Ọjo kẹẹẹdọgbọn la oo maa sanwo oṣu awọn oṣiṣẹ. Ti ọdun ba si ti pari, a o maa sanwo oṣu kan fun wọn gẹgẹ bii owo oṣu kẹtala. A o maa ṣeto idanilẹkọọ fun awọn oṣiṣẹ, yala nilẹ yii tabi loke okun nitori pe eeyan ki i mọ nnkan tan. A o si maa sanwo oṣu awọn oṣiṣẹ-fẹyinti.

 

ALAROYE: Awọn janduku kan dihamọra pẹlu ibọn waa ka yin mọ aafin lọjọ ti Olubadan fi yin joye, nibo ni iwadii de duro lori iṣẹlẹ yẹn?

Sharafadeen Alli: A mọ pe awọn eeyan kan ni wọn wa nidii ẹ, ṣugbọn mi o le ri wọn daadaa lọjọ yẹn. Ṣugbọn awọn to ri wọn daadaa ri wọn. Nigba ti awọn ọlọpaa tun mu awọn eeyan yẹn, awọn kan lo pe wọn pe ki wọn fi wọn silẹ, Ọlọrun si ju gbogbo wọn lọ.

 

ALAROYE: Ọna wo lẹ fẹẹ gba lo iriri yin ninu iṣejọba lati ṣakoso ipinlẹ yii bawọn araalu ba dibo yan yin sipo gomina?

Sharafadeen Alli: Mi o le sọ pe mo mọ gbogbo ẹ tan, ṣugbọn mo mọ ọpọlọpọ ninu gbogbo bi wọn ṣe n ṣe ijọba. Inu mi dun pe nigba ti awọn eeyan n bi Sẹnetọ Ladọja leere pe ta ni wọn maa mu ninu emi ati Sẹnetọ Lanlẹhin, esi ti wọn maa n fọ ni pe Sarafa lo mọṣẹ. Ti awọn ba gba maaki mẹwaa ninu iṣejọba awọn, o yẹ ki n le gba mẹta ninu ẹ. Wọn lemi lawọn jọ ṣiṣẹ, emi ni mo le bẹrẹ nibi tawọn ṣe e de. Ta a ba si wo iṣejọba to tun daa ju lẹyin iku Bọla Ige, ijọba Ladọja ni.

 

 

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.