Ijiya wa fun orileede yii lọdun 2019- Primate Samson Alabi Ọjọawo (Ijọ United African Baptist Church, Isalẹ Oke-Oge, niluu Saki nipinlẹ Ọyọ

Spread the love

Ayaafi ki awọn alagbara ninu adura lorileede yii fọwọ sowọ pọ lati gbadura pẹlu aawẹ, bi bẹẹ kọ, ijiya to lagbara yoo ba tọmọde tagba lorileede yii lọdun 2019.

 

Eto idibo ọdun yii ko ni i la wahala lọ bi ọpọ eeyan ṣe ro.

 

Ko ni i pẹ lẹyin ta a ba dibo ọdun yii tan ni wahala yoo ṣẹlẹ nitori eto ọrọ aje orileede yii ti ko fara rọ.

 

Lọdun 2016 ni mo sọ asọtẹlẹ pe ebi yoo pọ laarin ilu, o si wa si imuṣẹ, ṣugbọn lọtẹ yii, ounjẹ yoo pọ, ṣugbọn ko ni i si owo lati fi ra a.

 

A ni lati mura si adura ati aawẹ gidigidi ki Ọlọrun le mu wa rekọja awọn ipenija wọnyi.

 

 

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.