Ijinigbe: Ẹgbẹyẹmi ṣeleri eto aabo fawọn eeyan Ekiti *Bẹẹ lawọn ọlọpaa ya bo oju popo

Spread the love

Latari bi ibẹru awọn ajinigbe ṣe gba ọkan araalu, Igbakeji Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọtunba Bisi Ẹgbẹyẹmi, ti ṣeleri eto aabo to peye fawọn eeyan ipinlẹ naa.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja lo sọrọ naa fawọn oniroyin lasiko to n sọrọ lori awọn eto tijọba fẹẹ gbaju mọ lasiko opin ọdun ati ibẹrẹ ọdun to n bọ.

Ẹgbẹyẹmi ni eto aabo yoo gba ọna mi-in yọ nitori ijọba fẹẹ gbena woju awọn to n fi ijinigbe da awọn eeyan laamu, bẹẹ lo rọ awọn ṣọja ati ọlọpaa ti wọn ti n ṣeto aabo ipinlẹ naa lati ma ṣaarẹ.

Bakan naa nileeṣẹ ọlọpaa ti ṣeleri eto aabo to peye lasiko ati lẹyin ọdun fawọn eeyan Ekiti.

DSP Caleb Ikechucwu to gba ẹnu kọmiṣanna ọlọpaa, CP Ahmed Bello, sọrọ sọ ọ di mimọ pe awọn ọlọpaa adigboluja, ẹka eto aabo titi marosẹ atawọn to n gbogun ti iwa ọdaran ni yoo wa lawọn oju popo kaakiri lati asiko yii.

O waa rọ awọn eeyan lati fọwọ sowọ pọ pẹlu ileeṣẹ naa, ati lati pe awọn ti wọn ba kofiri nnkan ifura sori 08062335577.

 

 

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.