Ijẹsha sọkọ lu ọlọpaa, o ba balẹ si kootu

Spread the love

Ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgọta kan, Mark Ijẹhsha, ni awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko ti wọ lọ si kootu majisreeti to wa ni Ikẹja, wọn lo juko lu ọlọpaa kan, Inspẹkitọ Idowu David. Ẹsun mẹrin to ni i ṣe pẹlu igbimọ-pọ huwa ọdaran, dida omi alaafia ilu ru atawọn ẹsun meji mi-in ni wọn fi kan an ni kootu. Sjẹnti Micheal Unah to n gbẹnusọ fun awọn ọlọpaa ni kootu sọ pe ọkunrin naa sọ oko lu ọlọpaa yii lọrun lọjọ kẹwaa, oṣu to kọja, ni adugbo Aboru Oke-Odo, niluu Eko.

Ijẹsha loun ko jẹbi ẹsun naa pẹlu alaye. Adajọ A.A Fashọla faaye beeli silẹ fun un pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta Naira ati oniduuro meji niye kan naa.

Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu to n bọ, lo sun ẹjọ mi-in si.

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.