Ijamba biriiji Ọtẹdọla: Wọn fẹẹ fi yin jẹun lasan ni

Spread the love

Awọn kan ti n ko ara wọn jọ bayii, wọn ti bẹrẹ si i sọ oriṣiiriṣii ọrọ, wọn ti n purọ fawọn eeyan ilu, wọn ni ooṣa kan tabi awọn irunmọlẹ kan ati awọn ajẹ kan lo wa nibi odo to wa labẹ biriiji Ọtẹdọla, iyẹn lo fa a ti tirela fi maa n yi danu nibẹ, ti awọn bọọsi fi n takiti, ti awọn eeyan fi n ku sibẹ lojoojumọ. Irọ gbuu ni o, ko si ooṣa kan to n mu ẹjẹ awọn eeyan ni Ọtẹdọla. Bi ẹnikan ba wa to n mu ẹjẹ, awọn ti wọn n ṣejọba wa ni. Akọkọ ni pe ọọkan ibẹ yẹn ko dara, bo ṣe jinkoto sisalẹ bẹẹ lo tun lọ soke lojiji, iru ibẹ yẹn ki i ṣe fun mọto akẹru nla nla rara, iyẹn ni awọn ilu ti awọn ijọba wọn mọ iṣẹ wọn bii iṣẹ. Lati ọjọ ti ijamba ti n ṣẹlẹ nibẹ, ijọba ko mọ ohun to yẹ ki wọn ṣe. Bẹẹ ohun to yẹ ki wọn ṣe ko ju atunṣe si ọọkan ibi to lọ silẹ yẹn lọ, ki wọn gbe e soke ko ma si firii nibẹ mọ, ki ọna naa dọgba. Loootọ ki i ṣe pe ko si ibi to lọ soke to lọ silẹ ni awọn ọna mi-in o, ṣugbọn nitori bi awọn mọto to n gba ibẹ yẹn ṣe pọ to laarin iṣẹju kan, ki i ṣe ọna ti iru koto bẹẹ gbọdọ wa. Ṣugbọn ijọba tiwa ko ni i ya si iru rẹ, bi eeyan ba ku rẹpẹtẹ bẹẹ, wọn yoo jade wa, wọn yoo daro daro, awọn mi-in yoo bẹrẹ si i sun ẹkun ori-buruku, wọn yoo ni ọrọ ẹmi to ṣofo naa lo ka awọn lara bẹẹ. Bẹẹ ki i ṣe ẹkun wọn ni araalu nilo, ki wọn ṣe ohun to dara ni. Ijọba Faṣọla ṣofin pe ki tirela ma rin loju ọna yii laarin aago mẹfa aarọ titi di aago mẹwaa alẹ, nitori ọrọ oṣelu, ijọba eleyii ko ya si i, wọn ṣi awọn tirela ti ko dara yii silẹ ki wọn maa rin kiri. Ni awọn ilu to dara, ko sẹnikan ti i gbe epo bẹntiroolu gba aarin ilu, bẹẹ ni wọn ki i fi tirela gbe epo kaakiri, reluwee lo n gbe epo lati ilu kan si ilu keji, iye ti reluwee kan yoo si ko lẹẹkan ju ohun ti ọgọrun-un tirela yoo ko lọ. Awọn ti wọn n fi tirela ṣowo mọ eyi, wọn ko jẹ ki reluwee ṣiṣẹ, ijọba Naijiria ko si ya si i, bẹẹ epo bẹntiroolu yii lo n pa owo to pọ julọ fun ijọba wa, bi wọn ba yawo kan sọtọ lati kọ ọna reluwee fun epo bẹntiroolu yii, ki i ṣe ohun to pọ ju lati ṣe. Awọn Road Safety (FRSC) ti wọn ni ki wọn maa mu awọn mọto ti ko dara, awọn mọto ti wọn wọ lẹgbẹẹ, awọn ti wọn fẹẹ ṣubu loju ọna, ko ni i mu wọn, bi ẹ ba ri i ti wọn n le wọn kiri, owo ni wọn fẹẹ gba lọwọ wọn, bi wọn ba si ti gbowo, wọn yoo fi wọn silẹ ki wọn maa lọ ni. Ṣebi awọn ti wọn n pa wa niyẹn. Ki lo kan ajẹ, ki lo kan ooṣa. Awọn oniṣọọṣi ati aafaa yoo kan tun da kun iṣoro yin ni, nitori wọn ko ni i sootọ fun yin pe ijọba lo fi ojuṣe rẹ silẹ ti ko ṣe. Igbakeji Aarẹ wa, Yẹmi Ọṣinbajo, ti wa sibi ijamba yii, o ba ara Eko daro. Ṣugbọn kin ni yoo ti ibẹ jade? Ko si! Iyẹn ni ki ẹ ma ṣe jẹ ki ẹnikan tan yin jẹ o, lọjọ tijọba ba ṣe ojuṣe wọn, awọn eeyan ko ni i ku sori biriiji Ọtẹdọla mọ o.

(158)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.