Ija to n ṣẹlẹ ninu APC, anfaani ni fawa PDP l’Ekoo- Salvador Ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko ti sọ pe ija to n fojoojumọ

Spread the love

Ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko ti sọ pe ija to n fojoojumọ waye ninu ẹgbẹ oṣelu APC ti n mu anfaani rere ba awọn nitori pe gbogbo awọn tọrọ kan lawọn ti jọ n ṣe ipade papọ, ti yoo si mu eso rere wa ninu ibo to n bọ lọdun 2019.

 

Oloye Moshood Salvador to jẹ alaga ẹgbẹ naa lo sọrọ yii ninu atẹjade kan to tẹ wa lọwọ. O sọ pe bi ọrọ APC ti ṣe su awọn araalu lapapọ, bẹẹ naa lo ti su wọn nipinlẹ Eko, to si jẹ akoko ranpẹ lo ku fun wọn ninu ijọba.

 

O sọrọ yii lati fi tako ọrọ to n lọ nigboro pe ẹgbẹ oṣelu PDP ko jẹ ibẹru mọ fun APC, o ni ẹni to ba ri awọn ipade tawọn n ṣe, to ri bawọn eeyan ṣe fojoojumọ darapọ mọ awọn yoo ti mọ pe omi ti tan lẹyin ẹja APC nipinlẹ naa.

Salvador fi aidunnu ẹ han si iṣẹlẹ to waye nipinlẹ Plateau, nibi tawọn Fulani darandaran ti fẹmi ọpọ awọn eeyan ṣofo gẹgẹ bi eyi to ba ni lọkan jẹ, o ni lara pe ko si eto aabo niluu naa ni, ati pe irọ ni Buhari n pa fawọn araalu.

 

O ni ipaniyan ojoojumọ yii ko fẹẹ fawọn eeyan lọkan balẹ mọ, kaka kijọba wa ojutuu si i, irọ ni wọn yoo maa pa fawọn araalu. O ni pẹlu eto tawọn ti waa la silẹ bayii, igba diẹ lo ku fun ijọba APC ipinlẹ Eko ni Alausa.

(93)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.