Ija oṣelu n le si i, ijọba Akintọla sọ owo awọn  ọba di kọbọ kan loṣu

Spread the love

Nigba ti awọn ọba n ko ara wọn wọnu oṣelu nibẹrẹ eto naa ni ilẹ Yoruba, awọn paapaa ko le mọ pe nnkan yoo pada waa daru debii pe ere ti wọn nṣe naa yoo fọn wọn nikun. Ohun to si ṣẹlẹ ni pe ni ibẹrẹ-pẹpẹ, ko si ẹgbẹoṣelu pupọ, ẹgbẹ gidi kan naa to wa ni ẹgbẹ NNDP ti Herbert Macauley da silẹ, to pada waa di ẹgbẹ NCNC labẹ Nnamdi Azikiwe, ẹgbẹ kan naa tiọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria n ṣe niyẹn. Ohun to si jẹ ki ẹgbẹ naa fẹsẹ mulẹni pe ijọba oyinbo naa lo n ba ja, ko si si ija kan laarin ẹgbẹ yii ati ẹgbẹoṣelu mi-in, nitori ẹgbẹ oṣelu pupọ ko si nigba naa, afi awọn ẹgbẹ oṣelu keekeekee ti wọn n ṣe ni awọn abẹle tabi ẹgbẹ ilu ti kaluku n ṣe ni ilu ara wọn. Nitori eyi, ọpọlọpọ awọn ọba, paapaa awọn ọba ilẹ Yoruba, inu ẹgbẹNCNC ni wọn wa, awọn ti wọn ko si si ninu ẹgbẹ naa fẹran ẹgbẹ wọn.

Ṣugbọn ni 1951, ẹgbẹ oṣelu Action Group de, lẹyin ti wọn ti ṣe Ẹgbẹ ỌmọOduduwa fun bii ọdun mẹta. Gbogbo ọba pata lo wa ninu Ẹgbẹ ỌmọOduduwa, nitori awọn gan-an ni baba isalẹ fun wọn. Ṣugbọn igba ti wọn nṣe Ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa yii naa, ọpọ awọn ọba yii wa ninu ẹgbẹ oṣelu NCNC, nitori ko kuku si ẹgbẹ oṣelu mi-in ti wọn yoo ṣe. Igba ti ẹgbẹ AG, tiwọn n pe ni Ẹgbẹ Ọlọpẹ waa de, to si jẹ ẹni to da Ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa silẹ, to si jẹ akọwe-gbogbogboo fun ẹgbẹ naa lo da AG yii naa silẹ, koṣoro fun awọn ọba lati rọ wo inu ẹgbẹ yii, paapaa nigba ti wọn ti sọ fun ara wọn pe ẹgbẹ ọmọ Yoruba leleyii, o yatọ si ẹgbẹ awọn atọhunrinwa. Awọnọba bẹrẹ si i wọ inu ẹgbẹ naa, nigba ti Ọlọrun si ṣe e ti wọn dibo to jẹ AG lo wọle nilẹ Yoruba, Western Region, wọn fun awọn ọba nipo, owo idi oṣelu naa si n kan awọn ọba wa.

Ohun gbogbo n lọ deede ki awọn oloṣelu too bẹrẹ si i fi agbara wọn han, nigba naa ni ija bẹrẹ si i de laarin awọn ọba ati awọn olori ijọba. Ko si sohun to fa a ju pe awọn ọba ni alaṣẹ tẹlẹ, ọwọ wọn ni gbogbo aṣẹ wa pata. Ṣugbọn igba ti awọn oloṣelu de, ofin ti wọn ṣe nigba naa fi awọn ọba wọnyi si abẹ awọn oloṣelu, abẹ oloṣelu lo ku ti ọba ti n gba aṣẹ ko too ṣe ohunkohun, eyi tumọ si pe ọba ko jẹ ka-bi-ọ-ko-si-mọ, ohun yoowu ti ọbakan ba ṣe, ijọba wa lẹyin ẹ ti yoo beere bo ṣe jẹ lọwọ rẹ, ko kuku tilẹ le ṣe kinni naa bi ko jẹ pe ijọba fọwọ si i. Eyi ko tẹ awọn ọba yii lọrun, wọn si bẹrẹ si i binu. Awọn ọba yii n ro pe ẹgbẹ AG ti awọn mọ bi wọn ti bi i lo n fi iya jẹ awọn, pe ẹgbẹ NCNC ko ṣe bẹẹ fawọn, ṣe awọn ko mọ pe ofin ti wọn n lo tẹlẹ ti yipada, ofin ko fi ọba si abẹ oyinbo mọ, abẹ awọn oloṣelu lọba wa. Bẹẹ tẹlẹ, oyinbo lo n paṣẹ fawọn ọba.

Oyinbo lo n paṣẹ fun awọn ọba. Nigba ti awọn ọba yii ba si paṣẹ kan ti ko dara, tabi ti wọn fi iya jẹ ọba kan lọna aitọ, koda ko jẹ oyinbo naa ṣẹ sofin loootọ, awọn ẹgbẹ NCNC, tabi ẹgbẹ awọn ọdọ ọmọ Naijiria, Nigerian Youth Movement, ni wọn yoo dide lati maa gbeja iru ọba bẹẹ, awọn NCNC yii yoo si maa pariwo pe afi ki awọn kọwe siluu oyinbo ki wọn le fiya jẹawọn oyinbo to n ṣejọba Naijira to n fiyajẹ ọba wọn. Eyi lawọn ọba naa ṣero pe awọn oloṣelu NCNC ati awọn ẹlẹgbẹ wọn ni wọn fẹran awọn, awọnni wọn si n gbeja awọn, ti wọn fi waa n ro pe bo ba jẹ awọn ni wọn wọle ni West, wọn ko ni i fi iya jẹ awọn bi awọn AG ti ṣe sawọn yii. Nigba naa niawọn ọba kọọkan ro o paapaapaa, wọn si ni bi iwaju ko ba ṣee lọ, ẹyin yoo ṣee pada si fawọn. N ni wọn ba yi biri, awọn mi-in si n ṣe ẹgbẹ NCNC pada, wọn lawọn o ṣe ẹgbẹ Ọlọpẹ mọ.

Ṣugbọn iru awọn ọba bẹẹ ko le lọ jinna, nitori awọn mẹkunnu n fẹ ẹgbẹoṣelu AG gan-an, agaga nitori awọn eto ti wọn n ṣe fun wọn, paapaa etoẹkọ-ọfẹ to jẹ ki awọn ọmọ talaka maa ri ileewe lọ, ti ko si si pe wọn n lọọrababa niwaju ọba kan tabi niwaju awọn olowo ki wọn too le ri iṣẹ aje ṣe, tabi ki wọn too ri ọmọ wọn ran ni ile-ẹkọ to dara. Loju awọn araalu, ọba ti ko ba ti waa tẹle ẹgbẹ AG, ọba ti ko fẹran mẹkunnu ni, ika ọba si ni pẹlu.Ọba ti ko ba si ti tẹle AG paapaa, ọta ijọba funra rẹ ni, nitori wọn yoo ni nitori owo tabi nitori ti ko ri awọn ohun to n gba gba lo ṣe fẹẹ fiya jẹ awọn araalu rẹ nipa aini i jẹ ki awọn ohun daadaa ti awọn n ṣe kaakiri de ọdọwọn. Iru awọn ẹjọ wẹrẹwẹrẹ bayii lo dija Alaafin Adeniran Adeyẹmi ati ijọba awọn Awolọwọ, nigba ti awọn Awolọwọ si ti le yọ odidi Alaafin lori oye, awọn ọba to ku gbe jẹẹ ni.

Gbogbo eleyii ti ṣẹlẹ ni ibẹrẹ ijọba awọn Awolọwọ ni 1952 titi wọ 1956, latiọdun 1956 yii titi to si fi di ọdun 1960, o fẹrẹ jẹ pe ko si ọba Yoruba kan to n ṣe ẹgbẹ mi-in, AG ni gbogbo wọn n ṣe. Nigba to tilẹ jẹ pe awọn naa ti ni ile-igbimọ tiwọn, ile-igbimọ awọn ọba, to si jẹ gbogbo wọn lo wa nibẹ, ti awọn mi-in paapaa tun jẹ minista ijọba ninu wọn, ti wọn n gba owo-oṣu nla yatọ si owo ti wọn n gba nipo ọba, ti awọn naa si n ṣe ofin, ko si ọba kan ti yoo ṣe ẹgbẹ mi-in yatọ si ẹgbẹ Ọlọpẹ. Nigba naa, ẹgbẹ Ọlọpẹ ti di ọkan naa pẹlu awọn ọba ilẹ Yoruba, bẹẹ ẹgbẹ Ọlọpẹ ati Awolọwọ naa, ọkan ni. Igbadun awọn ọba ilẹ Yoruba yii pọ, nitori gbogbo ohun ti wọn ba fẹ lo n to wọn lọwọ, gbogbo ohun ti ijọba ba si fẹ, tabi ka sọ pe gbogbo ohun ti ẹgbẹAction Group ati Awolọwọ ba fẹ, lawọn naa n ṣe. Loju mejeeji, Action Group; lawọn ọba wa.

Ṣugbọn ni gbara ti Oloye Ladoke Akintọla gbajọba ni nnkan yipada. Awọnọba ti wọn ti ri ara wọn bii baba tabi bii ọrẹ Awolọwọ ko ri idi kan ti awọn fi tun gbọdọ maa foribalẹ fun Akintọla, paapaa nigba to jẹ lasiko ti Awolọwọfi n ṣejọba, ko si ọba kan, bo ti wu ko kere to, ti Akintọla le duro niwaju rẹko jampata. Akintọla ki i fi oju kekere wo awọn ọba yii, bo ba si n fẹ kinni kan bi ko ba tete ri i, a maa bẹ awọn ọba yii naa si Awolọwọ ki wọn le tete ba oun ṣe ohun ti oun n fẹ. Oju eleyii naa ni awọn ọba yii fi n wo Akintọla nigba ti oun naa waa di olori ijọba, ṣe awọn ko mọ pe ẹmọ ti kuro ni iye ti a n ta a tẹlẹ, agbara ti de ọwọ Akintọla, iyatọ si wa ninu ẹni to lagbara atiẹni ti ko lagbara. Akintọla ti ko lagbara ọtọ, Akintọla to lagbara lọwọ, ọtọni. Awọn ọba ni wọn ko tete mọyatọ, wọn ro pe Akintọla ana naa ni Akintọla oni ni.

Ohun gbogbo tilẹ n dara nigba ti ko si ija laarin Awolọwọ pẹlu Akintọla, biọba kan ba fẹ kinni kan bi ko ba tete ri i lọwọ Akinọla yoo tọ Awolọwọ lọ, tọhun yoo si paṣẹ pe ki ọkunrin olori ijọba tuntun naa ṣe e. Ọpọ igba niAkintọla ki i tilẹ i fẹ ki iru ọrọ bẹẹ de iwaju Awolọwọ, bo ba ti mọ pe ọba to sun mọ Awolọwọ ni tọhun, bo ba fẹ kinni kan, loju ẹsẹ naa ni yoo ti mọ bi yoo ti ṣe e fun un, bi kinni naa ko ba si ṣee ṣe, yoo mọ bi yoo ti ṣalaye fun un. Bi wọn ti jọ n ba kinni naa bọ ree ko too di ọdun 1961 ti nnkan bẹrẹ sii lọju pọ, to si jẹ nigba ti yoo fi di ibẹrẹ ọdun 1962, nnkan ti daru pata. Igba ti ija waa ṣẹlẹ, ti wọn tu ile-igbimọ aṣofin ka, ti wọn fi Moses AdekoyejọMajẹkodunmi ṣe olori ijọba fun oṣu mẹfa, ti wọn waa da Akintọla pada bii olori ijọba, ajọṣe oun ati awọn ọba pupọ ni ko gun rege mọ, awọn ọba diẹni wọn tẹle e.

Akintọla naa yipada, o si bẹrẹ si i ri awọn ọba kọọkan, o n fa oju wọnmọra. Awọn ọba to si kọkọ ri mu nibẹ naa ni Ọba Akran ti Badagry atiỌlọwọ ilu Ọwọ, Ọba Ọlatẹru Ọlagbẹgi. Minisita lawọn ọba yii, o si jọ pewọn o fẹẹ fi ipo wọn silẹ, awọn ni wọn si ṣaaju Akintọla, wọn kin in lẹyin pe bi ọrọ ba fẹẹ dija ko dija, bo ba si le dogun ko dogun, ko si bi ọbọ ti ṣe ori ti inaki ko ṣe, ko si ohun ti Awolọwọ ṣe ti oun Akintọla naa ko le ṣe. Nigbati ọrọ ti waa di wahala rẹpẹtẹ ti Awolọwọ si ti wa lẹwọn, awọn ọba ti wọn ko lọkan rọri pada, nitori Akintọla ti le wọn danu tẹlẹ nile-ijọba, nigba tiọpọlọpọ wọn ko si ri ibomi-in ti wọn yoo lọ, ti wọn ko si fẹẹ sọ owo ijọba to n wọle fun wọn tẹlẹ nu, kia ni wọn fi ori mẹyin, wọn sa nidii ohun yoowu to ba ti ni orukọ Awolọwọ ninu, wọn ni ijọba to ba wa lode lawọn n ba ṣe, Akintọla ni ọpọn ọrọ sun kan.

Ṣugbọn awọn ọba kan wa ti wọn ya alagidi, tabi ti wọn ko ri i bii iwaọmọluabi lati fi Awolọwọ silẹ ki awọn waa maa tẹle igbakeji rẹ nitori atijẹatimu. Wọn ri iwa ti awọn ọba to n tẹle Akintọla n hu yii bii iwa ọdalẹ, iwa ole, ati ailojuti gidi. Awọn wọnyi ni ẹyẹle ki i ba onile jẹ, ko ba onile mu, ko waa dọjọ iku rẹ ko yẹri, wọn ni ibi yoowu ti Awolọwọ wa, awọn ko ni i pada lẹyin rẹ, bẹẹ ni wọn ko ni i tori ohun ti awọn n ri gba nile-ijọba ki wọn dọrẹAkintọla ni tipatipa. Awọn ọba ti wọn kọkọ fori ko kinni yii ni Adesọji Aderẹmi ti i ṣe Ọọni, ṣugbọn wọn ko le doju ija rẹpẹtẹ kọ oun nitori awọn naa mọ pe ọrọ naa le bi awọn ọmọ Yoruba, paapaa awọn agbalagba ti wọn mọ pataki ipo Ọọni nilẹ Yoruba ninu. Ṣugbọn ni ti Ọdẹmọ Iṣara, ỌbaSamuel Akinsanya, loju ẹsẹ ni wọn ti ko bo oun, oun si ni ọba akọkọ to fori kona lọwọ awọn Akintọla.

 

Wọn o ti i sọrọ Ọdẹmọ tan nigba ti awọn ọba mi-in tun rọ sinu pakute yii, ti awọn Akintọla si sọ pe asiko naa niyẹn tawọn yoo fi han wọn pe wọn ko jẹnnkan kan. Bi wọn ti n ṣe eto naa ni pe awọn ijọba ibilẹ ni wọn maa n dẹ siawọn ọba yii. Idi ni pe ijọba ibilẹ kọọkan lo n ṣeto akoso aafin ọba nla kan, ni ọpọlọpọ ilu si ree, ọba yii funra wọn ni wọn n ṣe alaga ijọba ibilẹ, bi ọbakan ba si ti ko si wahala awọn ijọba loke lọhun-un, awọn ijọba ibilẹ yii ni wọn yoo dẹ si i, nitori labẹ ileeṣẹ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ni sẹkiteeria ni gbogbo ijọba ibilẹ wa, abẹ Oloye Rẹmi Fani-Kayọde to si jẹ igbakejiAkintọla ni ileeṣẹ naa wa, oun ni minisita to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ yii, eyi to tumọ si pe abẹ rẹ ni awọn ọba alaye gbogbo wa. Nitori aṣẹ to ba pa fun akọwe ijọba ibilẹ ni oun yoo tẹle, ohun ti oun ba si sọ, abi iwe to ba kọ, loju ẹsẹ ni ijọba ibilẹ to ba kọ ọ si gbọdọ tẹle e.

Eyi lo ṣe jẹ pe bi ọba kan ba n yan fanda fanda kiri, o fi ti Fani-Kayọde tabi Akintọla funra rẹ ṣẹ ni o, ọba ti ko ba ti fi ti awọn mejeeji yii ṣe, o n lọ niyẹn kiakia. Ọna ti wọn fi mu Ọdẹmọ naa niyẹn, ijọba ibilẹ rẹ ni wọn dẹ si i, wọn ni o n daamu awọn eeyan ilu naa, wọn lo fẹẹ maa gbowo ori kan ti awọn ko faṣẹ si, bẹẹ ohun to ṣẹlẹ gan-an ni pe Ọdẹmọ wa ninu awọn ọba to n tako Akintọla atijọba rẹ, nitori ọrẹ loun pẹlu Awolọwọ lọjọ to ti pẹ, bii ẹgbọn lo jẹ si gbogbo wọn. Ati Akintọla ni o, nitori lati igba ti wọn ti n ja ija ominira nilẹ yii ni gbogbo wọn ti wa ninu ẹgbẹ NYM, Nigerian Youth Movement.Ẹgbẹ yii ni ọpọlọpọ wọn ti pade, ti wọn si n jọ ṣe e titi ko too di pe Ọdẹmọde ipo ọba, ko si too di pe awọn Awolọwọ kawe di lọọya, ti wọn bẹrẹoṣelu, ti wọn si di olori ijọba. Gbogbo wọn lo mọ ara wọn. Akintọla mọỌdẹmọ, bẹẹ ni Awolọwọ naa si mọ ọn.

Ọrọ yii ni wọn fa ti wọn fi sọ owo-oṣu Ọdẹmọ di kọbọ kan pere, ti wọn si yọ ọ nipo rẹ gẹgẹ bii ọkan ninu awọn ọmọ igbimọ lọbalọba ni WesternRegion. Nigba ti wọn ṣe eleyii fun Ọdẹmọ, bo si tilẹ jẹ pe ọba naa ko wa si gbangba lati waa bẹ Akintọla, ọrọ rẹ yatọ, nitori alaye to bẹrẹ si i ṣe ni pe oun ko ba ijọba ja, awọn kan ni wọn fẹẹ sọ oun ati ijọba Akintọla di ọta araawọn. Iru ọrọ bayii a maa tẹ awọn Akintọla lọrun, nitori wọn mọ pe ọba to ba n sọ bayii, ọba naa ti sọrẹnda niyẹn, ki awọn tubọ fun okun diẹ mọ ọn lọrun ni, yoo gba tawọn patapata, yoo si maa ṣe gbogbo ohun ti awọn bafẹ ko ṣe. Ṣugbọn ki i ṣe ọpọlọpọ ọba lo n ṣe tiwọn ni tootọ, bo tilẹ jẹ peloju-aye, tabi ti wọn ba wa lọdọ wọn, wọn yoo maa sọrọ didun fun wọn ni. Ko jọ pe awọn Akintọla mọ eyi, nitori ọba to ba ti sọ pe oun fẹ tiwọn lọrẹwọn, awọn ti wọn ba si ti sọrọ to lodi si wọn, ijangbọn gidi ni wọn n ba wọn fa.

Eyi lo fa a ti wọn fi bẹrẹ ija pẹlu awọn ọba mẹrin kan lẹẹkan naa, ti ọrọnaa si la ariwo gidi lọ. Akarigbo ilẹ Rẹmọ, Ọba Moses Awolesi, ni wọnkọkọ mu o, ko si sohun meji to fa a ju pe wọn ni ọba yoowu to ba ti wa latiRẹmọ, nigba to jẹ Rẹmọ ni ile Awolọwọ, ọta Akintọla ati ijọba rẹ ni. Ohunto fa wahala fun ọba Awolesi ree. Bi wọn ti n ba ọba yii fa a naa ni wọn nawọ si Onitaji Itaji Ekiti lọhun-un, pẹlu Ọlọyẹ ilu Ọyẹ, ti wọn si fi OlukarẹIkarẹ, Ọba Amusa Momoh, ṣe ikẹrin wọn. Ija naa le, o si mu awọn ọba yii lomi, ọkan lara ohun to si fun ijọba Akintọla lagbara lori awọn ọba yii ni owo-oṣu wọn ti wọn ge ku pata.

Ki lawọn ọba yii kuku ṣe to bẹẹ? Ẹ pade Alaroye ọsẹ to n bọ yii o.

(119)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.