Ija n bọ: BUHARI TI DẸ EFCC S’ỌBASANJỌ

Spread the love

Awọn ti wọn mọ bi ọrọ oṣelu Naijiria ti ri ti mọ pe ibi ti ọrọ naa n lọ niyẹn, wọn ko kan mọ pe yoo ya kankan bayii ni. Aarẹ Muhammadu Buhari ti kọju ija si aarẹ ana, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ọrọ naa si ti n lọ sibi ti yoo ti di ariwo gan-an. Lati igba ti Ọbasanjọ ti kọwe gigun kan si Buhari pe bo ṣe n ṣejọba ko dara rara lọrọ ti di ariwo, to si ti di ohun ti awọn mejeeji n tahun sira wọn. Buhari kọkọ sinmi o, o ro pe Ọbasanjọ yoo kọ lẹta naa, yoo duro sibẹ ni, pe bo ba ti kọ lẹta rẹ tan, yoo tun wa iṣẹ mi-in ṣe. Afi ti pe Ọbasanjọ ko sinmi, bo ti kọ lẹta tan lo bẹrẹ si i ko awọn ẹgbẹ tirẹ kan jọ, o si bẹrẹ si i leri kiri pe awọn yoo gbajọba lọwọ Buhari lọdun 2019 to n bọ, nitori o ti han pe ọkunrin naa ko le ṣejọba Naijiria ko dara mọ, ẹni to ba si fẹ ilọsiwaju Naijiria, afi ko kun awọn lọwọ ki awọn le ọkunrin naa danu.

Awọn Buhari ko tun ti i mu kinni naa bii wahala gidi, afi nigba ti wọn ri i pe Ọbasanjọ bẹrẹ si i pe awọn oloṣelu jọ kaakiri, ti awọn eeyan si n rọ lọ si ọdọ rẹ loootọ, ti wọn n sọ pe wọn yoo ṣe ohun to ba ni ki awọn ṣe. Olu Falae lọ si ọdọ rẹ ni Abẹokuta, ipade ti wọn si ṣe nibẹ la ariwo lọ. Lati igba naa ni Buhari ati awọn ọmọ rẹ ti bẹrẹ eto mi-in, awọn kan si pe Aarẹ sẹyin, wọn sọ fun un pe ọrọ naa ko ṣee wo bi oun ti n wo o yii o, ẹni ti ko ba ni i jẹ ki eeyan jẹun yo, eeyan yoo ṣe tirẹ mọ iṣẹ ni, bo ba ṣe pe Ọbasanjọ lo fẹẹ di i lọwọ lati ma de ipo naa mọ, ko tete mura si i, ko jẹ ki awọn mọ bi awọn yoo ti ti i si ẹgbẹ kan. Ọsẹ to kọja ti Ọbasanjọ tun waa lọọ si ọdọ awọn aṣaaju ẹgbẹ Afẹnifere ni Akurẹ, to ba wọn sọrọ, to si ṣalaye idi ti awọn yoo fi le Buhari kuro lori aga ijọba, ọrọ naa ko jinnijinni gidi ba Buhari.

Ko ju ọjọ kẹta lẹyin ipade naa lọ nigba ti Buhari da esi ọrọ pada fun Ọbasanjọ, esi naa si jẹ esi to le gan-an. Owe buruku lo pa mọ ọn, owe naa si jẹ bii igba ti Buhari n pe Ọbasanjọ ni ole ni. Yatọ si tiyẹn, baba arugbo naa fihan pe oun fẹran Abacha ju Ọbasanjọ lọ, ati pe Abacha ṣe daadaa ju Ọbasanjọ lọ nigba to fi n ṣejọba. “Ohun to ba wu onikaluku ni ki wọn maa sọ nipa Abacha.” Buhari lo n sọrọ yẹn o, “Ṣugbọn ni temi o, mo fẹran Abacha, nitori awọn ohun rere to ṣe lasiko to fi n ṣejọba. Abacha ṣe titi, o kọ ileewe, o ṣe ina, o ṣe omi, oun lo si da ileeṣẹ PTF ti mo jẹ alaga rẹ silẹ, PTF yii la si fi ṣe gbogbo awọn ohun meremere ti a ṣe. Abacha ki i ṣe eeyan buruku bawọn eeyan ti n wi, ni temi, eeyan daadaa ni!”

Ọlọrun si ṣe e, ninu Aṣọ Rock lo ti n sọrọ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja lọ ni. Awọn ẹgbẹ kan ti wọn ni awọn ni ‘Buhari Support Group’ lo n gba lalejo, Ahmed Ali ti i ṣe olori ileeṣẹ awọn kọsitọọmu bayii lo si n ṣe olori ẹgbẹ naa. Nibi to ti n sọrọ fun wọn lo ti mẹnuba ọrọ Abacha, to si sọ pe o ṣe daadaa fun ilu yii ju awọn kan lọ. Nigba naa lo waa pa owe buruku ranṣẹ si Ọbasanjọ, oun naa ko si woju olori ijọba tẹlẹ naa ko too la a ni gbolohun, ko si jọ pe o kọ ibi ti ọrọ naa ba fẹẹ ja si. O sọrọ siwaju bayii ni pe, “Gbogbo daadaa ti a n sọ yii, ti a ṣe ọna lati Abuja nibi titi wọ Port-Harcourt, titi de Onitsha, titi to fi de Benin, ṣebi laye PTF ti Buhari fi mi ṣe alaga ẹ ni. Nibẹ ni awọn olori ijọba ana kan ti waa n pariwo kiri pe awọn na biliọnu mẹrindinlogun dọla ($16b) lori ọrọ ina mọnamọna, ẹ jẹ ka bi wọn, ina ọhun da o!”

Owe naa ki i ṣe owe ẹni meji, owe Oluṣẹgun Ọbasanjọ ni. Bo ṣe jẹ bẹẹ ni pe Ọbasanjọ lawọn aṣofin yii sọrọ ẹ pe nigba kan ti wọn lo na biliọnu mẹrindinlogun lori ina mọnamọna, ti iṣẹ naa ko si yanju titi to fi lọ. Ṣugbọn Ọbasanjọ lọ nigba naa, o si ṣalaye, o ni ko si ohun to n jẹ biliọnu mẹrindinlogun owo dọla, biliọnu mẹfa ni, gbogbo owo ti wọn n ṣẹ jọ, ti wọn n kọ sinu iwe fawọn aṣofin nigba naa, ko si eyi to ba ọrọ ina ti awọn ṣe mu. Nitori bẹẹ, Ọbasanjọ lo ni owe naa, Buhari naa si mọ-ọn-mọ ju oko ọrọ naa ranṣẹ si ọga rẹ tẹlẹ ni. Ohun to fi ṣe ni awọn oloyinbo n pe ni “Du-mi-ai-du yu” (Do-me-I-do-you), iwa ti Ọbasanjọ n hu si i loun naa mura lati gbẹsan. Bo ti sọ bẹẹ ni inu awọn ọmọlẹyin rẹ dun, wọn ni ohun ti awọn fẹ ki baba maa ṣe lati ọjọ yii ti ko ṣe niyẹn, Ọbasanjọ ko woju ẹ, koun naa ma ṣe woju ẹ rara.

Bi owe ba jọ owe ẹni ti a ko ba dahun, ẹru ija lo n ba onitọhun. Iru ọrọ bẹẹ ki i tilẹ i ṣe ti Ọbasanjọ. Kia lo ti fesi ranṣẹ, o ni Buhari ko kawe ni, bo ba jẹ o kawe, to si maa n kawe daadaa, gbogbo alaye pata to beere lori ọrọ ina loun ti ṣe sinu iwe kan ti wọn pe ni ‘My Watch’, eyi ti oun si fi ranṣẹ si i nigba ti oun kọ ọ, ti wọn tẹ ẹ jade. O ni bo si ṣe pe Buhari maa n ka awọn iwe to ba de ọwọ ẹ ni, tabi to ba maa n sọ pe ki awọn eeyan ka a foun, ko ni i beere iru ibeere to beere ni gbangba yẹn, nitori awọn ti wọn fẹẹ mọ ọna bi oun ti ṣe ijọba oun si lasiko ti oun n ṣejọba, gbogbo wọn ni wọn kawe naa, ti wọn si sọ ohun ti wọn ri nibẹ foun. Ọbasanjọ ni ọrọ naa ko ti i bọ o, ki Buhari tete kawe naa, bo ba si ti ka a tan, ko pe oun, oun raaye nigbakigba, ki awọn jọ jokoo, ki oun le ṣalaye awọn ti ko ba ye e fun un daadaa.

Buhari ko raaye iwe, ko si fẹẹ da Ọbasanjọ lohun mọ. Ṣugbọn awọn ọmọ rẹ ko gba, wọn ni iwa arifin ni fọgaa awọn, ẹni to ba si ti ri ọga awọn fin, awọn lo ri fin, awọn yoo ja ija naa debi to lapẹẹrẹ. Lẹsẹkẹsẹ ni EFCC ma ti bẹrẹ eto o, wọn ni awọn fẹẹ yẹ ọrọ owo ti wọn ni wọn na lori ina mọnamọna laye ijọba Ọbasanjọ wo, awọn fẹẹ mọ iye to na gan-an ati bi wọn ti na owo wọn si, ki ọkan awọn le balẹ pe wọn na owo naa daadaa. Wọn tilẹ sọ pe ki i ṣe nitori ki awọn le mu Ọbasanjọ tabi ki awọn foju ẹ gbolẹ lawọn ṣe fẹẹ wadii, awọn kan fẹẹ mọ ni: awọn fẹẹ mọ iye ti wọn jẹ gan-an, ati awọn ti wọn gba iṣẹ naa, ati bi wọn ti nawo ijọba. Wọn ni bi awọn ba ti mọ eleyii lawọn yoo ṣe akọsilẹ lọdọ tawọn, EFCC yoo si sọ pe ko si wahala ninu owo ti Baba Ọbasanjọ gba, iṣẹ ina mọnamọna ti wọn fẹẹ fi ṣe naa ni wọn fi ṣe.

Awọn ti wọn waa mọ itumọ ọrọ ni ko si alaye kankan nibẹ mọ, Buhari ti dẹ awọn EFCC si Ọbasanjọ, o fẹẹ fi wọn pa a lẹnumọ ni. Wọn ni ko fẹ ki Ọbasanjọ maa rojọ kaakiri tabi ko maa pariwo orukọ oun, ko si maa di oun lọwọ ni, nitori o mọ pe bi EFCC ba ti bẹrẹ iwadii, ti wọn n pe e lọ pe e bọ bayii, ko ni i roju raaye lati de ọdọ toun. Ọrọ ti jade lati agbo Ọbasanjọ naa ṣa o, wọn ni ohun ti baba n sọ ni pe ọkunrin arugbo naa yoo kan fi ara rẹ ṣe yẹyẹ ni, nitori awọn ohun ti awọn yoo gbe kalẹ fun un, oun naa ko ni i bọ ninu abuku ti yoo kan an layelaye.

Boya EFCC yoo pe Ọbasanjọ pe ko wa bi wọn ko ni i pe e, boya Buhari yoo bẹbẹ tabi ko ni i bẹbẹ, boya Ọbasanjọ yoo sa pada sẹyin tabi ko ni i sa, ohun tawọn araalu n beere lọwọ ara wọn kaakiri niyẹn. Ṣugbọn oju lo pẹ si, ko le pẹ ko le jinna, onikaluku naa ni yoo ri ibi ti ọrọ naa yoo pẹkun si.

(89)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.