Ija lawon omo egbe fi tuka nibi ibo abẹle ẹgbẹ oselu APC l’Ondo *Nise ni won sa ara won bii eran

Spread the love

Nnkan o ṣẹnuure laarin awọn ọmọ ẹgbẹ APC ipinlẹ Ondo lori eto ibo abẹle to waye laipẹ yii pẹlu bawọn ọmọ ẹgbẹ ọhun ṣe kọju ija sira wọn lawọn wọọdu kan, nibi ti ọpọ eeyan ti farapa lasiko eto idibo naa.

 

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni pupọ awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun lawọn wọọdu ati ijọba ibilẹ kan nipinlẹ Ondo ṣi n fẹhonu han lori ọkan o jọkan aiṣedeede ti wọn loo waye lasiko eto ibo ti wọn ṣe lati yan awọn ti yoo jẹ aṣoju ẹgbẹ yii lawọn wọọdu ati ijọba ibilẹ kọọkan.

 

Gẹgẹ bi alakalẹ eto ti ẹgbẹ APC ṣe, awọn wọọdu igba o le mẹta to wa nipinlẹ Ondo leto idibo ọhun ti kọkọ waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karun-un, oṣu ta a wa yii.

 

Ohun ta a gbọ pe o ṣokunfa wahala to waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ APC lasiko idibo ọhun ni iyapa to ti kọkọ wa laarin awọn aṣaaju ẹgbẹ naa ki eto ibo too waye.

 

ALAROYE gbọ pe awọn aṣaaju ẹgbẹ ti kan ti ko orukọ awọn alatilẹyin wọn jọ, eyi ti wọn fẹẹ yan lasiko eto ibo, igbesẹ yii lo pada doju gbogbo eto ọhun ru lawọn wọọdu kan ti wọn ko fi ri kinni ọhun ṣe rara.

 

Nijọba ibilẹ Guusu Akurẹ ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ondo, ọpọ wọọdu leto naa ko ti le waye pẹlu bawọn tọọgi oloṣelu kan ṣe ya bo wọn ni kete ti wọn fẹẹ bẹrẹ eto ọhun, ti wọn si da eto naa ru, eyi to mu ki idibo ma le waye mọ.

 

Awọn ọmọ ẹgbẹ kan to ba wa sọrọ lasiko eto ibo naa fẹsun kan Gomina Rotimi Akeredolu ati akọwe ijọba ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Sunday Abegunde, tawọn eeyan mọ si Abẹna pe wọn kọ lati gba awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti ko si ni igun tiwọn laaye lati kopa ninu eto ibo ọhun.

 

Ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ naa to ba wa sọrọ lati wọọdu kẹsan-an, eyi to wa nitosi ileewosan ijọba ipinlẹ Ondo sọ fun wa pe ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ ọjọ naa lo yẹ ki wọn bẹrẹ eto ọhun ni wọọdu naa.

 

Asiko tawọn ọmọ ẹgbẹ bẹrẹ si i de si wọọdu ọhun lati dibo lo sọ pe awọn tọọgi kan ti wọn fura si pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ awakọ de pẹlu ọkọ akero bọọsi mẹta ti wọn kun inu rẹ fọfọ.

 

Ọkan-ọ-jọkan awọn nnkan ija oloro bii ibọn, ada, aake atawọn nnkan ija oloro mi-in lo sọ pe wọn ko lọwọ, ti wọn si n ṣakọlu sawọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn ko si ni iha ti Gomina Akeredolu ati Abẹna.

 

Ọpọlọpọ awọn ohun eelo idibo ti wọn ba ni wọọdu naa lo sọ pe wọn bajẹ, ti wọn si ji awọn mi-in gbe sa lọ lẹyin ti wọn ti ṣe ọpọ eeyan leṣe.

 

Ki i ṣe wọọdu kẹsan-an nikan lo foju wina rogbodiyan lasiko idibo ọhun, o fẹrẹ jẹ pe gbogbo wọọdu mọkanla to wa nijọba ibilẹ Guusu Akurẹ ni wọn ti fẹsun kan Ọnarebu Sunday Abegunde ati alaga awọn awakọ NURTW, ẹka tipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Jacob Adebọ, ẹni tawọn eeyan mọ si Idajọ pe wọn ṣaaju awọn tọọgi kan lati waa da eto idibo ọhun ru, ti wọn si ṣe awọn ọmọ ẹgbẹ APC ti ko si nigun tiwọn leṣe.

 

Aṣofin ẹgbẹ APC kan to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Guusu ati Ariwa Akurẹ nile igbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja, Ọnarebu Afẹ Olowokere ati alaga ẹgbẹ APC nijọba ibilẹ Guusu Akurẹ, Alagba Ayọ Alogba, naa fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ.

 

Ọnarebu Afẹ Olowokere sọ fun wa pe oun ti sọ fun igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Ajayi Agboọla, lori itu tawọn tọọgi yii fi awọn eeyan pa lasiko eto idibo naa.

 

Gbogbo ọna lo sọ pe oun ti wa lati fi ohun to ṣẹlẹ naa to Akeredolu leti ko le tete wa nnkan ṣe nipa rẹ, ṣugbọn to jẹ pe oun ko ti i ri gomina ọhun ba sọrọ.

 

O ni igbesẹ ti n lọ lọwọ lati jẹ kawọn igbimọ to n ri si eto idibo ọhun gbọ nipa iṣẹle naa, o ni o di dandan ki wọn fagi le eyi ti wọn kọkọ ṣe.

 

A ko ri Ọnarebu Sunday Adegunde ba sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, ṣugbọn alaga ẹgbẹ awakọ nipinlẹ Ondo, Jacob Adebọ, ni gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun yii ki i ṣe ootọ, o ṣalaye pe oun ko figba kankan kuro ni wọọdu kẹrin ti i ṣe wọọdu oun titi ti gbogbo eto naa fi pari.

 

Iṣoro to wa lawọn ijọba ibilẹ bii Ariwa Akurẹ, Guusu Iwọ-Oorun Akoko, Guusu Ila-Oorun Akoko, Ariwa Ila-Oorun Akoko, Odigbo, Iwọ-Oorun ati Ila-Oorun Ondo ni pe eto ibo meji ọtọọtọ lo waye lawọn wọọdu to wa lawọn ijọba ibilẹ ta a darukọ wọnyi.

 

Abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo, Bamidele Ọlẹyẹlogun, sọ pe oun ko gbagbọ pe eto ibo waye rara ni gbogbo awọn wọọdu to wa nipinlẹ Ondo.

 

Ni nnkan bii aago mẹrin aabọ ọjọ naa lo sọ pe oun atawọn eeyan mi-in ṣẹṣẹ binu kuro ni wọọdu wọn ni Isarun/Erigi, nijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ, ṣugbọn ti Dokita Wahab Adegbenro (Kọmisanna feto Ilera nipinlẹ Ondo) atawọn mi-in ti wọn yan lati waa ṣẹto ibo ọhun kọ lati yọju.

 

Ọrọ naa ko si yatọ nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun ati Ila-Oorun Ondo, nibi ti ọkan ninu awọn oludije sipo gomina lasiko eto ibo gomina ipinlẹ Ondo to kọja, Ọnarebu Akinyinka Akinnọla ti ni ki wọn wọgi le gbogbo eto ibo ọhun, nitori aiṣedeede ati ojuṣaaju to waye lasiko ti wọn n ṣeto naa.

 

Akinnọla ṣalaye pe ki eto idibo ọhun too waye ni awọn wọọdu mejila to wa nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo lawọn aṣaaju ẹgbẹ naa ti ṣepade nijọba ibilẹ, nibi tawọn aṣoju ẹgbẹ ti wọn ran wa ti jẹ ko di mimọ pe, ida marundinlọgọta awọn olukopa ni wọn gbọdọ fun kọmisanna fọrọ ijọba ibilẹ ati eto oye jijẹ nipinlẹ Ondo, Ọnarebu Lọla Fagbemi, eyi to sọ pe ko dun mọ pupọ awọn ọmọ ẹgbẹ ninu.

 

Dipo ki wọn o dibo lati yan awọn aṣaaju naa, orukọ lasan lo ni awọn to waa ṣeto naa kọ nibi ti ko ti si aṣoju ajọ eleto idibo tabi awọn ẹṣọ alaabo.

 

Bakan naa lọrọ ri lawọn ijọba ibilẹ to wa lẹkun Ariwa, nibi tawọn alatilẹyin sẹnetọ to n ṣoju awọn eeyan ẹkun ọhun nile igbimọ aṣofin agba l’Abuja, Ṣẹnetọ Ajayi Boroffice, atawọn alatilẹyin Gomina Akeredolu ti kọju ija sira wọn, awọn ẹṣọ alaabo lo pada ba wọn da si i.

 

Ninu gbogbo ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ Ondo, ijọba ibilẹ Idanre ati ijọba ibilẹ Ọwọ, nibi ti adele alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ Ondo, Ade Adetimẹhin ati Gomina Akeredolu, ti wa nikan ni ko ti si wahala kankan.

 

Ko fi bẹẹ si rogbodiyan lọ titi ninu eto ibo aṣoju awọn ijọba ibilẹ ti wọn ṣe lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yii, yatọ sijọba ibilẹ Irele, nibi tawọn ọmọ ẹgbẹ APC tun ti doju ija kọra wọn.

 

Awọn aṣaaju ẹgbẹ ọhun meji atawọn eeyan mi-in la gbọ pe wọn farapa yannayanna niluu Ode-Irele lọjọ yii pẹlu bi wọn ṣe lawọn tọọgi oloṣelu kan ya bo wọn nibi ti wọn ti n ṣeto ọhun, ti wọn si ṣe ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ leṣe.

 

Lara awọn aṣaaju ẹgbẹ ọhun ti wọn ṣakọlu si lẹni to ti figba kan jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Afọlabi Iwalẹwa, ati alaga afunṣọ fun ijọba ibilẹ Irele, Ọmọọba Gbadebọ Odimayọ.

 

Ọnọrebu Iwalẹwa fẹsun kan Ọgbẹni Emmanuel Igbasan, ọkan ninu awọn kọmisanna Akeredolu pe oun lo ṣaaju awọn tọọgi kan lati waa ṣakọlu si wọn nibi ti wọn ti fẹẹ bẹrẹ eto naa.

 

Pupọ awọn ọmọ ẹgbẹ yii lo sọ pe wọn ti peju pesẹ si olu ile ẹgbẹ naa niluu Ode-Irele laaarọ ọjọ iṣẹlẹ ọhun, ti wọn si n reti ki eto idibo bẹrẹ, ṣugbọn to jẹ pe lairotẹlẹ ni wọn deede gbọ pe ko ni i sohun to jọ ibo didi nijọba ibilẹ naa, nitori pe awọn to ti wa nipo tẹlẹ ni yoo maa tẹsiwaju gẹgẹ bii adari ẹgbẹ nijọba ibilẹ Irele.

 

Ọrọ yii lo ni awọn n fa lọwọ ti awọn tọọgi oloṣẹlu kan ti wọn le ni ọgbọn fi deede ya bo wọn, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn soke leralera, ti awọn kan ninu awọn tọọgi ọhun si n ṣa awọn eeyan ladaa, nigba ti wọn n lu awọn awọn mi-in lalubami.

 

Awọn ẹṣọ alaabo kan ti Ọmọọba Odimayọ sare pe lo ni wọn gba oun lọwọ awọn tọọgi ọhun ti wọn ko fi ri oun pa.

 

Ṣa, komisanna ti wọn fẹsun kan, Ọgbẹni Igbasan, ni irọ ni wọn pa mọ oun, o ni Ọmọọba Odimayọ lo ṣokunfa rogbodiyan ọhun.

 

Akọwe ipolongo ẹgbẹ APC nipinlẹ Ondo, Steve Ọtaloro fidi ẹ mulẹ fun wa pe, niṣe lawọn tọọgi kan waa ya bo ile ẹgbẹ awọn to wa lojule kẹtadinlogun, laduugbo Oyemẹkun, niluu Akurẹ, ni nnkan bii aago kan kọja ogun iṣẹju oru ọjọ ti wọn fẹẹ ṣeto idibo ọhun.

 

Bawọn tọọgi ọhun ṣe kora wọn de lo sọ pe wọn bẹrẹ si i kọrin ogun, ti wọn si n pariwo orukọ akọwe to n ṣiṣẹ ni olu ile-ẹgbẹ naa, Smart Ọmọdunbi, pe ko tete waa fun awọn ni fọọmu ti tawọn yoo fi dibo.

Awọn ọlọpaa ‘A Division’ ni ko jẹ kawọn tọọgi naa raaye ṣe ifẹ inu wọn bo tilẹ jẹ pe wọn ba nnkan diẹ jẹ ninu ile ẹgbẹ naa.

 

Ọtaloro funra rẹ fidi ẹ mulẹ ninu atẹjade to fi ṣọwọ si wa ọhun pe lati olu ile ẹgbẹ awọn to wa l’Abuja lawọn ti yoo ṣeto idibo ọhun ti n bọ, o ni ki i ṣe lati ipinlẹ Ondo ni wọn ti yan awọn ti yoo dari eto naa.

Ko ti i sẹni to mọ ibi ti ọrọ ibo naa yoo ja si nitori awọn kan ti n pariwo pe awọn ko gba esi idibo naa wọle.

(41)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.