Ija Azikiwe pẹlu awọn Sardauna ati Balewa

Spread the love

Lọjọ ti wọn kọlu ọkan lara awọn alatilẹyin Oloye Ladoke Akintọla, iyẹn Ayọ Rosiji ti a wi yii, ọrọ naa ko rọrun fun un nigboro ilu Eko rara. Ṣe jẹẹjẹ tirẹ loun n lọ, oun ati ọrẹ rẹ kan, nigba to si bẹrẹ si i gbọ ariwo gee gee lẹyin rẹ, o ro pe awọn ti wọn n pọn oun le ni. Ṣe bo ba jẹ igba kan ni loootọ, bo ti n lọ nni, ariwo ti yoo maa tẹle e, ariwo apọnle ni, nigba ti wọn ti mọ pe ọmọlẹyin Awolọwọ ni. Amọ nnkan ti yipada bayii, ọmọ Dẹmọ ni wọn n pe e, tabi ki wọn pe e ni ọmọ Akintọla, orukọ mejeeji yẹn ko si le mu alaafia ba ẹnikẹni nigba naa. Igba ti oun ri i pe ariwo naa n le ju bo ti yẹ lọ lọkan rẹ bẹrẹ si i lu kiki, kiki, nitori kia lawọn ero ti pọ lẹyin rẹ, wọn o si ba tẹrin wa, wọn ko ba tere wa, ija ni wọn n ba bọ. Wọn n pariwo, ‘ole, ole’, nigba to si ya, wọn bẹrẹ si i juko fun un, bẹẹ ni wọn ko da ọrẹ rẹ naa si, oun naa n fara gba.

Nigba ti Rosiji funra rẹ boju-wẹyin, o ri wọn lọọọkan, oun naa si mọ pe ọwọ ija ni wọn n gbe bọ lọdọ oun yii, kia lo ti mu ọrẹ rẹ lẹyin, ni wọn ba fẹsẹ fẹ ẹ, ki oju ma ribi, gbogbo ara loogun rẹ o jare. Ile nla akọkọ to ri to jẹ ile ijọba, Niger House, ni Marina, nibẹ, lo sare wọ, to si fa ọrẹ rẹ wọ. Ọrẹ rẹ naa ti mọ pe ninu ewu loun wa, ko si ṣopo maa beere alaye kan mọ, o sare wọle koro ni. Amọ awọn ti wọn n le wọn yii ko duro mọ, ariwo, “Awo! Awo! Awo!” ni wọn n pa, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe, “Oun niyẹn! Ọkan ninu wọn niyẹn! Ẹ ma jẹ ko lọ o!” Igba ti wọn si ri i pe o ti sa wọ inu Niger House, awọn naa sa wa siwaju ile nla naa, wọn si n sọ pe ko jade, ko jade. Amọ awọn ọlọpaa atawọn sikiọriti mi-in wa lẹnu ọna ile yii, ko si sẹni kan to le fipa wọle, afi ẹni ti yoo ba ri ẹwọn gidi he.

Nigba ti wọn ko ri Ayọ Rosiji juko fun mọ yii, wọn doju okuta bo mọto ti wọn ti bọ silẹ ninu rẹ, iyẹn mẹsidiisi kan bayii, wọn n ju oko fun un titi ti wọn fi ba mọto naa jẹ gidi. Aṣe ni gbogbo igba naa, awọn alaṣẹ Niger House ti pe awọn ọlọpaa pe ki wọn waa gba Rosiji silẹ lọwọ awọn ti wọn fẹẹ pa a, awọn ọlọpaa naa si ti n sare bọ tagbara-tagbara. Amọ nigba ti wọn debẹ ti wọn ba awọn ero rẹpẹtẹ niwaju ile yii, ti wọn ko si pariwo meji ju pe ki wọn mu Rosiji jade fawọn lọ, awọn ọlọpaa naa kọkọ ba wọn sọrọ pe ki wọn maa lọ, bi wọn ba fẹẹ ri Rosiji, ki wọn lọ sile-igbimọ aṣofin, wọn yoo ri i nibẹ, nigba to jẹ oun ni olori ẹgbẹ Dẹmọ nile-igbimọ yii. Iyẹn gan-an lo si n bi awọn eeyan ninu o, pe ọwọ awọn ba olori ẹgbẹ Dẹmọ nile-igbimọ aṣofin, bi awọn ba fi igi ati kumọ da sẹria fun un, ko ṣe nnkan kan.

Awọn ero naa ko gbọrọ si awọn ọlọpaa lẹnu, nigba naa ni awọn yẹn lo tia-gaasi, ti wọn si fi tajutaju le gbogbo wọn lọ. Koda, wọn ri awọn kan mu ninu wọn, awọn mẹsan-an ti wọn si ri mu naa, wọn lawọn yoo ba wọn ṣe ẹjọ pe awọn ni wọn ba mọto Rosiji jẹ, ti wọn si tun fẹẹ ṣe e leṣe. Rosiji gan-an ko le fẹsẹ rin kuro ni Niger House, bẹẹ ni ko le wọ mọto mi-in, mọto awọn ọlọpaa lo gbe e jade nibẹ, bii igba ti eeyan lọ soju ogun ni. Ọjọ keji ni wọn ti ko awọn ti wọn ba a fa wahala yii dele-ẹjọ, ẹsun ti wọn si fi kan wọn ni pe wọn fibinu ba mọto mẹsidiisi tuntun ti Rosiji ṣẹṣẹ ra jẹ, wọn si huwa to le da rogbodiyan gidi silẹ laarin ilu, ṣe wọn jẹbi tabi wọn ko jẹbi. Awọn yẹn lawọn o jẹbi, wọn ni awọn o tiẹ mọ nnkan tawọn ọlọpaa n sọ, nitori jẹẹjẹ awọn lawọn n lọ ni Marina, ki wọn too waa ko awọn. Awọn ko si mọ Rosiji ri.

Igba ti ẹjọ naa ko lori ti ko nidii ni wọn fi awọn ti wọn mu yii silẹ, wọn si kilọ fun wọn pe ki wọn ma ṣe bẹẹ mọ. Amọ ọrọ ti kọja ikilọ, ikilọ ọhun ko si ni kinni kan lati ṣe fun awọn ti wọn n fa wahala, nitori awọn tọọgi ẹgbẹ Dẹmọ ko yee kiri, bẹẹ si ni awọn alatako wọn naa ti wẹwu ija, wọn ni nitori were ita la ṣe n ni were ile, ẹni ba foju doro ni, oro yoo gbe e. Awọn ẹgbẹ obinrin Dẹmọ tiẹ sare jade lati gbeja Akintọla. Awọn oloṣelu naa lo ko wọn jọ o, ṣugbọn ọpọ eeyan ko mọ. Ibadan ni wọn ko ara wọn jọ si, ede oyinbo ni wọn n sọ rai, wọn ni awọn o laiki bawọn eeyan ṣe lọọ dena de olori ijọba Western Region naa lode ariya to lọ, wọn ni ṣe wọn fẹẹ pa a ni abi ki lo ṣe fun wọn. Wọn ni bi awọn ti wọn wa nidii ọrọ yii ko ba jawọ, awọn yoo rinhooho fun wọn o, awọn yoo si pe adabi le wọn lori, bẹẹ adabi ja o jepe lọ.

Amọ iyẹn naa ko da nnkan kan duro, nitori bi awọn ọmọ Dẹmọ ti n fa wahala tiwọn, bẹẹ ni awọn ti wọn jẹ ti AG ati NCNC naa n kọrin kiri pe “bi ọwọ ba tẹ alaṣeju, pipa ni ẹ pa a, ka rohun jẹba lọla”, itumọ eyi si jọ pe nibikibi ti wọn ba ti ri awọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ, ariwo gidi yoo ṣẹlẹ nibẹ ni. Ani lọjọ kan, l’Ekoo, ni adugbo Tokunbọ ati Freeman, gbogbo awọn onimọto to n kọja lọ nibẹ ni wọn fara gba nnkan, oko lawọn ọmọ adugbo naa n sọ lu gbogbo wọn. Ninu oṣu keje, ọdun 1964, yẹn naa ni. Ohun to si fa wahala yii ni pe awọn araadugbo naa ri mọto ẹgbẹ Dẹmọ kan to kọja ni o, ko si sẹni to tete mọ ibi to n lọ, nibi ti mọto awọn ẹgbẹ NNDP naa ti n pooyi kiri ni awọn ọmọ adugbo ti bẹrẹ si i pe ara wọn jọ, ko si pẹ ni wọn bẹrẹ si i ju wọn loko, nigba ti mọto naa si sa lọ ti wọn ko ri i, eyi ti wọn ba ti ri ni wọn n doju ija kọ.

Awọn ọlọpaa ni wọn ṣẹṣẹ wa sibẹ ti wọn waa fi lanrofa tu wọn ka, iyanju rẹpẹtẹ si ni ki wọn too le le awọn onijangbọn naa pada si ile wọn. Bayii ni ija n ṣẹlẹ kaakiri, lati Eko titi wọ Ibadan ati titi de ilẹ Yoruba pata, bi ọrọ naa si ti n ba awọn ọlọpaa lẹru lo n ba awọn oṣelu oloootọ lẹru, afawọn oṣelu to fẹran wahala nikan ni ọrọ naa ko kan lara. Ohun to n ba awọn eeyan lẹru naa ni pe ko sẹni to mọ ibi ti iru ija bayii yoo pada ja si, ohun ti kaluku ṣa mọ ni pe igbẹyin ija bayii ko le daa, nitori lojoojumọ ni nnkan n bajẹ si i. Ọpọ awọn oloṣelu ati awọn araalu ko fẹẹ  ri Akintọla ati ẹnikẹni to ba n pe ara rẹ ni ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ, bẹẹ lọwọ Akintọla yii ati ẹgbẹ Dẹmọ ni ijọba ilẹ Yoruba wa, Akintọla ni Prẹmia, awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ to si ku ni wọn n ba a ṣejọba, ko sẹni kan to tun n ba wọn da si i mọ, gbogbo agbara pata si wa lọwọ wọn.

Amọ ki lo le maa fa iru ija bayii. Ẹgbẹ AG ni ko sohun meji to n fa a ju awọn ẹgbẹ Akintọla, ẹgbẹ Dẹmọ, fẹẹ riigi ibo naa ni, wọn ni wọn fẹẹ ṣojooro ibo yii, wọn fẹẹ fi tipatipa wọle, bo tilẹ jẹ pe awọn funra wọn mọ pe awọn eeyan ilu ko fẹ awọn. Akanni Dauda Adegbenro funra rẹ to jẹ olori ẹgbẹ Ọlọpẹ lo sọrọ naa, ko fi ran ọmọ ẹgbẹ AG kankan. O loun mọ ohun ti oun n sọ o, oun mọ pe awọn Akintọla fẹẹ riigi ibo naa ni, wọn ko fẹ ki ẹgbẹ Ọlọpẹ, AG, wọle ni wọn ṣe n ṣe gbogbo ohun ti wọn n ṣe yii. O ni awọn Akintọla ti ṣeto pe awọn yoo gba bii ẹẹdẹgbẹta awọn ẹya si iṣẹ ọlọpaa ibilẹ, o ni ohun to yẹ ki araalu beere ni pe kin ni Akintọla ati awọn eeyan rẹ fẹẹ fi ọlọpaa to to bẹẹ ṣe nigba ti ki i ṣe awọn ọlọpaa wọn ni ti ijọba apapọ. O ni ijọba apapọ funra wọn ti ko irinwo ọlọpaa wa, ki l’Akintọla tun fẹẹ fi ẹẹdẹgbẹta ọlọpaa ṣe.

Loootọ si ni, Akintọla ti ni awọn yoo gba awọn eeyan sinu iṣẹ ọlọpaa ibilẹ, ki wọn le ran awọn ọlọpaa ijọba apapọ lọwọ, ki wọn si le kun awọn ọlọpaa ibilẹ ti awọn ti ni tẹlẹ. Ṣugbọn Adegbenro ni ọrọ naa ko ri bi Akintọla ti n sọ ọ, o ni ohun ti wọn fẹẹ fi awọn ti wọn fẹẹ gba yii ṣe ni lati fi wọn ṣojooro lasiko ibo to n bọ nipari ọdun 1964 naa. O ni ọna ti awọn Akintọla yoo gbe kinni naa gba ni pe awọn eeyan ti wọn ba jẹ ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ ni yoo lanfaani lati ko awọn kan sinu iṣẹ ọlọpaa yii, awọn ni wọn yoo maa mu eeyan wa, wọn oo si fi asiko naa ko awọn tọọgi ti wọn n lo nigboro bayii sinu iṣẹ ọhun, iyẹn yoo le fun wọn ni agbara lati ṣe iṣẹ ti awọn olori Dẹmọ aa  gbe fun wọn, ko si si iṣẹ meji ti wọn yoo gbe fun wọn ju lati maa fiya jẹ awọn ti wọn ba jẹ aṣaaju ẹgbẹ Ọlọpẹ tabi ti NCNC lọ.

Loootọ lawọn eeyan Akintọla jade, ti wọn ni ọrọ naa ki i ṣe bẹẹ, Adegbenro n ba awọn lorukọ jẹ ni, nitori ọkunrin naa fẹran asọdun, sibẹ, ọpọ eeyan ko gba awọn Dẹmọ yii gbọ, wọn ni Adegbenro ko le ri wọn ti, paapaa nigba ti Adegbenro funra rẹ sọ poun ni ẹri lọwọ lati ko kalẹ lori ọrọ ti oun n sọ. Eleyii ko fi awọn araalu lọkan balẹ rara, paapaa nigba ti Adegbenro tun sọ ohun ti wọn ko mọ, ti wọn ko si ronu si fun wọn. O ni ajọṣe buruku kan wa laarin Sardauna Ahmadu Bello ti i ṣe olori ẹgbẹ NPC tawọn Hausa, ati Ladoke Akintọla tiwa. O mọ ohun ti Sardauna n ṣe nilẹ Tiv, lọdọ awọn ara Benue ati Plateau, nibi ti wọn ti n fi awọn ṣọja pa wọn ni ipakupa lọkunrin naa fẹẹ waa ṣe nilẹ Yoruba, ohun to fẹẹ ran Akintọla lọwọ lati ṣe niyẹn, ti wọn yoo maa pa awọn eeyan bii ẹran, ti ijọba yoo si yi oju rẹ sẹgbẹẹ kan.

Ṣe ni gbogbo igba naa ni ija buruku n lọ lọwọ  ni ilẹ awọn Tiv, to jẹ bi awọn ṣọja ti n kọlu wọn ni Jos, ni wọn n kọlu wọn ni Markurdi ati gbogbo agbegbe naa titi wọ ilu Lokoja. Bi wọn ti n pa awọn Igbira ni wọn n pa awọn Agatu, ko si sohun meji to n faja naa ju pe; awọn eeyan naa ko ṣe ẹgbẹ NPC to jẹ ẹgbẹ awọn Hausa yii lọ, wọn ni awọn ko le ṣe ẹru fun Fulani laelae. Amọ gbogbo ọrọ to ba ti ri bẹẹ yẹn, Sardauna ki i fẹẹ gbọ ọ seti rara, nitori bẹẹ lo ṣe ko ogun ati ija gidi lọ si aarin wọn, wọn si da ṣọja sibẹ ti wọn n ba wọn finra gidi. Gbogbo ọmọ Benue tabi Plateau tabi laarin awọn Agatu to ba n ba awọn olori ẹgbẹ NPC adugbo naa ṣagidi, ẹwọn lo fi n ṣere yẹn, o eyi to ba si lagbara ju, awọn ṣọja ni wọn yoo fi ile rẹ ṣe ọna nijọ kan. Iyẹn lo ṣe jẹ pe rogbodiyan ko fi agbegbe naa silẹ nijọ kan, ariwo ojoojumọ ni, awọn araalu ati awọn ṣọja onibọn.

Adegbenro ni gbogbo eto ti Sardauna n dana ẹ fun ilẹ Yoruba niyi, o fẹẹ ran Akintọla lọwọ pẹlu awọn nnkan ija ogun ni. Adegbenro ni ibẹru to tiẹ wa ni pe bi wọn ba ṣe bẹẹ ni ilẹ Yoruba ti wọn ba mu un jẹ, wọn yoo kọja si ilẹ Ibo naa, kẹrẹkẹrẹ, awọn eeyan naa yoo si gba gbogbo ilẹ Naijiria mọ ara wọn lọwọ. Adegbenro ni bi gbogbo aye ba gba, awọn Yoruba ko ni i gba iyẹn, AG ti i ṣe ẹgbẹ Ọlọpẹ ni yoo si ṣaaju ija naa, kawọn Akintọla tete maa mura ogun ni. Loootọ ọrọ West ni Adegbenro sọ, ṣugbọn nigba to ti mẹnuba ọrọ pe wọn yoo de ilẹ Ibo yii, ati pe wọn yoo gba Naijiria funra wọn yii, ọrọ naa ran kari Naijiria, o si di ohun ti awọn agbaagba mi-in n da si. Ọrọ naa pada waa di yanpọnyanrin, nigba ti awọn Hausa kan kọlu Nnamdi Azikiwe, aarẹ ilẹ Naijiria. Wọn bu u, wọn fi i wọlẹ ni o, n lọrọ naa ba di biliisi gidi.

Azikiwe ni aarẹ Naijiria, ipo kan ti ko si fi bẹẹ lagbara ni, ipo bii ipo oludamọran lasan ni wọn sọ kinni naa da nigba ti ijọba de ọwọ Sardauna ati Balewa tan, nitori ko sẹnikan ti i tẹle ọrọ ti aarẹ naa ba sọ. Awọn ọmọ Hausa ati awọn to n tẹle Sardauna ko tilẹ ka ọkunrin naa si aarẹ, wọn ki pe e ni aarẹ lẹyin rẹ, wọn yoo maa pe e ni aṣaaju awọn Ibo ni, ati pe iwa Ibo ko le tan lara ẹ. Eyi lo ṣe jẹ bi wọn ba ti raaye lati sọ ọrọ kan bayii, wọn yoo mọ bi wọn yoo ṣe tahun si Azikiwe, wọn yoo ni oun lawọn Ibo n sin, tabi ki wọn ni awọn Ibo lo n maa n ṣiṣẹ fun. Paripari rẹ ni pe ọpọlọpọ nnkan to yẹ ki Azikiwe mọ, ko si da si, ni wọn ki i jẹ ko mọ, wọn yoo gbe kinni naa gba ẹyin rẹ kọja, wọn yoo si ti ṣe e tan ko too maa gbọ. Bo ba gbọ naa to ba beere, ko sọrọ ti wọn yoo sọ fun un ju pe ko ma binu lọ, ṣugbọn eyi ko sọ pe ki wọn ma ṣe bẹẹ lọla.

Eyi ti wọn waa sọ gbẹyin ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keje, 1964 yii, bi Ige, o bi Adubi, nitori ibi ti wọn ro pe ọrọ naa yoo ja si kọ lo ja si. Awọn ọmọ Hausa, eeyan Sardauna yii, ro pe bi awọn ti maa n sọrọ naa ti Azikiwe yoo fi i ṣe osun ti yoo fi i para, bẹẹ naa ni yoo tun ṣe lasiko yii, pe ko ni ibinu kan ti yoo bi sawọn, ohun to ba wu awọn lawọn le sọ. Awọn o mọ pe o pẹ ti Azikiwe naa ti ko ọrọ sinu, nitori o ti mọ pe gbogbo ọrọ ati isọkusọ tawọn eeyan yii n sọ, bi ki i baa ṣe pe Sardauna n ti wọn lẹyin ni, ti ko si fẹ ki wọn maa bu oun, yoo ti pe wọn lati kilọ fun wọn pe wọn ko gbọdọ bu oun mọ, ṣugbọn nigba to jẹ ohun ti oun naa fẹ lawọn yẹn ṣe foun, ti wọn n bu oun bii ẹni layin, ti inu rẹ si n dun, iyẹn lawọn yẹn ko ṣe jawọ ninu ẹ, to jẹ gbogbo igba ni wọn n bu oun sinu iwe iroyin, ati lori redio kaakiri.

Ibinu yii ti wa nilẹ, awọn ọmọ Sardauna ko mọ, ni Azikiwe ba fa ibinu tirẹ yọ. Bẹẹ gẹgẹ bi olori orilẹ-ede Naijiria, ibinu ti Azikiwe rinlẹ kari aye ju ti awọn ti wọn ṣejọba lọ. Ọrọ kan lo tun ṣe bii ọrọ ni wọn ba tun pe Azikiwe lọmọ Ibo, ti wọn tun ni iwa Ibo yoo ṣa maa ba a kiri ibi to ba n lọ ni, ko le fi iwa Ibo silẹ, iwa Ibo naa ko si le fi i silẹ, o kan jẹ olori Naijiria ni. Nigba naa ni ọrọ yii bi Azikiwe ninu, lo ba bẹrẹ si i tu bii ejo si gbogbo wọn lara. Ati Sardauna ati Balewa, ati gbogbo ẹni to mọ nipa ọrọ naa, Azikiwe da girama bolẹ, o foyinbo sọ fun wọn pe nọnsẹnsi ni gbogbo ohun to n ṣe.

Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.

 

 

 

 

(79)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.