Ija awọn NCNC le si i, ni TOS Benson ba pariwo: “Gbogbo ọmọ Naijiria, ẹ gba mi,

Spread the love

Awọn Ibo fẹẹ pa mi o!”

Ẹgbẹ kan wa ti wọn n pe ni Ibo State Union, ẹgbẹ awọn ọmọ Ibo ni. Ẹgbẹ naa da bii ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa tiwa nigba naa, o kan jẹ wọn ti da ẹgbẹ yii silẹ tipẹ gan-an ki wọn too ṣẹṣẹ da tiwa silẹ ni, ẹgbẹ naa si ti ran ọpọlọpọ ọmọ Ibo lọwọ. Ko si olowo ọmọ Ibo ti ko si ninu ẹgbẹ yii, ko si si oloṣelu to fẹẹ lorukọ nilẹ Ibo ti ko ni i jẹ inu ẹgbẹ yii ni yoo kọkọ lọ. Ẹgbẹ naa ti ran Oloye Nnamdi Azikiwe paapaa lọwọ ati awọn oloṣelu mi-in ti wọn tun wa lati apa ọdọ wọn. Ọpọlọpọ awọn ọmọ Ibo ti wọn ti lọọ kawe niluu oyinbo jade, ẹgbẹ yii lo n ran wọn lọ. Lọrọ kan, ẹgbẹ yii ko ni ohun meji ti wọn n ṣe ju ọrọ ọmọ Ibo lọ, ko si sohun ti wọn ko le ṣe, ko si iye ti wọn ko le na lati ri i pe ọmọ Ibo bọ siwaju ninu ohun gbogbo. Ko sohun to buru ninu eleyii, o kan jẹ nigba tija bẹrẹ laarin awọn Yoruba ati Ibo nidii oṣelu, ẹgbẹ naa fara ko o.

Ni gbogbo bi ija yii ti n lọ, bi awọn ọmọ Ibo wọnyi ti n gba iwaju ni wọn n gba ẹyin, wọn si n wa ọna lati fi han gbogbo aye pe awọn oloṣelu Yoruba ti wọn wa ninu ẹgbẹ NCNC ni alaṣeju, awọn Ibo to ni ẹgbẹ kan pe wọn waa jẹun ni, ṣugbọn nigba ti wọn de idi ounjẹ, wọn fẹẹ mu wọn lọwọ dani. Eleyii lawọn Yoruba to wa ninu ẹgbẹ naa ko gba, awọn bii TOS Benson ni itan inaki loju awọn ko to, bo ba jẹ ti ọbọ ni, awọn mọ nipa rẹ. Wọn ni ṣebi Herbert Macaulay lo da ẹgbẹ rẹ silẹ, wọn si ti n ṣe ẹgbẹ naa le ni ọdun mẹwaa ko too di pe Azikiwe de lati ilu ọba to waa darapọ mọ wọn. Nitori pe o mọwe, o jẹ ọmọde, ni awọn aṣaaju ẹgbẹ yii ṣe mu un, to si n tẹle Macaulay kaakiri titi ti Macaulay fi ku, ti oun Azikiwe si waa pada di olori ẹgbẹ naa, nibo lẹgbẹ NCNC ti waa jẹ ti Ibo o!

Iwa awọn ọmọ ẹgbẹ Ibo State Union yii lo bi TOS Benson ninu, lo ba gbe iwe kan jade lọjọ kẹsan-an, oṣu kerin, ọdun 1964, o ni ki gbogbo aye kilọ fun ẹgbẹ Ibo State Union, abi kin ni wahala wọn gan-an. TOS Benson kọwe sita bayii pe: “Mo fẹẹ pe akiyesi gbogbo ọmọ Naijiria si iwa ati iṣesi awọn ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni Ibo State Union. Mo fẹ ki gbogbo awọn ọmọ Naijiria wo iwa ẹlẹyamẹya, iwa anikanjọpọn, iwa afemi-afemi ti ko tun si iru rẹ nibi kan laye, tawọn ọmọ ẹgbẹ Ibo Union yii n hu ni Naijiria, ki gbogbo ọmọ Naijiria si mọ pe iru iwa bẹẹ ko ni i gbe wa de ibi idagbasoke ti a fẹ, yoo kan pa wa lara gbẹyin ni. Ohun ti ẹgbẹ awọn ọmọ Ibo yii n ṣe ko dara o, bi a ko ba si tete jọ dide ki gbogbo wa pawọ pọ ka ba wọn wi bayii, ohun ti ọrọ naa yo mu wa lọla ko ni i tẹ ẹnikẹni lọrun, ọrọ to le da nnkan ru fun gbogbo wa ni.

“Ẹ wo ọrọ ija to n lọ ninu ẹgbẹ NCNC, awọn ẹgbẹ Ibo Union ti gba ọrọ naa kanri, wọn si ti sọ ara wọn di lọọya, agbẹjọro fun awọn ọmọ ibo to wa ninu ẹgbẹ yii, nibi ti ọrọ naa si ti kan wọn ko ye mi rara. Ẹgbẹ oṣelu NCNC yatọ si ẹgbẹ Ibo Union, nibo ni wahala to wa ninu ẹgbẹ wa ti waa kan wọn, to di ohun ti awọn araale n tori rẹ ranṣẹ si ara oko. Kin ni tiwọn ninu ọrọ yii, iyẹn ni ko ye emi rara. Mo n sọ ọrọ yii ki i ṣe nitori ohun meji, bi ko ṣe ki gbogbo ọmọ Naijiria le mọ ohun to n lọ ati iwa awọn eeyan yii ni. Ki lo kan ẹgbẹ Ibo Union ninu ija to n lọ ninu NCNC? Kin ni tiwọn nibẹ? Mo tun beere lẹẹkan si i. Loju awọn Ibo State Union, ko si ọmọ Ibo kan to le ṣe ibajẹ, tabi to le ṣe aṣiṣe, gbogbo ohun yoowu ti ọmọ Ibo ba ṣe lo dara, ko si aidara ninu ọrọ ọmọ Ibo, iduro awọn ọmọ ẹgbẹ Ibo State Union niyẹn.

“Bi ko ba waa jẹ bẹẹ, ki lo de ti ẹgbẹ yii, tabi ọmọ ẹgbẹ yii kankan ko le sọrọ si Ọmọwe Okechukwu Ikejiani, ti wọn ko le ba a wi nipa iwa to n hu ni ileeṣẹ reluwee to jẹ tijọba apapọ, nibi to ti n le awọn ọmọ Yoruba ti wọn wa nibẹ to n ko awọn ọmọ Ibo si i. Ki lo de ti ko si aṣaaju ẹgbẹ awọn ọmọ Ibo kan to le sọ pe ohun ti eeyan wọn yii n ṣe ko daa. Ki lo de ti wọn ko le ba Ọmọwe Ikejiani sọrọ nigba to sọrọ arifin si olori ẹgbẹ NCNC, Ọmọwe Michael Okpara, ẹni to jẹ Prẹmia, olori ijọba adugbo wọn? Awọn nnkan ti mo n beere lọwọ awọn ẹgbẹ Ibo Union yii ṣe pataki, nitori iwa ti wọn n hu yii, iwa to le yẹ opo ti Naijiria funra rẹ duro le lori ni. Nigba ti ile kan ba si wa ti opo to gbe e duro ba ti bẹrẹ si i yẹ, gbogbo ọlọgbọn ni yoo mọ pe ile naa ti ṣetan to fẹẹ wo niyẹn. Ohun ti mo ṣe n beere awọn ibeere wọnyi niyẹn.

“Fun ẹni ti ko ba ye daadaa, tabi ẹni to ba ti gbagbe, ẹ jẹ ki n ran yin leti. Ọrọ ti a n sọ yii, iyẹn ọrọ to dija ninu ẹgbẹ yii, bo ṣe bẹrẹ ni pe awa kan ninu ẹgbẹ fi ẹsun kan awọn aṣaaju ẹgbẹ wa pe bi wọn ti ṣe n pin awọn ipo to ba kan ẹgbẹ NCNC lapapọ ko tẹ wa lọrun, nitori gbogbo ipo naa, bi wọn ba ti n wa, ọdọ awọn ọmọ Ibo lo n lọ, bẹẹ awọn ọmọ Ibo si ni aṣaaju ẹgbẹ wa. Ẹsun ta a fi kan wọn niyi, a si kọ ọrọ naa si iwe, emi ni mo ṣaaju awọn to gbe iwe naa lọ. Ẹgbẹ wa la kọwe si, ẹgbẹ NCNC, awọn aṣaaju wa la si ba sọrọ. Awọn kan tun dide ninu ẹgbẹ, wọn ni ẹsun ti a fi kan awọn aṣaaju ẹgbẹ yii ki i ṣe bẹẹ, awọn naa si tun fi ẹsun mi-in kan awa ti a gbe iwe ẹsun akọkọ lọ. Ki ọrọ ma dija, awọn aṣaaju gbe igbimọ kan dide pe ki wọn lọọ wadii ọrọ naa. Igbimọ naa ko ti i bẹrẹ iṣẹ tawọn kan fi binu kuro ninu ẹgbẹ wa.

“Bi awọn kan ṣe binu kuro yii, awa kan ko kuro ninu ẹgbẹ, a duro sibẹ, a si fi ọkan awọn aṣaaju wa balẹ pe awa ko ni ibi kan i lọ, o si ṣee ṣe ka ri ninu awọn ti wọn binu lọ paapaa gba pada bi a ba mura si ọrọ naa, ti a si le yanju ohun to n bi wọn ninu. Lẹnu iṣẹ eyi la wa lọwọlọwọ. Gbogbo ohun ti a n ṣe yii, aarin awọn to ba jẹ ọmọ ẹgbẹ, ati aṣaaju ẹgbẹ, NCNC la ti n ṣe e, ko kan araata, ko si lọwọ ẹlomi-in ninu ju awa ti a jẹ ọmọ NCNC lọ. Ki waa lo kan Ibo Union ninu ọrọ naa, kin ni wọn da si i si. Ta lo pe wọn si i, kin ni wọn si ṣe ro pe ẹtọ awọn ni lati da si i. Ṣe ki wọn le fi ẹsẹ ahesọ tawọn eeyan n sọ pe awọn Ibo lo ni ẹgbẹ NCNC mulẹ ni abi bawo? Tabi ki wọn le tubọ fun awọn eeyan lọrọ sọ pe ẹgbẹ NCNC ti bajẹ, wọn ti yẹsẹ kuro lori ọna ti awọn ti wọn da ẹgbẹ naa fi i le. Ko ye mi rara ni mo ṣe n sọ.

“Ofin ẹgbẹ wa ti mo mọ lati bii ọdun mẹtadinlogun ti mo ti n ṣe ẹgbẹ yii bọ ni pe nibi ti ifẹ ara ẹni, tabi ifẹ ẹnikẹni, tabi ifẹ awọn ẹya eeyan kan ba ti tako ofin ẹgbẹ NCNC, ofin ẹgbẹ ni yoo leke, ti ẹgbẹ ni yoo ṣẹ, kaluku yoo gbagbe ẹya to ti wa, tabi ifẹ to wa lọkan rẹ, wọn yoo si mu ti ẹgbẹ ṣe kia. Bi awọn ti wọn da ẹgbẹ ti ṣe gbe ofin naa kalẹ ree, ofin naa la si ti n tẹle lati ọjọ yii wa. Ṣe awọn ẹgbẹ Ibo Union waa n sọ fawa ọmọ Naijiria to ku bayii pe ohun ti awọn Ibo ba ti n fẹ ju ohun ti apapọ ẹgbẹ NCNC ba n fẹ lọ ni. Ṣe wọn n sọ pe ohun ti Ibo ba n fẹ ni nọmba-waanu ni, ti ohun yoowu ti awọn to ku ba n fẹ ni Naijiria yii ko ja mọ kinni kan mọ. Awọn Ibo kan ti wọn wa ninu NCNC naa ni wọn si da gbogbo wahala yii silẹ o, tori awọn ni wọn n lo ileeṣẹ ijọba lati fi gbe awọn eeyan wọn sipo, ti wọn si n fọwọ rọ Yoruba ibẹ sẹyin.

“Ẹgbẹ awọn ọmọ Ibo yii ti n sọ fun gbogbo awọn eeyan wọn pe mo koriira awọn Ibo ni, pe n ko fẹran wọn, mo fẹẹ ba wọn lorukọ jẹ, mi o fẹ ki ẹtọ to tọ si wọn kan wọn lọwọ ni Naijiria, mo fẹ ki wọn wa labẹ awọn Yoruba, iyẹn ni mo ṣe n pariwo. Akọkọ ni pe mo fẹ ki gbogbo eeyan pata ni Naijiria, paapaa awọn ọmọ Ibo mọ pe mi o koriira wọn o, mi o ni ohun ti mo fẹẹ gba ninu ki n ma jẹ ki ẹtọ to tọ si wọn kan wọn lọwọ. Fun ẹni ti ko ba mọ, iyawo ti mo kọkọ fẹ, Ibo ni, n ko si le gbagbe ẹ laelae nitori awọn ohun ti a jọ ṣe papọ ko too di oloogbe, awọn ohun ti o pa emi pẹlu ẹ pọ lagbara debii pe ko si bi mo ṣe le ṣe lọjọ kan ti n ko ni i ranti rẹ, oun ati awọn eeyan ẹ ni. Iyẹn ni pe ko si bi mo ṣe le koriira awọn Ibo laye mi, nitori emi pẹlu wọn ti di ara kan naa: eeyan mi ni wọn, eeyan wọn lemi naa.

“Sugbọn kinni kan wa ti n ko le faramọ, ti n ko le gba, iyẹn naa ni pe mi o ni i fẹ ki awọn Ibo maa fi ẹtọ awọn eeyan mi-in dun wọn. Mi o ni i fẹ ki Ibo tori pe awọn fẹẹ ga, ki wọn mura lati tẹ Yoruba ri, tabi lati sọ Yoruba di ero ẹyin, iyẹn ni emi ko ni i ṣe o. Bi a o ba ga, ki a jọ ga ni, bi a o ba dagbasoke, ka jọ dagbasoke, ki ohun to ba tọ si kaluku bọ si i lọwọ, ohun ti emi fẹ niyẹn. Mi o gbọdọ maa sọ fun yin, ṣugbọn awọn ti wọn mọ mọ, wọn mọ iye ti ẹgbẹ awọn ọmọ Ibo yii ti na nitori lati ba emi ẹni kan ṣoṣo yii lorukọ jẹ, ati lati sọ mi di ẹni ti ko jẹ nnkan kan, ti awọn eeyan ko ni i gba ọrọ rẹ gbọ, wọn ko fẹ kawọn eeyan gbọ ohun mi rara. Bẹẹ ootọ lọrọ mi, ohun to n lọ ni mo n sọ. Ki gbogbo ẹni to ba fẹran Naijiria ba awọn ẹgbẹ Ibo State Union sọrọ, ki wọn sọ fun wọn pe Naijiria yii, ti gbogbo wa ni, ki wọn ma da a ru o!”

Bi Oloye Theophilous Owolabi Ṣobọwale Benson ti kọwe jade lọjọ kẹsan-an, oṣu kẹrin, ọdun 1964, ree, ija to n lọ laarin awọn Yoruba ati awọn Ibo ninu ẹgbẹ NCNC lo si fa a. Awọn ọmọ Yoruba n binu, wọn ni gbogbo ipo nla nla bii minisita bii alaga iṣẹ ijọba ti ijọba apapọ ba ti pin kan ẹgbẹ NCNC, awọn Ibo lo n jokoo tẹ ẹ. Nibi ti wọn ba si ti tun ri i pe awọn Yoruba jẹ ọga, wọn yoo wa ọna lati yọ wọn danu, wọn yoo si fi ọmọ Ibo mi-in si i. Ohun to n faja niyẹn. Awọn eeyan tilẹ ro pe ija naa ti pari ni, afi bi Benson ṣe tun ru kinni naa jade, nigba ti awọn ọmọ Ibo bẹrẹ si i gbogun ti i, ti wọn n rojọ rẹ kaakiri pe oun lo n da ẹgbẹ ru, oun lo fẹẹ sọ Yoruba di olori awọn Ibo ninu ẹgbẹ wọn. Awọn ti wọn ka iwe ti Benson gbe jade ti mọ pe ọrọ naa ko ni i lọ bẹẹ, awọn kan sọ pe awọn Ibo yoo fesi ọrọ, ọjọ ti wọn yoo fesi gan-an ni wọn ko le sọ.

Ṣugbọn aileja ni ita baba mi ko debi yii, ọdan ojude baba ẹni ki i gbeja ẹni. Awọn ẹgbẹ Ibo State Union ko jẹ ki ọrọ naa tutu rara, lẹsẹkẹsẹ ni wọn da esi pada fun TOS Benson, wọn ni ko wa ibikan jokoo si, aṣiri ẹ ti tu sawọn lọwọ ọjọ pẹ. Wọn ni ki lọkunrin naa tun n duro ṣe ninu ẹgbẹ NCNC, wọn ni ko tete kọwe fipo ẹ silẹ gẹgẹ bii minisita, ko si fi ile-igbimọ aṣofin apapọ silẹ nitori orukọ NCNC lo fi wọle sibẹ, ko waa dije ipo naa lọdọ awọn ọrẹ rẹ tuntun ti wọn wa ninu ẹgbẹ NNDP, nitori awọn mọ pe inu ẹgbẹ to fẹẹ lọ niyẹn. Wọn ni gbogbo awọn ọrẹ ẹ lo wa ninu ẹgbẹ tuntun yii, awọn si mọ pe Oloye Ladoke Akintọla ati Fani-Kayọde ti wọn da gbogbo ọrọ yii silẹ n ṣẹwọ si i lojoojumọ pe ko maa bọ lọdọ awọn ko waa gba yindinyindin. Wọn ni o ti han bayii pe ẹgbẹ NCNC ti ko ẹran mero, iru awọn eeyan bii Benson to wa ninu ẹgbẹ wọn ni igi to n ṣe eefin ninu ẹgbẹ yii, afi ki wọn tete yọ wọn danu.

Ẹgbẹ Ibo Union ni ko si alaye kan ti Benson yoo tun ṣe ti aye yoo gba a gbọ mọ, nitori gbogbo eeyan lo mọ pe ọkan ninu awọn ti wọn da ẹgbẹ NNDP silẹ ni, ṣugbọn ko laya lati wọ inu ẹgbẹ naa lo ṣe duro sinu NCNC lati tubọ ba ẹgbẹ naa jẹ si i. Wọn ni ko si orukọ meji ti eeyan yoo pe iru TOS Benson ju alaimoore lọ, nitori oore ti awọn Ibo ṣe fun un ko ṣee ka tan, awọn Ibo ti wọn ṣa wa ninu NCNC ni wọn sọ ọ da gbogbo ohun to da loni-in, abi ki waa ni gbogbo fulenge to n ṣe kaakiri. “Bi ko ba si awa ọmọ Ibo ti a duro ti i, ṣe TOS Benson le de ipo to wa loni-in yii ni, ki waa lo fẹẹ joye afibisoloore si, ti ko rẹni ti yoo bu mọ to jẹ awa Ibo ni. O yẹ ki ọkunrin yii ranti o, pe nigba ti awọn Yoruba rẹ kọ ọ silẹ, awa Ibo la ma gbe e depo, ti a si jẹ ko sare ga ninu oṣelu bo tilẹ jẹ pe awọn Yoruba ẹgbẹ ẹ n binu nitori ẹ.”

Awọn ẹgbẹ Ibo State Union sọ ninu atẹjade naa pe “Eeyan kan, tabi iran kan, tabi alagbara kan ko le fọwọ rọ wa sẹyin lori ọrọ Naijiria yii, nigba to jẹ pe awa la ja fun ominira pẹlu owo ati iṣẹ aṣekara, ati gbogbo agbara ti a ni. Iwa ika gbaa ni fun Oloye TOS Benson ti a mu jade lati inu okunkun to wa nibi ti ko ti jẹ nnkan kan, ti a si sọ ọ sinu imọlẹ ti oun naa waa di eeyan nla. Ko waa daa ko tori pe oun fẹẹ jẹun, ko tori pe oun fẹẹ gba nnkan lọwọ awọn kan, ko waa tapa si awọn ti wọn gbe e dide. TOS Benson fẹẹ sọ wa di eeyan buruku loju awọn Yoruba onilaakaye ni, o fẹ ki wọn maa ri gbogbo Ibo bii ọta wọn. Ẹ ba a sọrọ o, ikoriira to ni fun awọn Ibo yii ti to gẹẹ o, bi ko ba si jawọ ninu ẹ, yoo kandin ninu iyọ, ohunkohun to ba si ri nidii ẹ, ko tete yaa fara mọ ọn!”

Ọrọ ti ẹgbẹ awọn ọmọ Ibo sọ gbẹyin yii ba TOS Benson lẹru, iyẹn pe yoo kandin ninu iyọ, tabi pe ohun to ba ri nidii ẹ, ko tete fara mọ ọn. Niṣe lọkunrin naa pariwo sita lojiji, o ni “Gbogbo ọmọ Naijiria ẹ gba mi, awọn Ibo fẹẹ pa mi o!” Nigba naa ni ọrọ naa di ariwo loootọ loootọ, awọn aṣaaju Yoruba dide, wọn ni nnkan kan ko gbọdọ ṣe TOS, awọn agbalagba Ibo naa ni kinni kan ko le ṣe e, ọrọ oṣelu lasan ni, ijọba apapọ da si i pe ọrọ yii ti fẹẹ le ju bo ṣe yẹ lọ o. Ṣugbọn ọrọ naa ko tẹ TOS Benson lọrun, ko mọ ibi ti ileri awọn Ibo yii le ja si foun. Nigba naa ni Ladoke Akintọla, olori ijọba West dide, Igbakeji rẹ naa, Fani-Kayọde, dide, wọn ni nibi ti nnkan de duro bayii, awọn yoo gbeja TOS Benson, awọn yoo gbeja ọmọ iya awọn, nitori aṣa ko gbọdọ wọle ko gbe ọmọ ewurẹ lọ. Eewọ ni o!

 

(20)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.