Ija agba meji l’Ọṣun: OYETỌLA KOJU ADELEKE

Spread the love

Bii ala lo ri loju awọn aṣaaju ati adari ẹgbẹ APC patapata, ki i ṣe awọn ti wọn wa ni ipinlẹ Ọṣun nikan o, awọn ti wọn wa ni gbogbo Naijiria ni, ṣugbọn tawọn ara ilẹ Yoruba lo le ju, nitori titi di bi a ti n wi yii, ẹlomi-in ṣi ro pe oju ala loun wa ni. Ohun to n ya wọn lẹnu pọ gan-an ni. Wọn ko nigbagbọ rara pe ẹgbẹ oṣelu kan yoo lagbara lati le ko girigiri ba ẹni ti wọn n wo gẹgẹ bii Arẹmọ APC nilẹ Yoruba, Ọgbẹni Raufu Arẹgbẹṣọla, ti i ṣe gomina ipinlẹ naa. Bi ẹnikẹni yoo ba si waa fun ọkunrin ti wọn n pe ni Baba Kabiru to ti ṣe gomina ipinlẹ naa fun odidi ọdun mẹjọ ni idaamu, ki i ṣe ẹni ti gbogbo wọn ti sọ lorukọ alajoota, ti wọn pe ni Ade Dancer, iyẹn Sẹnetọ Ademọla Adeleke. Ṣugbọn lojiji ni gbogbo nnkan sun siwaju fun wọn, ibi ti wọn foju si, ọna ko ba ibẹ lọ rara, iyẹn ni wọn si ṣe ro pe ala lawọn n la.

Alaroye ti fi ẹsẹ rẹ mulẹ pe bi ko jẹ ọgbọn ti wọn da si i, iyẹn ọgbọn pe ori agba ree san ju oju agba ree lọ, ti wọn si lo kaka ki ọmọde pa mi layo, ma lo ọwọ kan ojooro, Adeleke yoo ti maa palẹmọ lati wọle ijọba bayii, nitori ajọ INEC to ṣeto ibo naa iba ti sọ pe oun lo wọle. Ọrọ naa iba da wahala silẹ paapaa, nitori fun bii wakati meji lẹyin ti wọn ti ka gbogbo ibo to ti pe, ti awọn araalu si ti mọ ẹni to wọle, INEC ko le jade lati kede orukọ ọkunrin naa, koda wọn ko le sọrọ paapaa, wọn sa lọ pata kuro lori afẹfẹ ni. Ni gbogbo akoko naa, awọn alagbara n fi foonu ba ara wọn sọrọ ni, wọn fẹẹ mọ ohun ti wọn yoo ṣe gan-an. Awọn aṣaaju APC kan ni ki wọn sọ fun INEC ki wọn kede orukọ Oyetọla gẹgẹ bii ẹni to wọle, gbogbo wahala to ba si ku nibẹ, ki wọn da a da awọn, awọn yoo yanju ẹ.

Ọna ti wọn fẹẹ gba fi kede orukọ ọkunrin naa ni pe wọn ti yọ ibo ẹgbẹrun kan ninu ibo tawọn eeyan di fun PDP, wọn ni ẹgbẹrun mẹsan-an lo yẹ ko jẹ, ki i ṣe ẹgbẹrun mẹwaa to wa nibẹ. Ṣugbọn nibi ti awọn ti wọn n ka ibo ti n fa ọrọ naa lọwọ ni awọn ọlọpaa ti mu ọkunrin kan de, Salawu Mutiu Kọlawọle, ọkan ninu awọn oṣiṣẹ INEC to n ṣeto idibo naa ni. Aṣe Salawu lo lọọ ya iwe ibo ti awọn eeyan ti di fun ẹgbẹ PDP ni Ayedaade, nibi ti wọn ti sọ pe ibo ẹgbẹrun mẹsan-an lo wa nibẹ, to si jẹ ẹgbẹrun mẹwaa nibo ti awọn eeyan di gan-an. Nigba ti ọwọ iya dun Salawu loootọ loootọ, o ni ki wọn ṣe oun jẹẹjẹ, ki wọn ma gbẹmii oun, ki i ṣe pe oun deede waa ya esi idibo naa, ọga awọn kan, Arabinrin Aderinoye, lo ni ki oun lọọ ya a, ki APC le bori nibẹ daadaa.

Nigba ti awọn ti wọn ti n mura lati yọ ẹgbẹrun kan kuro ninu ibo Adeleke ki wọn si kede pe ko wọle gbọ ariwo ojiji yii, kia ni kaluku ṣe mẹdọ, wọn si sọ yika pe bii igba ti eeyan yoo da ogun silẹ ni ipinlẹ Ọṣun ni bi wọn ba da oju ibo naa ru. Ṣugbọn sibẹ naa, wọn ni ko yẹ ki wọn fiya jẹ APC bẹẹ, ki wọn ma gbe e fun Adeleke, ki wọn jẹ ki awọn wa ọgbọn da si i. Ọgbọn ko ni i tan laye ki wọn wa a lọ sọrun lo jẹ ki wọn wo inu iwe ofin eto idibo, wọn si sa si abẹ ofin kan to sọ pe bi ibo ti ẹni to wọle ba fi ju ekeji rẹ lọ ko ba ti to iye ibo ti ko dara ti wọn bajẹ, dandan ni ki wọn tun ibo naa di, iyẹn ni alaga eto idibo naa, Adeọla Fuwapẹ lo to si kede bayii pe, “Emi Joseph Adeọla Fuwapẹ to jẹ olori awọn oṣiṣẹ to dari eto idibo yii kede pe akude ni ibo Ọṣun yii, ibo naa ko le pari bayii rara!”

Njẹ kin ni wọn yoo waa ṣe si i o? Afuwapẹ ni ọna meje pere lawọn yoo ti dibo keekeeke, ọjọ Alamisi, Tọsidee, to si n bọ yii lawọn yoo dibo naa. O ni wọn yoo dibo lọna mẹta ni ijọba ibilẹ Orolu, wọn yoo di i lọna kan ni Ifẹ North, wọn yoo di i ni ọna meji ni Ifẹ South, wọn yoo si di ẹyọ kan l’Oṣogbo. Ọrọ naa bi awọn aṣaaju PDP ninu, wọn si kigbe lojiji pe, “Haa, ojooro leleyii o!” Alukoro ẹgbẹ wọn, Kọla Ologbondiyan, ni “Eleyii ko daa. Gbogbo ohun to yẹ ki ondupo gomina tiwa ṣe labẹ ofin lo ti ṣe. O ni ibo to pọ ju ti alatako rẹ lọ. O ni ibo ida mẹrin ni gbogbo agbegbe ijọba ibilẹ, ki waa ni wọn tun fẹ ko ṣe. A ko ni i gba ki wọn lu wa ni jibiti yii gbe, ohun to ba gba ni a oo fun un!” Atiku Abubakar naa sọrọ, o ni eru to foju han leleyii, bẹẹ ni Bukọla Saraki ni ki Adeleke tete lọ sile-ẹjọ, ko le gbajọba ẹ lọwọ wọn.

Afuwapẹ to kede esi abajade ibo naa funra ẹ ni ko si ohun ti awọn le ṣe ṣaa o. O ni ibo 254, 698 ni Adeleke ni, Oyetọla si ni 254, 345, eyi ni pe ibo 353 pere ni Adeleke fi ju Oyetọla lọ. Ọkunrin naa ni bo ba ti ri bẹẹ, afi ki awọn dibo lawọn ibi ti wahala ti ṣẹlẹ, ki awọn le yanju ọrọ naa. Ọrọ naa dun mọ awọn APC ninu gan-an. Ta ni yoo ṣe! Ṣe awọn ti fidi jalẹ, wọn ko si le dide, ofin tuntun ti wọn fa yọ yii nikan lo ko wọn yọ. Aṣiwaju Bọla Tinubu ti i ṣe aṣaaju agba fẹgbẹ wọn sọ pe “A ti la okun pupa ja bayii, awa naa ti ri i bi ọrọ ti jẹ, ko si si ohun ti a le ṣe ju ka dupẹ lọwọ awọn ololufẹ wa ati ọmọ ẹgbẹ ti wọn jade lati dibo lọ. Bo ba jẹ awọn kan ni, wọn yoo da oju ibo yii ru ni, ṣugbọn ẹgbẹ tiwa ki i ṣe bẹẹ, ka dupẹ fun APC ti ki i ṣe ojooro. Ohun ti mo n sọ fawọn ololufẹ wa bayii ni pe ki wọn jade lọjọ Alamisi ju bi wọn ti jade ni Satide lọ, ki wọn si fibo gbe ẹgbẹ wọn dide pada.”

Ṣugbọn ko jọ pe ọrọ naa yoo rọrun bi Tinubu ti wi yii o, nitori kinni naa ti di ija agba meji, yoo si le diẹ fun APC, afi ki wọn mura daadaa. Awọn PDP ti sare jade, wọn ni awọn n lọọ ba Iyiọla Omiṣore, ẹni to jẹ ẹgbẹ rẹ lo ni ibo to pọ julọ ni Ileefẹ, paapaa ni agbegbe ti wọn ti fẹẹ tun ibo di yii. Wọn ni PDP ni Omiṣore, ko ni i jẹ ki ẹgbẹ rẹ ṣubu. Minisita igba kan ri, Fẹmi Fani-Kayọde, tiẹ ni oun ti ba Omiṣore sọrọ, o si ti ni ko si ṣiṣe ko si aiṣe, oun yoo ti Adeleke lẹyin ki awọn le jọ le ijọba buruku to dọti ipinlẹ Ọṣun lọ. Bakan naa ni wọn ni gomina tẹlẹ, Ọlagunsoye Oyinlọla, ti ni oun yoo ba Alaaji Fatai Akinbade ti ẹgbẹ rẹ naa ja raburabu sọrọ, bẹẹ lawọn yoo si mu Adeoti ti awọn APC fiya buruku jẹ naa mọra, nitori bi awọn ko ba mura bẹẹ, awọn mọ pe APC fẹẹ ṣojooro ni.

Bi ọwọ awọn PDP ba si fi le to Omiṣore loootọ, to dide to yi Ifẹ po fun wọn, to si fi ote le e pe PDP ni kawọn eeyan oun dibo fun, pẹlu awọn oludibo bii ẹgbẹrun meji to wa lagbegbe oun nikan, nnkan yoo ṣẹnuure fun Adeleke lẹyin ibo. Amọ o, APC naa ko kawọ gbera, awọn naa n sọ pe ki Oyetọla funra rẹ lọọ ri Omiṣore, ko si fa a mọra nigba to jẹ nibẹrẹ ọjọ oun naa, inu AD lo wa tẹlẹ, bẹẹ ni wọn ni ki wọn tete lọọ ba Adeoti, akọwe ijọba Arẹgbẹṣọla, ki wọn sọ fun un ko jeburẹ, ko ma jẹ ki awo ba awo jẹ loju awọn ọgbẹri, ko duro ti awọn ki awọn le jawe olubori nibi ibo kekere yii. Awọn aṣaaju APC mi-in paapaa n sọ pe bi ọrọ ti ri yii, ki awọn tete mu agbara ijọba apapọ sọrọ naa ni, nitori bi awọn ko ba ṣe bẹẹ, omi yoo ti ẹyin wọ igbin lẹnu, igbin ku niyẹn o!

Bayii ni ọtun n leri, ti osi naa n leri; ọtun n mura, osi naa n mura; ija agba meji leleyii, o di ọjọ Alamisi ka too riran wo lọna Ọṣun

(28)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.