Igbeyawo ọdun mẹjọ tuka l’Okitipupa

Spread the love

Adajọ kootu kọkọ-kọkọ kan to wa niluu Okitipupa, ti paṣẹ pe ki igbeyawo ọdun mẹjọ to wa laarin Abilekọ Ajeyẹmi Famoye ati ọkọ rẹ, Ọgbẹni Sunday Famoye, di tituka nigba ti obinrin naa sọ pe ifẹ ọkọ oun ti yọ lẹmii oun.

Abilekọ Ajeyẹmi lo mu ẹsun ọkọ rẹ wa sile-ẹjọ naa pe gbogbo igba lo maa n lu oun ni alubami lori awọn ọrọ ti ko to nnkan.

Bakan naa ni olupẹjọ tun juwe ọkọ rẹ bii ọdaju ọkunrin pẹlu bo ṣe sọ pe o pa oun ti.

Iya ti ọkọ rẹ fi n jẹ ẹ naa lo sọ pe ko sẹyin bi oun ko ṣe rọmọ bi fun un nigba ti oyun bii mẹfa bajẹ lara oun, eyi lo si fa a ti ọkunrin naa fi gbe igbesẹ lati fẹ iyawo meji mi-in, ti gbogbo wọn si bimọ fun un.

Nigba ti wọn pe Ọgbẹni Sunday to jẹ ọkọ iyawo siwaju pe ko waa sọ tẹnu rẹ lori awọn ẹsun ti iyawo rẹ fi kan an, o ni oun ko ni alaye kankan lati ṣe ju pe ki wọn ba oun bẹ iyawo oun, nitori oun ṣi nifẹẹ rẹ daadaa, oun ko si ṣetan lati kọ ọ silẹ.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Aarẹ kootu ọhun, Ọgbẹni Adedeji Adebisi, tu igbeyawo naa ka, niwọn igba ti gbogbo akitiyan kootu lati ba wọn yanju rẹ ko so eso rere.

(29)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.