Igbeyawo ọdun mejila tuka n’Ikarẹ-Akoko

Spread the love

Kootu kọkọ-kọkọ to wa n’Ikarẹ-Akoko, ti faṣẹ si i pe ki igbeyawo ọdun mejila kan di tituka latari ẹsun agbere ti olujejọ, Abilekọ Fọla Oseni, fi kan ọkọ rẹ, Ọgbẹni Ṣọla Oseni.

 

Ninu ọrọ ti olupẹjọ sọ lasiko to n ṣalaye lori awọn idi to fi pinnu ati jawee ikọsilẹ fun ọkọ rẹ lo ti juwe olujẹjọ ọhun bii alagbere.

 

Ọkan ninu awọn ale ọkọ rẹ to jẹ ọlọpaa lo ni o maa n pe oun sori foonu lọpọlọpọ igba, ti yoo si maa ṣepe nla nla fun oun lai ṣẹ lai ro.

 

O ni ṣe lọkọ oun maa n binu kuro ni yara ti awọn jọ n sun, ti yoo si lọọ tilẹkun mọri ninu yara mi-in nigbakuugba toun ba ti n ba a sọrọ lori irinkurin to n rin kaakiri igboro.

 

Ẹsun keji to tun fi kan olujẹjọ ọhun ni bo ṣe lo pa oun atawọn ọmọ meji toun bi fun un ti fun bii oṣu mẹwaa gbako, ti ko si fun awọn lounjẹ.

 

Kikọ ti ọkunrin naa kọ lati sanwo-ori rẹ lati bii ọdun mejila sẹyin ti wọn ti fẹra wọn ni abilekọ ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn ọhun tun juwe bii idi pataki mi-in to fi fẹẹ kọ ọ silẹ.

 

Nigba ti wọn pe ọkọ iyawo siwaju pe ko waa sọ tẹnu rẹ, ẹbẹ lo ki mọlẹ to n bẹ ni kootu pe ki wọn saa ba oun bẹ iyawo oun, nitori pe ko si awijare kankan toun fẹ maa sọ.

 

Ọkunrin to n ṣiṣẹ tiṣa naa sọ pe gbogbo ẹjọ ti olupẹjọ ro mọ oun lẹsẹ loun fara mọ patapata, o ni ki wọn ba oun bẹ ẹ ko le yi ipinnu rẹ pada.

 

Nigba ti wọn si bẹ obinrin ọhun titi ti ko gba lo mu ki Aarẹ kootu naa, Ẹniọwọ E.O. Adelabu, tu igbeyawo wọn ka, to si paṣẹ pe ki awọn ọmọ wọn mejeeji wa nikaawọ iya wọn, niwọn igba tọjọ ori wọn ṣi kere.

 

O tun paṣẹ fun olujẹjọ pe o gbọdọ maa san ẹgbẹrun meji Naira fun itọju ọmọ wọn akọkọ to jẹ ẹni ọdun marun-un loṣooṣu, ati ẹgbẹrun mẹrin Naira fun itọju ọmọ keji to ṣi jẹ ọmọ ọwọ.

 

 

 

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.