Igbeyawo ọdun mẹẹẹdọgbọn fori sanpọn l’Okitipupa

Spread the love

Nitori ẹsun ọdaju ati ifiyajẹni ti iyawo fi kan ọkọ rẹ, kootu kọkọ-kọkọ to wa l’Okitipupa, ti tu igbeyawo ọdun mẹẹẹdọgbọn to wa laarin Ọgbẹni Tomisin Kayọde ati iyawo rẹ, Abilekọ Kikẹlọmọ Kayọde, ka.

 

Inu oṣu kẹjọ, ọdun yii, ni obinrin ọhun mu ẹsun ọkọ rẹ wa si kootu naa, nibi to ti n rawọ ẹbẹ si wọn pe ki wọn ba oun fopin si ibaṣepọ to wa laarin awọn.

 

Iyaale ile yii ni lati ibẹrẹ pẹpẹ igbeyawo awọn ni ede-ai-yede ti wa laarin awọn mejeeji, awọn ko si ri i yanju titi digba to fi wa si kootu lati waa jawee ikọsilẹ.

 

O ni nnkan to le yanju iṣoro ti oun n koju lọwọ ni ki ipinya de ba ibaṣepọ ọlọdun gbọọrọ naa, ki olukuluku wọn si maa ba tirẹ lọ.

 

Olujẹjọ naa kọ lati fesi si gbogbo ẹsun ti iyawo rẹ fi kan an, bakan naa lo han ninu iwa rẹ pe oun naa faramọ ki igbeyawo awọn mejeeji tuka ni ibamu pẹlu ẹbẹ olupẹjọ.

 

Aarẹ kootu naa, Alagba O. Adedeji, paṣẹ pe ki ibaṣepọ awọn mejeeji di tituka, niwọn igba ti wọn ko ti ri aarin wọn yanju fun oṣu mẹrin gbako ti wọn ti bẹrẹ igbẹjọ.

O ni ọmọ kan ṣoṣo to wa laarin wọn lẹtọọ lati gbe nibikibi to ba wu u laarin baba ati iya rẹ, nitori pe ọmọ naa ti dagba daadaa, o si le da inu ro funra rẹ.

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.