Igbesẹ ti bẹrẹ lori bi Ọlọwọ tuntun yoo ṣe gori oye

Spread the love

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, lawọn afọbajẹ ilu Ọwọ bẹrẹ igbesẹ lori bi Ọlọwọ ti wọn ṣẹṣẹ yan, Ọmọọba Ajibade Gbadegẹṣin Ogunoye, yoo ṣe gori itẹ awọn baba nla rẹ.

Gẹgẹ bo ṣe wa ninu iṣẹdalẹ ilu Ọwọ, ẹni ti wọn ba ṣẹṣẹ yan lawọn afọbajẹ gbọdọ fidi iyansipo rẹ mulẹ lẹyin ọjọ mẹrinla geere ti wọn ba ti kede rẹ gẹgẹ bii ọba.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja ni gbogbo awọn afọbajẹ tun ko ara wọn jọ pẹlu awọn eeyan pataki mi-in niluu Ọwọ, lati ṣayẹyẹ fifi idi iyansipo Ọmọọba Ajibade Gbadegẹṣin mulẹ gẹgẹ bii ọkan ninu awọn ilana ati igbesẹ ati yan ọba tuntun.

Alaga awọn afọbajẹ, Oloye-agba Ọlanrewaju Famakinwa, to tun jẹ Ọjọmu tilu Ọwọ to kede fifi idi iyansipo ọba tuntun naa mulẹ ni aato ti wọn ṣe naa pọn dandan lẹyin ọjọ mẹrinla ti olori awọn Ọmọlọwọ ba ti fa ọba ti wọn dibo yan le awọn afọbajẹ lọwọ.

Igbesẹ yii lo ni o wa lara ofin to de ilana fifi ọba tuntun jẹ niluu iṣẹnbaye naa, o si fi kun un pe eto ọhun gbọdọ lọ pẹlu ajọyọ ati ariya nitori pe ọjọ ti ko ṣee gbagbe bọrọ lo maa n jẹ fawọn eeyan ilu naa.

Alaga afun-un-sọ nijọba ibilẹ Ọwọ, Ọmọọba Ṣẹgun Ọmọjuwa, to jẹ ọkan lara awọn alaboojuto eto ọhun rọ gbogbo awọn ọmọ ilu naa la ti fọwọsowọpọ pẹlu ọba ti wọn ṣẹṣẹ yan, ki alaafia ati isọkan to ti wa laarin wọn tẹlẹ le maa gbooro si i.

Ọmọọba Ajibade Gbadegẹsin Ogunoye funra ẹ fi idunnu rẹ han si bi ohun gbogbo ṣe lọ lai si wahala tabi ija ṣaaju ati lẹyin iyansipo ọhun, o si ṣeleri fawọn araalu poun aa ṣa gbogbo ipa oun fun idagbasoke ati itẹsiwaju ilu Ọwọ, ni gbara toun ba ti gbọpa asẹ.

Ko ju bii ọsẹ kan pere lọ lẹyin tawọn afọbajẹ kede Ọmọọba Ajibade gẹgẹ bii Ọlọwọ tuntun ti ijọba ipinlẹ Ondo, labẹ akoso Gomina Rotimi Akeredolu, toun naa jẹ ọmọ bibi ilu Ọwọ, fun un ni igbega lẹnu iṣẹ ijọba to n ṣe.

Ipo adari lo wa tẹlẹ nileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo ko too di pe wọn kede iyansipo rẹ gẹgẹ bii ọkan ninu awọn akọwe agba patapata fun ileeṣẹ naa lọsẹ to kọja.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.