Igbega awọn ọba di wahala, Oyebọde atawọn kan pe ijọba lẹjọ

Spread the love

Rukerudo ti bẹ silẹ lori igbega ati iyansipo ti Gomina Abdulfatah Ahmed ṣe fawọn ọba ati baalẹ kan ni agbegbe Ariwa,

(Kwara South), laipẹ yii pẹlu bi Ọmọọba Oyebọde Kasali Akinọla atawọn mi-in ṣe wọ ijọba lọ sile-ẹjọ.

ALAROYE gbọ pe wọn n pẹjọ lati tako iyansipo Yisau Atọlagbe gẹgẹ bii baalẹ akọkọ ni Gaa Bọlọrunduro, ẹni ti wọn pe ni ajeji ati alejo nilẹ Igbọnna.

Awijare wọn ni pe Onigbọnna lo fun awọn baba nla Atọlagbe ni ilẹ lati tẹdo si nigba kan sẹyin,  fun idi eyi, wọn ko le waa gba ilẹ lọwọ awọn, ki wọn si tun maa jẹ adari le awọn araalu lori.

Wọn ni igbesẹ tijọba Kwara gbe jẹ ọkan lara ohun to lodi ti wọn n ṣe nipa igbega ati iyansipo awọn ọba.

Lọsẹ to kọja yii nijọba gbe ọpa aṣẹ ati iwe-ẹri fawọn ọba alaye kan lẹkun Ariwa ti Gomina Ahmed ti wa. Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan kan ti ni kinni ọhun lọwọ oṣelu ninu, paapaa julọ bo ṣe n waye lẹyin ọsẹ diẹ ti ẹgbẹ PDP to n ṣejọba fidi-rẹmi ninu atundi ibo.

Awọn to pẹjọ ọhun ni ko si tabi-ṣugbọn kan nibẹ pe o tọ, o yẹ kijọba ṣe igbega fawọn ọba alaaye kan lati ọdun diẹ sẹyin. Ṣugbọn o yẹ ki wọn tọ awọn ọba ilu lọ ko too di pe wọn yan baalẹ siluu.

Ṣe ki idibo ọdun 2014 too waye nijọba Kwara ti gbe orukọ awọn Baalẹ ati Magaji kan jade lati ṣegbega fun wọn sipo kẹrin nibamu pẹlu ofin to rọ mọ iyansipo awọn ọba ati oloye ilu nipinlẹ Kwara.

Ṣugbọn ikede naa da awuyewuye silẹ pẹlu bawọn ọba alaye kan ṣe fẹdun ọkan wọn han tako bijọba ṣe gbe awọn orukọ naa jade lai jẹ kawọn mọ si i. Oriṣiiriṣii lẹta atako lo waye nigba naa.

Wọn ni lai ka gbogbo ẹjọ ati bawọn kan ṣe n fapa-janu si, ijọba tẹsiwaju lati fun awọn baalẹ kan ni iwe iyansipo ati igbega.

Ti baalẹ Gaa Bọlọrunduro ọhun lawọn eeyan ri gẹgẹ bii ohun to le da nnkan ru nijọba ibilẹ Ọyun, paapaa julọ laarin awọn ọba to wa nibẹ.

Awọn araalu Igbọnna lo ti n leri pe bijọba ko ba tete fopin si igbesẹ to gbe naa, o le ṣakoba fun wọn ninu idibo ọdun 2019.

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.