Igba Naira ni mo n fun awọn ọkunrin ti mo ba ti ṣe ‘kinni’ fun-Okafor

Spread the love

Ebuka Okafor, ẹni ogun ọdun, ti jẹwọ pe loootọ loun n ba awọn ọmọkunrin sun, ati pe igba Naira loun maa n fun wọn lẹyin ti oun ba ṣe nnkan toun fẹẹ ṣe tan.
Laarin ọsẹ to kọja yii ni awọn ọdọ kan mu Okafor lagbegbe Ọja Oṣodi, niluu Akurẹ, wọn si fẹsun kan an pe o maa n ṣe ibalopọ akọ si akọ.

Aafin Deji ilu Akurẹ ni awọn ọdọ yii kọkọ wọ ọ lọ, lẹyin ti wọn ko si ri ọrọ naa yanju laafin Deji ni wọn fa afurasi ọdaran naa le awọn Sifu Difẹnsi ilu Akurẹ lọwọ.

Ọkunrin naa jẹwọ pe loootọ loun n ṣe kinni fun awọn ọkunrin bii toun. O ni ko ti i pẹ pupọ toun bẹrẹ iwa yii, nitori pe inu oṣu kẹjọ, ọdun yii, ni oun ṣẹṣẹ bẹrẹ si i huwa naa. Igba Naira lo ni oun maa n fun awọn ọkunrin toun ba ti ṣe kinni fun lẹyin ti wọn ba ti ba oun ṣere tan.
Ni idahun si ibeere akọroyin wa lori idi to fi fẹran ibasun awọn ọkunrin ẹgbẹ ẹ bẹẹ, o ni ai ni obinrin nitosi oun lo fa iwa toun n hu naa.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Ọga ajọ Sifu Difẹnsi nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Pedro Awili, sọ pe awọn ti fa Okafor le ileeṣẹ to n ri sọrọ awọn obinrin nipinlẹ Ondo lọwọ fun igbesẹ to yẹ.

Awili waa rọ awọn obi lati maa mojuto awọn ọmọ wọn daadaa, ki wọn ma baa kẹgbẹ-kẹgbẹ, bẹẹ lo tun rọ awọn araalu lati tete maa fi ohunkohun to ba n ṣẹlẹ layiika wọn to awọn ẹṣọ alaabo leti.

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.