Idris, ọga ọlọpaa atijọ, ewo lewo o

Spread the love

Lọjọ ti wọn n so ami oye nla mọ ọga ọlọpaa pata ti wọn ṣẹṣẹ yan, Muhammed Adamu, lara ni Abuja, ti Aarẹ Buhari wa lọwọ ọtun, ti ọga ọlọpaa ti tẹlẹ wa lọwọ osi, ẹni to ba ri oju ọga ọlọpaa atijọ yii, iyẹn Ibrahim Idris, yoo mọ pe nnkan bọ sọnu lọwọ rẹ. Niṣe loju rẹ ku teitei, gbogbo ẹrin ti wọn si n rin nibẹ ko de inu rẹ, irẹwẹsi ba a, o si han jade loju rẹ, ati ninu ẹrin to n rin. Bi eeyan ba ṣe iṣẹ kan to fi de ipo ọga pata, lọjọ ti yoo ba fẹyinti, ọjọ ayọ lo yẹ ko jẹ fun un, ko maa rẹrin-in, ko si maa ba awọn eeyan ṣere, nitori oriire gidi lo ṣe, ki i ṣe gbogbo eeyan ni i ṣiṣẹ ti i fẹyinti, tabi ti i di ọga pata. Amọ Idris ko le rẹrin-in, o boju jẹ bii ẹni ti iṣẹ bọ lọwọ rẹ, tabi bii ẹni to ṣowo ṣọọti, o da bii eegun to jade lati aarọ ti ko fẹẹ wọle mọ.  Ki lo le mu iru eyi wa? Ko si ohun meji ti i mu iru eyi wa ju bi ẹni to fẹẹ fi ipo silẹ ko ba lo ipo naa daadaa lọ. Idris ba nnkan jẹ gẹgẹ bii ọga ọlọpaa, o si ti ro pe gbogbo iwa ti oun n hu yii, Buhari ko ni i le oun lọ, yoo fi ọjọ kun ọjọ oun ninu iṣẹ naa, igba ti wọn ba si ṣeto idibo tan, o kere tan, oun yoo tun lo bii ọdun kan si i ki wọn too ni ki oun maa lọ. Ohun ti Buhari fẹẹ ṣe naa ree, ṣugbọn ariwo pọ, awọn eeyan taku, awọn oloṣelu lawọn yoo ṣe iwọde, awọn ọga ọlọpaa atijọ ni ki Buhari ma fi apẹẹrẹ buruku lelẹ lati pe oun n fi ọjọ kun ọjọ to yẹ ki Idris fẹyinti, nigba ti ariwo ọhun ti pọ de oju rẹ, ko si ohun ti Buhari le ṣe mọ, wọn ni ki Idris maa lọ, eyi to ṣe to. Ohun to mu un to ba oju jẹ niyẹn. Awọn iwa to ti hu lo n ranti, awọn iṣẹ buruku ti wọn ti ran an toun naa ti jẹ, awọn iwa ti ko yẹ ka ba ọga ọlọpaa nidii rẹ to ti hu ati ohun to ṣe fawọn eeyan ti wọn ṣi wa nipo agbara bayii lo n ja a laya. Kin ni yoo ṣẹlẹ soun, ohun to n ṣe e niyẹn. Bẹẹ bi agbara ba ti kuro lọwọ eeyan, ti ẹlomi-in ti bọ sibẹ, tọhun ko jẹ kinni kan bayii mọ. Awọn kan wa to jẹ bi wọn pade ọga ọlọpaa yii nita, bi wọn fọ ọ leti, ko si ohun ti yoo ṣe, afi ko fi ara rẹ pamọ sibi kan ki wọn ma ri i. Ẹkọ to wa ninu eleyii ni pe bi ọba ran eeyan ni iṣẹ ẹru, ko fi tọmọ jẹ ẹ, bi eeyan ba si wa nipo kan, ko maa ranti pe ibẹ kọ loun yoo wa titi laye, oun yoo pada kuro nibẹ ni. Ohun ti ọkunrin Idris yii ko ranti ree, o ti ro pe ẹni ti wọn ba fi jẹ ọga ọlọpaa pata, igbakeji Ọlọrun ni, ibẹ ni yoo si wa titi aye. O ti ṣẹlẹ bayii o, ipo ti bọ lọwọ ọga Idris, o wa n ka ṣioṣio kiri. Amọ ko ti i ri kinni kan o, iya ti yoo jẹ oun naa ko ti i mọ, o ku diẹ fun un. Ẹni to ba wa nipo kan to ba ba ibẹ jẹ, iru iya to n jẹ wọn n duro de Idris, bo fẹ bo kọ, yoo si jiya naa dandan.

 

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.