Idibo ku si dede, egbe PDP n leri pe awon yoo bori, APC ni ko sohun to jo o *Awon egbe yooku naa ni tawon ni araalu n fe

Spread the love

Bo tilẹ jẹ pe ọkan pataki lara awọn idibo ti yoo waye lorileede yii lọdun yii, iyẹn idibo gomina, ti waye kọja nipinlẹ Ọṣun, sibẹ, eto oṣelu ṣi n gbona girigiri bayii, eleyii ko si ṣẹyin abajade idibo gomina to waye loṣu kẹsan-an, ọdun to kọja.

 

Loootọ, igbẹjọ nipa bi ajọ eleto idibo ṣe kede Alhaji Gboyega Oyetọla ti ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu idibo gomina naa ṣi n lọ lọwọ niluu Abuja, sibẹ, ọpọ awọn onwoye gbagbọ pe o ṣee ṣe ki ohun to ṣẹlẹ nigba naa jẹ ọpakulẹtẹ ibi ti igi oṣelu yoo wo si nipinlẹ Ọṣun lọsẹ to n bọ.

 

Ti a ko ba gbagbe, lẹyin idibo gomina to waye lọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan-an, ọdun 2018, ninu eyi ti ẹgbẹ oṣelu mejidinlaaadọta ti kopa, ibo ọọdunrun ati diẹ ni oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnetọ Ademọla Adeleke fi gbe ti APC, ṣugbọn ajọ INEC ni awọn ko le kede rẹ gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori.

 

Wọn paṣẹ pe ki atundi ibo wa lawọn wọọdu kan nijọba ibilẹ Oṣogbo, Guusu Ifẹ, Ariwa Ifẹ ati Orolu. Atundi ibo yii waye lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, lasiko yẹn ni ẹgbẹ SDP ti wọn wa nipo kẹta fọwọsowọpọ pẹlu ẹgbẹ APC, wọn si fi ibo to din ni ẹẹdẹgbẹta ju ti PDP lọ, idi niyi ti ajọ INEC fi kede Gboyega Oyetọla gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ọṣun.

Nigba ti Ademọla Adeleke ṣagbeyẹwo ọrọ idibo yii, o ni ko tẹ oun lọrun, idi niyi to fi pẹjọ siwaju igbimọ ti aarẹ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lorileede yii gbe kalẹ lati ṣatunyẹwo ọrọ idibo naa, o si n lọ lọwọ niluu Abuja.

 

Bi ọrọ yẹn ṣe waa ri lo jẹ ki awọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji bẹrẹ si i leri si ara wọn pe idibo sẹnẹtọ atawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin apapọ ti yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji, ọdun yii, ni aala ti yoo fi oko ọlẹ han.

 

Awọn ẹgbẹ oṣelu APC sọ pe gbogbo iṣẹ tijọba to kuro nipinlẹ Ọṣun ṣe, labẹ Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, lodidi ọdun mẹjọ lo gbin ifẹ ẹgbẹ awọn sọkan awọn eeyan ipinlẹ ọhun. Wọn ni ko si iye igba tidibo kankan le waye nipinlẹ Oṣun; yala tijọba ibilẹ tabi tijọba apapọ, ti ẹgbẹ oṣelu PDP le rọwọ mu.

 

Ṣugbọn awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni tiwọn sọ pe iwa-ipa ti ẹgbẹ APC fi ṣeru lasiko atundi ibo gomina ko le ṣiṣẹ lọdun yii, koda, ọsẹ to kọja ni alaga wọn, Sọji Adagunodo, kegbajare lọ sọdọ ọga agba ọlọpaa lorileede yii, Mohammed Adamu, pe awọn ẹgbẹ APC ti bẹ awọn tọọgi lọwẹ lati bẹrẹ si i kọlu awọn aṣaaju ẹgbẹ PDP kasiko idibo too to.

 

Afi bii igba to jẹ pe wọn ko dibo ri ni gbogbo wọn ṣe n sa kabakaba kaakiri kọrọkọndu ipinlẹ Ọṣun bayii. Igbagbọ ọpọlọpọ eeyan ni pe ẹṣin ọla Arẹgbẹṣọla lawọn ọmọ ẹgbẹ APC maa n gun ṣakọ lasiko to wa lori aleefa, ṣugbọn ni bayii to jẹ pe gomina ti ko lagbaja lo wa nibẹ, olukaluku awọn oludije ni wọn n gbe ẹru wọn nibi to ti wuwo.

 

Niha Aarin-Gbungbun Ọṣun, Alhaji Ganiyu Ọla-Oluwa lati ijọba ibilẹ Ọlọrunda, ni ẹgbẹ PDP fa kalẹ, Dokita Ajibọla Bashiru lati ijọba ibilẹ Oṣogbo, ni ẹgbẹ APC fa kalẹ, nigba ti Ọtunba Lai Oyeduntan toun naa wa lati Oṣogbo yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu ADP ninu idibo naa.

 

Ọlaoluwa ti figba kan jẹ alaga ijọba ibilẹ Ọlọrunda, oun si ni alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun to gbeṣẹ fun Adagunodo. Bo ṣe jẹ pe imọ iwe ti ọkunrin oloṣelu yii ni ko to ti ẹni ti ẹgbẹ APC fa kalẹ, ṣe lawọn eeyan ro pe Ajibọla yoo maa jo kaakiri pe oun ti wọle lai ti i dibo, ṣugbọn oun naa mọ pe ẹran to yi lo n jẹ namọ.

 

Ọdun meje ni Ajibọla fi ṣe kọmiṣanna fun Arẹgbẹṣọla, o kọkọ jẹ kọmisanna fun akanṣe iṣẹ (Special duties), ko too di pe o di kọmisanna feto idajọ. Oluṣakoso fun atunkọ awọn ileewe nla nla ti Gomina Arẹgbẹṣọla kọ, iyẹn O’School, ni Ọtunba Oyeduntan ko too di pe o darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ADP lọdun to kọja, nigba ti katapila gba aarin wọn kọja.

 

A oo si ranti pe ibo ijọba ibilẹ Oṣogbo ati Ọlọrunda lo tun n sọ ibi ti igi oṣelu yoo wo si nipinlẹ Ọṣun bayii, idi niyẹn ti ọrọ naa fi le diẹ, ẹgbẹ mẹtẹẹta ni wọn n ja raburabu lati wọle lagbegbe naa. Lara awọn oloṣelu ti oju ṣi wa lara wọn lati Aarin-Gbungbun ọhun ni Gomina Gboyega Oyetọla, Ọmọọba Oyinlọla, Baba Adebisi Akande, Ọnọrebu Lasun Yusuff, Ẹnjinia Adeniji, Ọtunba Titi Laoye-Tọmọri, Ọnọrebu Kayọde Oduoye, Sẹnẹtọ Ṣọla Adeyẹye, Sunday Akere, Dokita Yẹmi Fatounbi ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

Ni ẹkun Iwọ-oorun Ọṣun, nibi ti Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti wa, wọn ko mu ọrọ naa ni kekere rara, koda, Dokita Deji Adeleke ti ọpọ eeyan gbagbọ pe ko nifẹẹ ninu oṣelu lo n ṣaaju awọn oludije ẹgbẹ PDP kaakiri lati ṣepolongo ibo.

 

Akọgun Lere Oyewumi lo n dije funpo Sẹnetọ fẹgbẹ PDP, Ẹnjinia Adelere Oriolowo ni APC fa kalẹ, ẹgbẹ ADP si fa Ọmọọba Dọtun Babayẹmi silẹ. Bo tilẹ jẹ pe wahala ṣi wa fun ẹgbẹ PDP lagbegbe naa pẹlu ẹjọ ti awọn alatilẹyin Dokita Akin Ogunbiyi pe Oyewumi, sibẹ, karakara ni ipolongo ibo n lọ nibẹ lojoojumọ.

 

Ohun to ṣẹlẹ ni pe Ogunbiyi loun ati Ademọla Adeleke jọ ja fitafita fun tikẹẹti ẹgbẹ PDP nigba naa, nigba ti wọn mu Ademọla, awọn alakooso ẹgbẹ naa l’Abuja sọ pe ki wọn yọnda ipo igbakeji gomina fun awọn alatilẹyin Ogunbiyi, ṣugbọn Ọnọrebu Adeogun ti Ademọla ti mu ṣaaju igba naa sọ pe oun ko le fi tikẹẹti naa silẹ.

 

Nigba ti eleyii ko bọ si i ni wọn tun ni ki awọn Adeleke yọnda ipo Sẹnetọ fun Ogunbiyi funra rẹ, a gbọ pe wọn bẹ ọkunrin yii ko too fara mọ eto yẹn, ṣugbọn iyalẹnu lo tun jẹ fun un nigba ti awọn alagbara kan yari kanlẹ pe ṣe ni ki Ogunbiyi lọọ to, wọn ni ṣẹṣẹ-de lọkunrin naa nipa oṣelu ipinlẹ Ọṣun, Akọgun Lere Oyewumi si gba fọọmu naa.

 

Ibinu yii lawọn alayilẹyin Ogunbiyi fi gba kootu lọ, wọn pe Oyewumi, ọmọ bibi ilu Ikire ọhun lẹjọ, koda, ẹjọ naa n gbona lọwọlọwọ nile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa nipinlẹ Ọṣun, ko si sẹni to mọ ibi ti kangun-kangun-kangun ẹjọ naa yoo kangun si.

 

Ni ti Oriolowo, ọmọ bibi ilu Iwo yii ni alakooso eto O’ramp labẹ iṣejọba Arẹgbẹṣọla nipinlẹ Ọṣun, bo tilẹ jẹ pe baba naa ko lagbaja rara, sibẹ, oun naa n gbiyanju niwọnba tiẹ, o si n ṣeleri awọn nnkan ti yoo ṣe fawọn araalu.

Ọmọ bibi ilu Gbọngan ni Dọtun Babayẹmi ni tiẹ, o si da bii ẹni pe ariwo ọkunrin naa n dunlẹ, koda, ojoojumọ lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu oriṣiiriṣii n ṣeleri atilẹyin fun un.

 

Lara awọn eekan oloṣelu ti yoo sọ ibi ti nnkan n lọ lagbegbe naa ni idile Adeleke, Alhaji Moshood Adeoti,  Alagba Peter Babalọla, Dokita Akin Ogunbiyi, Ọnọrebu Folukẹ Etteh, Benedict Olugboyega Alabi, Bọla Oyebamiji, Mudashiru Hussein, Abẹnugan Najeem Salam, Bamidele Salam, Adejare Bello ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

Loke-loke ni ọkan gbogbo awọn oloṣelu lati ẹkun Ila-Oorun Ọṣun wa bayii, idi ni pe Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla gbọdọ mura, ki ẹgbẹ oṣelu mi-in ma gba ibẹ mọ ọn lọwọ, Ọtunba Iyiọla Omiṣore gbọdọ fi han gbogbo aye pe loootọ loun tọ si apọnle tawọn ẹgbẹ oṣelu APC n fun oun lọwọlọwọ bayii, bakan naa lawọn ẹgbẹ PDP n leri pe awọn yoo fagba han ẹgbẹ APC lagbegbe yẹn.

 

Igbakeji ọga-agba nileeṣẹ ajọ asọbọde orileede yii tẹlẹ, Ọmọọba Francis Adenigba Fadahunsi, lati ilu Ilasẹ-Ijeṣa ni ẹgbẹ PDP fa kalẹ, ẹẹkeji si leleyii ti yoo dupo naa, koda, ahesọ to n lọ kaakiri, bo tilẹ jẹ pe ile-ẹjọ sọ pe ko ri bẹẹ, ni pe baba yii lo wọle lọdun 2015, ṣugbọn ti wọn gbe ibo naa fun Sẹnetọ Babajide Ọmọworarẹ ti ẹgbẹ APC nigba naa.

 

Ọnọrebu Ajibọla Famurewa lati Ileṣa ni ẹgbẹ APC fa kalẹ, oun lo n ṣoju awọn eeyan agbegbe ilẹ Ijeṣa nile igbimọ aṣofin apapọ lọwọlọwọ, oun si ni alakooso eto ipolongo idibo gomina to gbe Oyetọla wọle.

 

Ọnọrebu Oluṣẹgun Fanibẹ, ọmọ bibi ilu Ileefẹ, to n dije labẹ ẹgbẹ oṣelu Accord Party naa ko ṣe e fọwọ rọ sẹyin. Ọkọ Arugbo, gẹgẹ bi wọn ṣe maa n pe e lagbegbe Ifẹ/Ijeṣa naa n fin awọn ẹgbẹ oṣelu to ku lapẹ, o si daju pe wọn yoo jọ pin ibo yẹn ni lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji, ti a wa yii.

 

Lara awọn oloṣelu ti oju wa lara wọn lagbegbe yẹn ni Arẹgbẹṣọla, Omiṣore, Ọmọworarẹ, Adeogun, Erelu Oluṣọla Ọbada, Wale Ladipọ, Ọnọrebu Oluwọle Ọkẹ, Alagba Ebenezer Babatọpẹ, Ọnọrebu Adeogun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

Ni ti idibo aarẹ, bi awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ṣe n sọ pe ida aadọrun-un ninu ọgọrun-un idibo ipinlẹ Ọṣun lo wa fun Aarẹ Mohammadu Buhari lawọn ẹgbẹ oṣelu PDP ni itanjẹ lasan ni, wọn ni ki Buhari yaa gbagbe Ọṣun, nitori pe Alhaji Atiku Abubakar lawọn araalu yoo dibo fun.

 

Bi ọrọ ṣe wa n lọ bayii lo mu ki kọmisanna ọlọpaa l’Ọṣun, Fimihan Adeoye maa fojoojumọ pariwo pe oun ko ni i faaye gba ẹnikẹni lati da omi alaafia ipinlẹ Ọṣun ru nipa idibo yii, o ni ki ẹnikẹni ti ko ba lẹtọọ lati wa nibudo idibo ra ounjẹ sile, ko si rọra maa gbọ ohun to ba n lọ lori redio lọjọ naa.

 

Bakan naa ni kọmisanna fun ajọ eleto idibo, (INEC) nipinlẹ Ọṣun, Oluṣẹgun Agbaje, ni ko ni i si aaye fun magomago lasiko idibo naa, ọmọ ajọ naa tọwọ ba tẹ pe o gbabọde pẹlu awọn oloṣelu yoo fimu danrin.

 

(15)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.